Ikú Olumegbon: Ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́ta ló lò lókè èèpẹ̀, kó tó mí kanlẹ̀

Oríṣun àwòrán, Fatai Olumegbon
Ọkan lara awọn afọbajẹ ilu Eko Oloye Fatai Abiodun Olumegbon, ti jade laye.
Olumegbon jẹ́ àgba oyè ni ilu Eko nigba aye rẹ àti ọkan lara awọn afọbajẹ ilu Eko. Bakan naa lo jẹ oloye to n mojuto agbegbe Ajah ati awọn agbegbe miran to sunmọ.
Iroyin fidirẹmulẹ p,e gbajugbaja oloye naa jade laye ni orilẹede Ghana lọjọ aiku, ọjọ Kẹrinlelogun oṣu Kẹta, lẹni ọdun mọkandinlọgọta.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Baṣọ̀run Gáà, tó yan ọba mẹ́rin, pa ọba mẹ́rin àmọ́ ọba karùn-ún ló pa á
- Gómìnà Ganduje wọlé fún sáà kejì ní ìpínlẹ̀ Kano
- Supplementary election: Ọlọpàá gbé ikọ kògbérégbè díde lọ si wọ́ọ̀dù ìdìbò Gama
- A kẹ̀yìn sí Atiku torí àtúntò Nàíjíríà tó fẹ́ ṣe - Árẹ̀wá
- Ajimọbi tún gbé iṣẹ́ àgbàṣe ₦30bn jáde lọ́jọ́bọ - Seyi Makinde
- Iná ṣe ọṣẹ́ ní Mile 12 l‘Eko, ọ̀pọ̀ ilé àti ìsọ̀ jóná
- PDP ṣe èrú ìbò gómìnà ní Benue àti Sokoto, a kò ní gbà - APC yarí
A gbọ pe aisan kan, ti wọn ko darukọ, lo gba ẹmi rẹ.
Oloye Olumẹgbọn, tii se ọkan lara awọn afọbajẹ nilu Eko, nii tun se Fatai Olumegbon olori oye Idejo ni aafin ọba Eko to wa ni Iduganran.








