Díẹ̀ lára àwon oúnjẹ ìbílẹ̀ wa tó tin ń di àwátì báyìí

Ọpọlọpọ awọn ounjẹ abalaye orilẹede wa lo ti n di awati bayii, paapaa ju lọ nilẹ Yoruba .
Pupọ ninu ounjẹ ti awọn baba nla wa n jẹ laye atijọ ni awọn ọmọ aye ode oni ko mọ, awọn miiran gan ko tilẹ gbọ orukọ irufẹ awọn ounjẹ bẹẹ ri.
Loni to jẹ ayajọ ọjọ ounjẹ lagbaye, a fẹ wo diẹ lara awọn ounjẹ ilẹ Yoruba to ti da bii pe o ti n kasẹ nilẹ laye ode oni.
1. Abari
Abari jẹ ọkan lara awọn ounjẹ ilẹ Yoruba to gbajumọ laye nigba kan ri. Sugbọn ọpọ lara awọn ọmọ aye ode oni ni ko mọ abari yii.
Abari fara jọ mọimọi, sugbọn agado ni wọn fi n ṣe abari dipo ẹwa.
Ni awọn ẹya kan lorilẹede Naijiria, wọn ma n pe ni Ukpo Oka, Sapala, Oka Ekusu tabi Ekoki, awọn miiran tun ma n pe nigba Ngwu Oka.
Awọn Yoruba man fi ìgbá si i, bẹẹ ni awọn Igbo ma n fi efirin tabi ẹfọ ugwu si i, ko le ni orun didun.
Lara awọn eroja ti wọn ma n fi se abari ni agbado, tataṣe, ede, igba, ata gigun, epo pupa, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
2. Egbo
Ewa ati agbado ni Egbo, o si jẹ ounje ilẹ Yoruba.
Bi wọn ṣe ma n se Egbo ni pe, wọn ma se agbado gbigbe titi ti yoo fi rọ, bakan naa ni wọn ma se ẹwa lọtọ.
Wọn ma n jẹ Egbo pẹlu ata dindin to ni alubọsa, epo pupa, ẹja yiyan ati tomati ninu.
Awọn elo ti wọn fi n se egbo ni agbado, ẹwa, epo pupa, tomati, abubọsa, ata, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
3. Aadun

Oríṣun àwòrán, @ojogbon_yoruba
Aadun jẹ ounjẹ ipanu nilẹ Yoruba. Agbado, epo ati awọn eroja miiran ni wọn fi n ṣe.
Awọn Yoruba ma n lo aadun ni ibi aṣeyẹ tabi igbeyawo laye atijọ.
Ohun ti wọn fi n se aadun ni; agbado ti wọn ti lọ, epo pupa, iyọ, ati awọn eroja miiran.
4. Ọjọjọ
Ọjọjọ jẹ ọkan gboogi lara awọn ounjẹ Yoruba laye atijọ.
Iṣu ewura ni wọn fi n ṣe Ọjọjọ.

Oríṣun àwòrán, Youtube/Onyx Food Hill
ọjọjọ dabi akara loju, paapaa ti eeyan ba n wo o lati okere.
Bo tilẹ jẹ pe o le to aadọta iṣẹju lati pese Ọjọjọ, ṣugbọn ko ṣoro lati pese rara.
Awọn eelo Ọjọjọ ni iṣu ewura, ororo, ata rodo, alubọsa, ede, iyọ diẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
5. Iṣu àti epo tàbí kẹ̀tẹ́

Oríṣun àwòrán, Youtube/Nigerian Food Recipes
Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan lero pe talaka nikan lo n fi epo jẹ iṣu, ṣugbọn ko ri bẹẹ rara tori ounjẹ to da yatọ ni.
Ọpọlọpọ awọn eeyan ti pa epo ti lati maa fi jẹ iṣu bayii, ti wọn si ti n lo ẹyin dindin, ṣugbọn iṣu ati epo ma n dun laye atijọ ninu oko.
Awọn mii laye atijọ nil Yoruba a maa fi kẹtẹ jẹ isu tori o ni ọpọlọpọ ororo lara.
ẹni ba fẹ gbadun iṣu ati epo ni lati se iṣu naa ṣaaju, lẹyin naa ni yoo tọ epo diẹ sori iṣu gbigbona naa, o lee fi iyọ diẹ si i.
Lobatan!













