Facebook mú àyípadà bá àtẹ̀jíṣẹ́ síra ẹni lórí òpó Instagram, wo àwọn ǹkan tó kàn ọ níbẹ̀

Facebook

Oríṣun àwòrán, others

Facebook lo jẹ oju ayelujara to n fun awọn eniyan jakejado agbaye lanfani lati le maa kan siraẹni lai kuro loju kan, bakan naa lo ti se iranwọ fun ọpọ eniyan lati mu idagbasoke ba oko-owo wọn

Lati ọjọ kinni, oṣu kẹwaa, ọdun yii lọ, ti o ba n lo aapu atejisẹ (facebook Messenger) Instagram, Bonfire abi aapu miran to jẹ ọkan lara eyi ti Facebook n ṣe, awọn ofin tuntun to niṣe pẹlu rẹ ree:

  • Nkan ti awọn eeyan gbọdọ mọ nipa rẹ. (Personal Information)

Gẹgẹ bi facebook se sọ, wọn o ni ta awọn nkan bii orukọ, atejisẹ e-mail ati awọn nkan miran fun awọn olupolongo ọja lori ayelujara, afi to o ba fun wọn laṣẹ lati ṣe bẹẹ.

Ṣugbọn niwọn igba to jẹ pe ọfẹ ni Facebook, awọn le maa fi awọn ipolongo to wulo fun ọ sọwọ si ọdọ rẹ.

  • Facebook ko ni foju rena awọn iwa to lewu

Ti o ba si danwo awọn ijiya ro wa ree

O ṣeeṣe ki wọn yọ nkan ti o fi si oju opo rẹ, mu adinku ba bi o se n lo awọn eroja kọọkan, wọn le ti oju opo rẹ pa, tabi ki wọn fa ọ le ọlọpaa lọwọ.

Wọn ni nigbakugba ti o ba fi nkan to lodi si ofin wọn soju opo rẹ, wọn o yọ kuro, wọn si ṣe alaye fun ọ lori rẹ.

Bakan naa ni wọn fẹ ki o fi ẹsun sọwọ, ti ẹnikẹni ba ṣe ohun to tẹ ẹtọ rẹ loju mọlẹ tabi ru ofin wọn.

Idi abajọ ni lati mu ki awọn aapu naa fi awọn eniyan lọkan balẹ lati lo. Ile iṣẹ naa ni awọn ti gba ọpọ eniyan siṣẹ lọna ọtọ to si jẹ pe iṣẹ wọn ni lati ma ṣọ eni to ba ru ofin kankan tabi to huwa aitọ si elomiran.

Nitori naa lati asiko yii lọ, o ṣe pataki ki o maa kiyesi awọn nkan ti o n ṣe lori ayelujara Facebook.

Àkọlé fídíò, Òwò ẹrú ọmọdé àti obìnrin lórí ayélujára

Koda bi o ba fọju, anfani wa fun ọ, nitori Facebook ti ni ki awọn to ni ipenija oju ma foya, aaye wa fun wọn lati lo awọn atunse tuntun naa.

Awọn irinṣẹ igbalode AI yoo maa ran awọn to ni ipenija oju lọwọ lati ni imọ nipa fọto tabi fidio ti ẹnikẹni ba fi sọwọ sori Facebook tabi Instagram

Fun awọn ti agbegbe wọn o fibẹ faaye gba ayelujara to yanranti, Facebook ti se awọn ilana ibanisọrọ ti yoo jẹ ki wọn ni anfani lati le wọ Facebook

Àkọlé fídíò, Nítorí owú jíjẹ, ọkọ Zarka gé imú aya rẹ̀ dànú!

Awọn nkan ti Facebook fẹ ki o ṣe:

*Facebook n fẹ ki o lo orukọ apejẹ rẹ ti gbogbo eniyan mọ ọ si lojoojumọ

*Sọ ootọ nipa ara rẹ ninu awọn nkan ti o kọ sori atejisẹ.

*Oju opo kan soso lo le ni, ki o si maa loo fun nkan ti ara rẹ nikan.

*Ma fi nọmba ti o fi n wọle sori aapu Facebook rẹ han ẹnikẹni, iwọ nikan lo wa fun, ma fun ẹnikẹni ni atejisẹ facebook rẹ tabi ki o pati ki ẹlomiran maa lo lai gba aṣẹ lọdọ Facebook funra rẹ.

Àkọlé fídíò, Wo ọna ti o le gba lati fi daabo bo ara rẹ lori Facebook.

O ko ni ẹtọ lati lo Facebook:

* bi o ko ba ti pe ọmọ ọdun mẹtala

*Bi o ba ti tẹwọn de lori ẹsun ifipabanilopọ tabi idunkoko mọ ọmọlakeji rẹ

*ti facebook ba ti ti oju opo rẹ pa ri nitori o ru ofin rẹ

*ti ofin ba ti jan lontẹ pe o ko le lo eyikeyi ninu nkan ti Facbook n ṣe

Awọn nkan ti o le fi ranṣẹ ati eyi ti o ko le fi ranṣẹ

Lootọ ni ile iṣẹ naa ni ki o ci nkan ti o ba mọ tabi sọ weo ọkan rẹ fun wọn, sugbọn kii ṣe lati ba ti ọmọlakeji rẹ laye jẹ.

Àkọlé fídíò, Àṣìṣe ọlọ́pàá àti Adájọ́ sọ mí di ẹni tí wọ́n dájọ́ ikú fún, ọpẹ́lọpẹ́ Fayoṣe tí ko buwọlu

Wọn ko ni fun ọ lanfani lati pin:

*Nkan ti yoo pa tabi tako ofin wọn ati awọn alaalẹ.

*Nkan to ba lodi si ofin, iroyin ofege ti o le mu isina wa, idẹyẹ sini tabi iwa gbajuẹ ori ayelujara.

*Awọn ro le tẹ ẹtọ ọmọlakeji rẹ loju mọlẹ ati jiji iṣẹ ọpọlọ ẹlomiran.

*Gbigbe awọn fairọọsi to lewu sori ayelujara

*Jiji data awọn eniyan

O le ka awọn nkan mira to ku to yẹ ki o mọ nibihttps://m.facebook.com/legal/terms/preview