Ekiti APC: Kíkọ ọjà tàbí afárá sí Ekiti kọ́ ni ìdàgbàsókè

Gomina Ipinlẹ Ekiti

Oríṣun àwòrán, Facebook

Àkọlé àwòrán, Kayode Fayemi

Ijọba Kayode Fayemi ni ipinlẹ Ekiti pe ọdun kan ni ọjọru ọsẹ yii ṣugbọn ẹgbẹ alatako ni ko si ipe fun ajọyọ.

Ẹni ti o jẹ abẹnugan fun gomina ana ni Ipinlẹ naa, Lere Olayinka ṣalaye pe ko si idagbasoke kan ti Fayemi gun le lati bii ọdun kan sẹyin.

O tun ṣalaye pe ko si atunṣe popona pẹlu gbogbo ọna aarin ilu ti o ti bajẹ ti ko si si ohun kan pato ti wọn le ri tọka si.

Ninu isọrọ tirẹ, alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ naa, Adegboyega Oguntuasẹ sọ wi pe lootọ ko si oun ti a le tọka si ṣugbọn idajọ n bẹ lọwọ ara ilu.

Nigba ti yoo fesi si ọrọ naa, Akọwe agba si Gomina Fayẹmi, Yinka Oyebode sọ wi pe, Fayemi ti ṣe gudugudu meje ati yaaya mẹfa.

O tẹsiwaju pe, ẹkọ ọfẹ ti Ijọba Fayoṣe kọ lati fun awọn akẹẹkọ Ipinlẹ naa ni Fayẹmi fun wọn lai gba owo kọọkan bo ti wu ki o kere mọ.

Ko ṣai mẹnu ba atunto ti Ijọba n muba gbogbo ohun ti Ijọba ana ti bajẹ ni Ipinlẹ naa bii gbigba owo ori lọwọ awọn ọmọ ile ẹkọ.

O ṣalaye pe gbogbo owo oṣu ti ijọba Fayoṣe jẹ ni wọn san pada lati igba ti wọn ti wa lori aga iṣejọba.