Buhari: Kò sí àyè wíwọ ọkọ̀ bààlú olówó gọbọi mọ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @thesignalng

Ajọ ajafẹtọ ẹni, SERAP ti sọ pe arumọjẹ lasan ni igbeṣe ti aarẹ Muhammadu Buhari gbe lati fi adinku si owo ti awọn oṣiṣẹ ijọba n na lori irinajo silẹ okere.

Igbakeji adari ajọ SERAP, Kolawole Oluwadare lo sọ ọrọ yii ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ BBC.

Kolawole sọ pe eyi ti aarẹ Buhari ṣe pẹlu mimu adinku ba iye owo ati ọjọ tawọn oṣise ijọba yoo maa na ni irinajo ko buru, ṣugbọn ko tan iṣoro to n dojukọ Naijiria lasiko yii.

O ṣalaye pe igbesẹ naa ki yoo ni ipa kankan lara awọn ọmọ Naijiria, O ni "kini anfaani adinku owo tí ko nipa lara awọn ara ilu."

Kolawole sọ pe ohun to ṣe pataki ju ni ki ara ilu mọ bi ijọba ṣe n ṣeto ọrọ ilu, yato si bi gbogbo nkan ṣe ṣokunkun si wọn.

O tẹsiwaju pe "Yatọ̀ si iru ọna ati mu adinku ba owo ti ijọba n na yii, ohun to ṣe pataki ni ki ìjọba mú ọrọ igbaye gbadun ara ilu lọkunkundun."

Segun Sega Awosanya ti apele rẹ n jẹ Segalinks ni tirẹ ni, igbesẹ aarẹ naa jẹ ọna lati ka ọkan ara ilu kuro ninu ohun to ṣe pataki ni.

Segalinks sọ pe, kaka ki aarẹ mu ileri rẹ to ṣe pe oun yoo ta ninu awọn baalu to wa ni arọwọto rẹ, nnkan miran lo n gbaju mọ.

Àkọlé fídíò, Kayode Abiara: Ọmọ Nàíjíríà, ẹ má ba ọkàn jẹ́ lórí ààbò tó mẹ́hẹ, ewu ìgbà ìkẹyìn ló jẹ́

O ni arumọjẹ lasan ni ikede naa, ati pe ko si iyatọ kankan ti adinku yii yoo mu ba aye awọn ara ilu ti ara n ni.

O wa ke si ijọba lati ṣe ayẹwo bi o ṣe n na owo, paapaa julọ owo ti awọn to wa ni ijọba n gba.