Oyo Politics: Onímọ̀ nípa òṣèlú ní kí 'Gomina Makinde má polongo ọ̀rọ̀ àwọn aráàlù

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Twitter
Laipẹ yii ni iroyin kan jade pe gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ni àwọn araalu n ke si oun lati lọ fun saa keji.
Bi o tilẹ jẹ wi pe amojuẹrọ Seyi Makinde ni oun fesi si ohun ti wọn sọ pe ki wọn jẹ ki oun gbajumọ awọn iṣẹ to dawọle ni lọọlọ yii.
Nigba ti BBC Yoruba kan si onimọ nipa ọrọ oṣelu kan ni fasiti ilu Ibadan, Ọmọwe Dikrullahi Yagboyaju ni lakọkọ oun fẹ nigbagbọ pe bi gomina ṣe sọ ọ naa lo ri pe awọn eeyan lo sọ bẹẹ.
Eyi ni wi pe bo ba ṣe pe lootọ awọn araalu lo n kan sara si iṣẹ rẹ ti wọn si n pe e pe ko lọ fun saa keji ko buru nitori pe awọn oloṣelu lọpọ igba lo maa n fi ọgbọn fi iru ọrọ naa sita lati wo bi awn eeyan yoo ṣe gba a si.
Ẹwẹ, ni iha ti awọn araalu to n sọ bẹẹ, Ọmọwe ni o ku diẹ kaato tori gomina gan ko tilẹ tii lo ju oṣu mẹfa lọ ti wọn si ti wa n sare da orin ko wa ṣe dun mẹrin mii.
O ni ka tilẹ gba pe gomina ti bẹrẹ saa rẹ daadaa, "fun emi o, mo ro pe o ti ya ju. Ki gomina le ri orukọ wọn kọ silẹ ninu iwe itan to daa ni ipinlẹ Oyo, agbọgbọn'ti ni ki wọn maa gbọ orin maa jo lọ mo n wo ẹyin rẹ tawọn araalu kan n kọ fun wọn".
- Àṣírí tú! Ọwọ Ọlọpàá ti tẹ ilé ìfìyà jẹni tí wọ́n fi ń pe ilé kéú ní Katsina
- Funke Adesiyan, òṣèré Yollywood tó di olùrànlọ́wọ́ aya ààrẹ, Aisha Buhari
- Àgungùnlá! Bí Buhari wọ́gilé wíwọ bàálù olówó gọbọi fún òṣìṣẹ́ ìjọba kó ṣe aráàlú láǹfàní - SERAP
- Obinrin kan àti ọmọ rẹ̀ jóná nínú ìjàmbá iná ọjà Onitsha
- Àwọn ojú oge Yollywood t'ọ́jà wọ́n ṣì ń tà wàràwàrà
O fi we ọmọ ileewe ti ko tii ka ipele ikini yọri na ni fasiti ti wọn ti n sọ fun pe ibi ti yoo ti ṣiṣẹ ree to ba ti pari agunbanirọ rẹ.
Ọmọwe Yagboyaju ni ki gomina gbọ ọ̀rọ̀ naa ko kan feti gbọn ọn danu ni ko si yẹ ko tii ka a kun rara lasiko yii.
O ni iru orin to yẹ ko maa jade ni pe "gomina o, a dupẹ lọwọ yin o, ẹ n gbiyanju o, kẹẹ 'se daadaa si ni o".
Ọmọwe ni ẹni to ba mọ nkan to n ṣe gbudọ ṣọra fun apọnju latọdọ araalu.
Ni idahun si wi pe ṣe ofin sọ pe asiko kan pato leeyan le kan sara si iṣẹ gomina ati lati sọ pe ko lọ fun saa kan sii, Yagboyaju fesi pe ohun gbogbo lo lasiko tirẹ.
"Bi oloṣelu ba n ṣe awọn nkan to ṣe adehun rẹ nigba ipolongo, o yẹ ka lu wọn lọgọ ẹnu lootọ pe wọn ṣe daa ṣugbọn fun ẹni to ba ni arojinlẹ a mọ pe 'a fẹ kẹ ṣe saa kan sii' ko tii kan iyẹn rara".
Ipa aidaa to wa ninu bi gomina ọhun ba wa gba nkan ti wọn sọ gbọ, ti ara rẹ ya sii, to si ti n fi huwa, o lee ṣi ẹni to n ṣe daadaa ọhun gan lọna.
O yẹ ko tẹ ẹ jẹjẹ ni, a mọ pe gomina Seyi Makinde n ṣiṣẹ daadaa ṣugbọn ko fi apẹrẹ ọmọ ile iwe ti oun sọ fi kọgbọn, ko kawe mẹrin akọkọ rẹ ja na.
O ni ki awọn araalu gaan ma ṣe ti gomina gbọọn gbọọn.













