Seyi Makinde: Gbogbo iṣẹ́ àgbàṣe tí Ajimọbi ṣe lẹ́yìn ìbò ní màá gbéyẹ̀wò

Oríṣun àwòrán, Engr Seyi Makinde
Gomina tri ilu sẹsẹ dibo yan nipìnlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ko tii sinmi lori ariwo to n pa pe, gomina to wa nipo lọwọ, Abiọla Ajimọbi mọọmọ fẹ gbọn owo ilu gbẹ ni ki oun to gba ọpa asẹ lọwọ rẹ ni osu karun ọdun yii.
Atẹjade kan ti agbẹnusọ Seyi Makinde, Dọtun Oyelade fisita salaye pe, se ni ijọba Ajimọbi n fi iwanwara gbe awọn isẹ agbase kan jade pẹlu ọkẹ aimọye biliọnu naira, to si mu ifura dani.
Seyi Makinde wa leri leka pe gbogbo isẹ agbase ti Ajimọbi ba gbe jade lẹyin idibo gomina to kja ni oun yoo tu isu de isalẹ ikoko wọn ni kete ti oun ba gba ọpa asẹ tan losu karun ọdun yiii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Iná ṣe ọṣẹ́ ní Mile 12 l‘Eko, ọ̀pọ̀ ilé àti ìsọ̀ jóná
- PDP ṣe èrú ìbò gómìnà ní Benue àti Sokoto, a kò ní gbà - APC yarí
- Gómìnà Ganduje wọlé fún sáà kejì ní ìpínlẹ̀ Kano
- Kò sí ilé ẹjọ́ kankan tó yọ mí - Gboyega Oyetọla
- Leah Sharibu ni wòlíì wa ní àgọ́ Boko Haram - Obìnrin tó jàjàbọ́
- Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ń sàìsàn, òṣìṣẹ́ ọba ti pọ̀ jù - Oluwo
"Eyi to ya ni lẹnu julọ ni isẹ agbase towo rẹ to biliọnu lọna ọgbọn naira ti Ajimọbi kede rẹ lẹyin ipade igbimọ alasẹ ijọba to waye lọsẹ lọsẹ to kọja, mu ifura dani, paapa nigba to jẹ pe awọn gbese kan wa nilẹ lati 2011 tijọba Ajimọbi ko san."
Makinde fikun pe awọn osisẹ ti wọn ni ifẹ ilu lọkan, ti ke gbajare tọ oun wa pe, Ajimọbi ti n dete lati ri daju pe ijọba to n bọ ko ni tete ri ẹsẹ walẹ, nipa gbingbọn owo ilu gbẹ.









