Ìwádìí ICPC fi hàn pé ènìyàn 721 fi ayédèrú ìwé ẹ̀rí gba iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, Ht
Bá wó ni òṣìṣẹ ẹẹdẹgbẹrin ati mọkanlelogun ṣe gba iṣẹ ijọba apapọ pẹlu iwe ayederu?
Eyi ni ibeere to gba ẹnu ọpọ ọmọ Naijiria kan bi iwadii ajọ ICPC to n risi iwa ajẹbanu ati iwa aitọ ni Naijiria ṣe jade.
Iwadii yii lo ṣafihan iye awọn to n ṣiṣẹ ni ajọ to n ṣakoso ọgba ẹwọn (NPS), abo ara ẹni ni aabo ilu (NSCDC), iwọle-wọde eniyan si Nigeria (NIM), panapana (FFS) ati awọn ajọ meji miiran.
ICPC n ṣe agbeyẹwo iwe ẹri awọn oṣiṣẹ to le ni ẹgbẹrun lọna ogoji ninu eyi ti aṣiri ti tu lori awọn to n lo ayederu iwe ẹri wọnyii.
Àwọn ileeṣẹ ijọba apapọ mẹfa ni wọn ti ri awọn to n lo iwe ẹri ayederu yii.
Lara awọn ẹgbẹrun lọna ogoji naa, ICPC ni awọn ti gbe iwe ẹri ẹgbẹrun mejila yẹwo lara eyi ti wọn ti ri iye ayederu iwe ẹri yi.
Ajọ naa ko ti i ṣalaye igbesẹ ti yoo gbe lori awọn to n lo ayederu iwe naa lẹyin ti agbeyẹwo iwe ẹri naa ba pari.










