Ikare Monarch: Ọdún méjìdínláàdọ́ta ní Oba Adegbite-Adedoyin ló lókè èèpẹ̀, kó tó mí kanlẹ̀

Awọn ara ilu Ikarẹ Akoko

Lẹyin ti Ọwá Ale Ikarẹ, Oba Adegbite-Adedoyin papòdà lẹ́ni ọdún márùndínláàdọ́rùn ún lánaa, ọjọ Iṣẹgun, ni ọjọ kinni, oṣu kẹsan an , ọdun 2020 ni BBC kan si ilu naa.

Awọn ara ilu sọrọ nipa Kabiesi to waja naa pe o gbiyanju ipa rẹ fun idagbasoke Ikare Akoko.

Awọn ara ilu Ikarẹ Akoko

Ọba Ọwa Ale ilu Ikarẹ, Ọba Samuel Kolapo Adegbite-Adedoyin ti rebi agba n re.

Ori ade yi gẹgẹ bi ohun ta ri gbọ lo ọdun mejidinlaadọta lori apere ki o to dagbere faye lọjọ Iṣẹgun ni aafin rẹ to wa ni agbegbe Okorun.

Lasiko igbe aye rẹ, Oba Adegbite ni aarẹ ẹgbẹ awọn lọbalọba aadoje kan ni ipinlẹ Ondo to si tun jẹ ọmọ ẹgbẹ igbimọ lọbalọba ipinlẹ Ondo.

Awọn ara ilu Ikarẹ Akoko

Ọpọ awọn ara ilu Ikarẹ Akoko lo tu yahaya lọ si aafin lati kọkọ rii pe ṣe lotọ ni Kabiesi waja ki nitori wọn ni awọn ko fẹ gbagbọ pe ki Baba papoda lasiko yii.

Ṣugbọn wọn n fi idaro han lẹyin ti wọn rii pe Kabiesi Adegbitẹ ti re ibi agba n re.

Awọn ara ilu Ikarẹ Akoko

Tọkunrin, tobinrin tọmọde tagba lo n wa si aafin wa ki awọn ẹbi ati Oloye ku ara fẹraku Kabiesi Adegbitẹ to lọ ba awọn baba nla rẹ.

Akọroyin wa to fidi ọrọ yi mulẹ sọ pe niṣe ni gbogbo ilu Ikare n kẹdun Ọba wọn ti ilu si pa lọọlọ.

Awọn ara ilu Ikarẹ Akoko

Ọmọ Oba Adeleke, ọkan ninu awọn ọmọ ti Kabiesi to waja fi silẹ lọ naa ṣalaye iru eeyan ti baba rẹ jẹ fun BBC Yoruba pe oninuure to fẹran ara ilu to n jọba le lori ni.

Ṣugbọn ko le fidi asiko ti wọn yoo tẹ baba si itẹ mulẹ pe ipade ṣi n lọ pẹlu awọn ti ọrọ kan laafin.

Aworan Owa Ale ilu Ikare

Oríṣun àwòrán, The Nation Newspapers

Ta ni Kabiesi Adegbitẹ Adedoyin to waja ni Ikarẹ Akoko?

Lọdun 1935 ni wọn bi Ọba Adegbite Adedoyin ti asiko ibi rẹ si ṣe deede ọdun meji si igba ti wọn bi Moses Orimolade oludasilẹ ijọ mimọ Kristẹni Cherubim and Seraphim Church.

Ọba Adegbite Adedoyin kawe gboye imọ anofin ta si gbọ pe o lọwọ si idasilẹ ile ẹkọ girama to le ni mẹjọ laarin ọsun 1978 si 1982.

Ikede iku ọba naa ko ti waye nitori pe awọn to yẹ ko ṣe ni o ni awọn etutu kan to yẹ ni ṣiṣe k'awọn to kede iku rẹ faraye.

Ọdun 1972 ni Owa Ale gun ori apere awọn babanla rẹ gẹgẹ bi Owa Ale ikẹtadinlogun ilu Ikare.

Àkọlé fídíò, 'Oyenusi ló mú mi wọ ẹgbẹ́ adigunjalè kó tó di pé mo b'Ólúwa pàdé'