Ọọni Ile Ifẹ - Ọba aláàánú ni Ọba Adéyeyè Enitan Ògúnwùsì

Oríṣun àwòrán, facebook
Kabiyesi Ọba Adeyeye Babatunde Enitan Ogunwusi ni a bi ni ọjọ kẹtadinlogun, Oṣu kẹwaa, ọdun 1974.
A bii si agbo ile Oluropo ati Wuraọla ni deede agogo kan ọsan ti o si jẹ ikarun un ọmọ laarin awọn ọmọ obi rẹ.
Ogunwusi ti o wa lati Idile Ọba Giesi, ni Agboole Agbedegbede ni Ilu Ile- Ife.
Ọba Alayeluwa Ogunwusi ni Ọba Ọọni ọkanlelaadọta ti ti o ti jẹ ni Ilẹ Yoruba.
- Ta ni Sadiya Umar Farouq tí ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ń gbé pé òun ló fẹ́ dí ìyàwó tuntun Buhari?
- Jessica Nabongo ni obìnrin àkọkọ nílẹ Adúláwọ tó rin gbogbo àgbáyé.
- Mi ò gbọ́ pé Akeredolu ti yọ mí nípò gẹ́gẹ́ bíi Olùbádámọraǹ rẹ̀ - Pelemo
- Irú ọjà wo ni wọ́n kò ti lè yan Ìyálọ́jà?
- 'Gomina Makinde, àgbọ́gbọn'tí ni kẹ́ẹ gbọ́ àwọn ará Oyo o lórí sáà kejì 'torí...'

Oríṣun àwòrán, Facebook
Asọtẹlẹ ṣaaju ìbí Oba Ogunwusi pe:
Ṣaaju ọjọ ibi rẹ ni wọn ti sọ asọtẹlẹ iru ẹni ti yoo jẹ, idi niyi ti iya rẹ ṣe pe e ni Enitan ti baba rẹ agba si sọ ọ ni Adeyeye.
Ọba Enitan ni o jẹ ikarun un laaarin awọn ẹgbọn rẹ ti o si ni aburo meji lẹyin rẹ.
Gẹgẹ bi Ọba Alade, O ni anfaani sii lati fẹ obinrin ti o wu u, lara awọn obinrin rẹ ni; Adebukọla Bombata ti o fẹ ni ọdun 2008.
Bakan naa lo fẹ olori Wuraọla ni ọdun 2016, nigba ti ifẹ aarọ rẹ jẹ Omọlara Ọlatunbọsun.
Ọba Adeyeye Ogunwusi Enitan ni Eledumare fi ọmọ jinki rẹ ti Adeọla Aanuoluwapọ si jẹ akọbi.
Oọnirisa gbe olori SilẹkunOla Naomi niyawo ti ayọ wọn dẹ jọ pọ.
Wo awọn ile iwe ti Ọọniwusi ti kawe:
Ọba Ẹnitan bẹrẹ ile iwe alakọbẹrẹ ni ile iwe ọjẹ wẹwẹ Ṣubuọla, ni Akobọ ni ilu Ibadan.
Ti o tun tẹsiwaju ni ile iwe giga Peteru Mimọ ni ilu Ile Ifẹ ti o si gba oye Imọ lori Iṣiro owo ni ile iwe Gbogboniṣe Ilu Ibadan.
O jẹ ọmọ ẹgbẹ awọn oluṣiro owo lorilẹ-ede Naijiria, oriṣiriṣi eka egbe iṣiro owo ni Kabiyesi jẹ ọmọ ẹgbẹ wọn.
Bakan naa ni wọn tun fi ami ẹyẹ ọmọ ẹgbe imọ ofin ati imọ nipa bi a ti n ṣakoso ile iṣẹ da Kabiesi lọla ni ile iwe Fasiti ti Ilu Nsukka ati fasiti Igbinedion.

Oríṣun àwòrán, facebook
Ọba Enitan ni baba isalẹ ile iwe fasiti Orilẹ-ede Naijiria ni Ilu Nsukka.
Ṣe laarin obi ni a ti n yọfin inu rẹ ni ọrọ Ọba Enitan jẹ laarin ọpọ awọn eniyan pataki to du ipo oye Ọba naa.
Ọba Ogunwusi Enitan gun apere oye Ọọni ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, Oṣu kẹwaa, Ódun 2015.
Awọn Aṣeyọri ati ami ẹyẹ:
Gẹgẹ bi Ọba ti o fẹran alaafia, o pari ija pelu Iku baba yeye, Alaafin ti ilẹ Ọyọ lati mu iṣọkan ba ilẹ Yoruba lapapọ.
O ti gba ami ẹyẹ kaakakiri ilẹ Yoruba lori ọrọ alaafia.
Ọba Enitan ti ja fun ẹtọ awọn obinrin lọpọ igba.
Oba Ogunwusi ti mu ayapada ba lle Ife gidi nipa sisọ ilu naa di awokọṣe ati ibi Igbafẹ nipa gbingbin ododo ati mimu atunṣe ba bi ilu naa ti ri.
O jẹ alaanu ati olufifunni, ti o si n ran awọn eniyan lọwọ pupọ.
Ni ọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun 2016, ni a fi kọkọrọ lati jẹ ọmọ Ipinlẹ Franklin ni orilẹ-ede Amẹrika le Kabiyesi lọwọ.
O jẹ Ọba Ilu mọọka ni orilẹ-ede yii ati loke okun.














