NIN: Ohùn mẹ́ta pàtàkì tó yẹ kí o mọ nípa nọ́mbà ìdánimọ̀ Nàìjíríà

Kaadi idanimọ E-Card

Oríṣun àwòrán, Google

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lẹnu lọọlọ yii, oju opo Twitter ti n sọ putuputu lori ọrọ owo sisan lati gba kaadi idanimọ mi ti ti tẹlẹ ba sọnu tabi ti ọjọ ba pe lori ti tẹlẹ.

Ohun to mu ọrọ yii wa ko ju ibeere ti eeyan kan beere loju opo Twitter ajọ to n ṣeto kaadi idanimọ ni Nigeria NIMC nipa gbigba kaadi mi ti eleyi toun ni ba sọnu.

Esi ti aṣoju ajọ naa kan fun pe yoo san ẹgbẹrun mẹta Naira lati fi gba omiran ti ọjọ ba ti pẹ lori ti tẹlẹ ko jẹ nnkan to dun mọ awọn eeyan ninu.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Yatọ si ẹgbẹrun mẹta yii, idahun naa sọ pe ẹni ti o ba sọ kaadi rẹ nu gbọdọ san ẹgbẹrun marun naira lati gba omiran.

Ọrọ yii mu iriwisi orisirisi wa ti awọn eeyan kan n si n binu pe ko yẹ ki ajọ naa ma gba owo ki o to fun awọn ọmọ Naijiria ni kaadi mi .

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Skip X post, 3

End of X post, 3

Bi ọrọ yi ti ṣe n ja rainrain la ba ni ki a kan si oju opo ajọ naa lati mọ pato itunmọ ati iyatọ to wa laarin awọn ọrọ bi NIN,nọmba idanimọ ati E-Card to jẹ kaadi idanimọ ti ajọ naa n fun awọn eeyan.

NIN lo se pataki ju niabi kaadi E-Card

Erongba ijọba pẹlu nọmba idanimọ ni pe ki awọn eeyan ma lo fun gbogbo ohun to ba ni ṣe pẹlu iforukọsilẹ.

Bo jẹ kaadi idibo tabi iwe irina to fi mọ iwe aṣẹ iwakọ,NIN ti ajọ NIMC n fun eeyan ti wọn ba ti gba orukọ rẹ ati awọn nnkan idanimọ miran silẹ lo ṣe pataki julọ.

Koda ti ọjọ ba pe lori awọn elo idanimọ to ku bi kaadi idibo,iwe irina, tabi iwe aṣẹ iwakọ,bi eeyan ko ba ni NIN,ko ni le gba omiran ninu awọn eleyi ti a ka kalẹ

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Ni soki, bi eeyan ba ti ni NIN, ọrọ buṣe amọ bi kaadi idanimọ rẹ ba sọnu, o di dandan ki o fi owo gba omiran.

Gbedeke iye ọjọ ti eeyan yoo fi lo wa lori kaadi E-Card amọ titi lai ni eeyan o fi ma lo NIN

Nibo ni eeyan ti le ri nọmba NIN yii?

Pupọ eeyan lo ma n ro wi pe ti oun ba ti gba kaadi idanimọ E-Card ti NIMC n fun awọn eeyan,wọn yoo ti kọ NIN rẹ si lara.

Ọrọ ko ri bẹ rara.

Awọn nọmba miran wa lara kaadi idanimọ E-Card lootọ amọ ko si NIN lara wọn.

Aworan iwe pelebe ti wọn kọ nọmba NIN si

Oríṣun àwòrán, Google

Iwe pelebe ti wọn ma n fun eeyan lẹyin to ba pari iforukọsilẹ ti aworan wa lara rẹ ni wọn kọ NIN nọmba si.

Nọmba mọkanla ni nọmba yii, ti o si wa lapa oke iwe pelebe yii.

N3500,N5000 ni wọn n gba E-Card to ba sọnu,elo ni wọn fi n gba NIN miiran?

Akọkọ naa, nọmba NIN ko le sọnu, wọn ko si le forukọ silẹ lati gbaa lẹẹmeji.

Ohun ti o ma n saba ṣẹlẹ ni ki awọn eeyan ma ri iwe pelebe ti a ṣafihan rẹ loke ti o ni nọmba NIN lara.

Ti eleyi ba ṣẹlẹ gẹgẹ bi alaye ti NIMC ṣe si oju opo wọn eeyan le ri pada yala ki o lọ si aye iforukọsilẹ tabi ki o si tẹ nọmba *346# lori ẹrọ alagbeka rẹ lati ri pada.

Ti o ba wa di dandan pe eeyan fẹ san owo lati gba nọmba yi,ko le san ju ẹẹdẹgbẹta naira lọ amọ yi o tẹle awọn igbesẹ kan ki o to le gba.

Aworan kaadi idanimo

Oríṣun àwòrán, Google

Ibeere nla ti o wa ku lẹyin alaye ti a ṣe yi ni pe kini ti awọn ti ko ri kaadi gba ti NIMC ni wọn gbọdọ san owo ti ọjọ ba pe lori kaadi naa?

Ajọ naa kori esi fọ si ibeere yi ti awọn eeyan n bere botilẹjẹwipe wọn ni awọn ko lowo lati tẹ kaadi fun awọn ọmọ Naijiria.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Ona abayọ lo ku bayi, ko si tii daju ẹni ti yoo wa abayọ si ipenija to wa nilẹ yi.