FinCen files: Báńkì HSBC ṣe agbódegbà fún àwọn oníjìbìtì owó èké láìnáání ìkìlọ̀

HSBC lawon oluwadii ti ṣi aṣọ ni oju rẹ pe o lọwọ ninu bi awọn onijibiti ṣe n ko awọn iwe ẹgbẹlẹgbẹ dọla owo ilẹ Amerika ti wọn lu awọn oludokoowo kiri agbaye ni jibiti.
HSBC ni banki to tobi ju ni ilẹ Gẹẹsi, lo awọn idokoowo rẹ ni ilẹ Amerika lati fi gbe owo naa lọ si aṣuwọn rẹ to wa ni Hong Kong laarin ọdun 2013 ati 2014.
Inu iwe iwadii kan ti wọn pe ni FinCen ni aṣiri bi banki naa ṣe kopa ninu jibiti ẹlẹgbẹerun mejilelọgọta pọun naa wa.
- Ọlọ́jọ́ Festival 2020:Ọ̀ọ̀ni ti Ilé Ifẹ̀ tí wọ ìléèdí ọlọjọ méje tí kò ní rí ẹnikẹ́ni sójú
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ afurasí ọlọ́pàá tó yìnbọn fún ọ̀dọ́kùnrin tó fún èèyàn lóyún s'átìmọ́lé
- Ọ̀rọ̀ Soyinka àti Obasanjo papọ̀ lórí pé Buhari n ṣe ìpínyà Nàìjíríà
- Ọ̀wọ́ngógó búrẹ́dì gbòde kàn lẹ́yìn tí àwọn oníbúrẹ́dì da iṣẹ́ sílẹ̀
Amosa, banki HSBC ṣalaye pe oun ko fi igba kankan kọja aala ofin lẹnu iṣẹ oun paapaa julọ nipa difi iroyin awọn nnkan bẹẹro awọn alaṣẹ to ba yẹ leti.
Awọn iwe iwadii naa se alaye bi awọn onijibiti idokoowo sogun dogoji Ponzi scheme ṣe bẹrẹ kete lẹyin ti wọn ni ki banki naa san owo to din diẹ ni biliọnu meji dọla owo ilẹ Amẹrika lorilẹedẹ Amẹrika fun biba awon eeyan kowo pamọ kiri lọna ti ko tọ.
Awọn agbẹjọro fun awọn oludokowo ti wọn lu ni jibiti labẹ eto naa ṣalaye pe o yẹ ki banki ọhuun ti gbe igbesẹ to yanranti labẹ eto naa.
Ki ni jibiti idokoowo pnzi yii da ke lori?
Jibiti idokoowo ti wọn ṣekilọ fun banki HSBC lori rẹ yii ni wọn n pe ni WCM777. Oun lo ṣokunfa iku oludokowo kan, Reynaldo Pacheco ti wọn ba oku rẹ labẹ omini ile kan to wa ni Napa, California loṣu kẹrin ọdun 2014.
Awọn ọlọpaa sọ pe nṣe ni wọn sọọ ni okuta pa.

O rari wọ eto idokoowo naa, bẹẹni ireti wa pe yoo mu ọpọ awọn oludokoowo miran wọle lati di ọlọrọ jaburata.Arabinrin kan ti ọgbẹni Pacheco mu wọle padanu ẹgbẹrun mẹta dọla eleyi lo si ṣokunfa iku rẹ lọwọ awọn ajinigbe ti wọn bẹ lowẹ sii.
Okan lara awọn ọlọpaa to ṣe iwadi naa, Sajẹnti Chris Pacheco, (ko tan mọ ẹni to ku o), iwadii naa ni nse lo n gbiyanju lati mu aye dara fun awon eeyanlai mọ pe awọn gbajuẹ lo gba oun, o si fi ẹmi ara rẹ dii.
O ni jibiti ti idokoowo olowo ele Ponzi lu u lo ṣokunfa iku re.

Ki ni awọn ileri ti eto olowo ele onijibiti naa se fun wọn?
Ọmọ orilẹ-ede China kan ti orukọ rẹ n jẹ Ming Xu lo da a silẹ ko si si ẹni fi bẹẹ mọ ohunkohun nipa boya ilẹ Amerika lo gbe bi o tilẹ jẹ oe awon eeyan kan n sọ pe ibẹ lo ti lọ si ileewe gba imọ keji ni fasiti.
Ni ilu Los Angeles ni arakunrin Xu, abi Dr. Phil gẹgẹ bi ọpọ ṣe maa n pe e tẹdo si. Nibẹ lo si ti n ṣe ojuse pasitọ ijọ awọn ijọ kan.
Ọgbẹni Xu ni idokowo kariaye loun n ṣw, eleyii ti yoo mu ere ida ọgọrun fun ẹnikẹni to ba kopa laarin ọgọrun ọjọ.
Ohun to n ṣe naa ni eto idokowo olowoele onijibiti Ponzi WCM777.
Nipasẹ idanileko kaakiri, loju opo Facebook ati YouTube owo to le ni ọgọrin miliọnu dọla ni wọn pa wọle nipasẹ ohun ti wọn n oe ni idokowo latiri ayelujara.
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ọkùnrin tó gé akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ wẹ́lẹ́ wẹ́lẹ́ fún òògùn owó ní Ikorodu
- Ọkọ̀ méjì jóná ráùráú níbi tí ọkọ̀ tó gbé bẹntiróò ti gbiná
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ọkùnrin tó gé akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ wẹ́lẹ́ wẹ́lẹ́ fún òògùn owó ní Ikorodu
- Áṣẹyin kìlọ̀ fáwọn adarí olóṣèlú Nàìjíríà láti ṣe ohun tó yẹ nítorí ará ọ̀run ń wò wọ́n!















