Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomọṣọ
Mo parọ fawọn eeyan pe mi ò loyun ni titi mo fi bimọ- Dupẹ
BBC Yoruba ṣawari obinrin kan, dupe ti ọpọ n pe ni Iya Muiz sọrọ ilẹ kun lori bi o ṣe bi awọn ọmọ rẹ mẹrin fun baba meji ki o to tun loyun ọmọ karun un.
Dupẹ ni oun duro nitosi lati mọ ẹni ti yoo gbe ọmọ naa lẹyin ti oun bii lẹgbẹ ṣalanga to fi gbe ọmọ naa sori akitan ni Ogbomọsọ ni ipinlẹ Oyo.
- Inú mí dùn bí ìpínlẹ̀ Ọyọ se setán láti bẹ̀rẹ̀ ilé-ìwé tí àwọn akẹkọ̀ọ́ ń gbé- Òbí
- Ọkùnrin kan di èrò ọ̀run nítorí pé o fi ẹ̀sùn kan alájọgbélé rẹ̀ pé o n yan ìyàwó ẹnìkan lálè
- Àṣà Oge Ṣíṣe ní Akọ́mọlédè BBC Yorùbá ń gbé yẹ̀wò lónìí, Ó yá, iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀...
- Ẹgbẹ́ wa ò dàrú o! Kódà gbọingbọin la wà lẹ́yìn Akintoye gẹ́gẹ́ bíi adarí YWC nílé, lẹ́yìn odi
- Ohun tí a mọ̀ nìyí nípa gbọ́nmi síi omi ò tó lórí ọ̀rọ̀ oyè Babaloja-General ní ìpínlẹ̀ Oyo
Koda, ọrọ yii lagbara de ibi pe, o ni lati igba ti oun ti loyun ni oun ti mọ pe oun maa sọ ọmọ naa nu ni nitori ko si bi oun ṣe fẹ ri owo fi tọ ọ rara.
Iya Muiz ni oun ni akọbi ni ile baba oun pẹlu ọmọ mejidinlogun ti ko si agbara rara.
O ni iya ọkọ aarọ oun ko fẹ ki oun fẹe gbadun nigba ti ọkọ keji lahun ti ko si ni itọju obinrin lọwọ.
Lẹgbẹ ile iwosan Akala ni Ogbomọṣọ lo pada sọ ikoko ọmọ naa nu si ki awọn alaanu to ba a ri i he ti wọn si gbe e lo fun itọju.
Lẹyin o rẹyin ni aṣiri Dupẹ tu sọwọ ẹbi, ara ati ọlọpaa.
- Ọmọ Nàìjíríà, àfikún owó iná tuntun bẹ̀rẹ̀ lónìí: ọjọ́ kínní, oṣù kẹsàn án, ọdún 2020- NERC, Disco
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti bẹ̀rẹ̀ àtúnkọ́ ilé tí ẹlikọ́pútà tó jábọ́ bàjẹ́ ní ìlú Eko
- Àṣírí tú! Wo àwọn tó ń jí owó Covid-19 tí Ìjọba ní wọ́n yóò káwọ́ pọ̀nyìn rojọ́
- Ọ̀kọ̀ ojú omi dànù, ènìyàn méjì kù, ẹnìkan di àwátì
Alaga kansu, Adeyinka Rẹmi Oluwaseun ni Ogbomọṣo ati aya rẹ ba BBC sọrọ lori bi wọn ṣe pada ri ọmọ naa ti wọn si n tọju iya ati ikoko bayii.
Koda, awọn ni wọn sọ ọmọ tuntun naa ni orukọ: Moraaanugba Oluwaseun Adeyinka bayii.
Wọn gba imọran pe ki awọn ọdọ maa ni isẹ lapa ki wọn si ma pa ọmọ jọ silẹ lai lagbara ati le pese itọju fun wọn.
- Sinimá àwòdamiẹnu, Ẹ̀fáńjẹ́líìsì jìyà àjẹmumi nílé aṣẹ́wó l'Ejigbo ní ìlú Eko
- Gbajúgbajà òṣèré “Blue film'' wọ gàù ẹ̀sùn fífipá bá obìrin 13 lòpọ̀
- Èèyàn 239 míràn ṣẹ̀ṣẹ̀ kó COVID-19 ní Nàìjíríà
- Ọba Saudi Arabia yọ ọmọ rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ kúrò nípò nítorí ìwà àjẹbánu lórí owó tó yẹ fún ààbò ìlú
- Ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí Adams Oshiomole kìí ṣe ojú lásan, àwọn kan ló fẹ́ pa á- APC

