Babajide Sanwo-Olu 'pa'lù ẹnu dá',o lóun kò ṣèlérí nípa súnkẹrẹ-fàkẹrẹ Apapa láàrín ọgọta ọjọ

Oríṣun àwòrán, @jimidisu
Yoruba ni ẹni to ba fẹ parọ laa ni ẹlẹri oun wa lọrun.
Lori awuyewuye oun ti Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu sọ nipa didẹkun sunkẹrẹ fakẹrẹ Apapa, ile iṣẹ BBC ṣewadi, a si ri ẹri pe o sọ bẹẹ.
Ninu awọn fọnran fidio kan ti a fidi rẹ mulẹ pe oun lo wa ninu rẹ ni ẹri yii ti waye.
Lọjọ iṣẹgun ni Gomina Sanwoolu pa ilu ẹnu da pe oun ko fi igba kankan ṣeleri lati mu opin ba sunkẹrẹ fakẹrẹ oju ọna Apapa laarin ọgọta ọjọ.
Gomina lede ọrọ yii nigba ti o n dahun ibeere lọdọ awọn akọroyin ni ile ijọba Aso Rock nilu Abuja lọjọ Iṣẹgun.
''Ohun ti mo sọ ni pe mo maa ṣe agbeyẹwo ohun to n ṣẹlẹ l'Apapa laarin ọgọta ọjọ, mi o ni mo maa mu opin ba sunkẹrẹ fakẹrẹ to n waye nibẹ
Awọn ẹri naa re e
Akọkọ fọnran fidio ibi ti o ti seleri yi tọwọ wa tẹ ni ibi to ti n ṣe ifọrọwero niwaju awọn eeyan nibi ayẹyẹ wa wi tẹnu rẹ ti ile iṣẹ karakata ipinlẹ Eko ṣagbatẹru rẹ.
Lai si ani ani o darukọ ọgọta ọjọ gẹgẹ bi gbedeke ti oun da lati mu opin ba sunkẹrẹ fakẹrẹ Apapa
Ẹ wo fidio naa nibi
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Ẹlẹkeji fidio ti a ri gẹgẹ bi ẹri pe o sọrọ yi naa ko fẹ yatọ si akọkọ nipa oun to ṣeleri lati ṣe .
Dipo ọgọta ọjọ, o ni oun yoo dẹkun ipenija yi laarin ọgọrun ọdun ti oun ba de ori alefa.
O ku ọsẹ meji ti wọn yoo dibo Gomina ni o sọ ọrọ yi ni oṣu Kini ọdun 2019
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ki lo mu Gomina ma ṣẹ lori ileri
Opopona Apapa jẹ ọkan ti o ṣe pataki fun lilọ bibọ ọkọ ati awọn ero nilu Eko.
Nitori bi lilọ bibọ ti ṣe pọ nibẹ, ọpọ eeyan lo ma n ha si inu sunkẹrẹ fakẹrẹ ati pe awọn ọkọ nla a ma saba bajẹ si ọna naa ti o si jẹ idiwọ nla.
Pupọ ninu awọn to ti jẹ Gomina ni wọn ti gbiyanju lati yanju wahala to wa loju ọna yi ti wọn ko ri yanju.
Awọn ara ilu Eko si ti n ke gbajarẹ ki ijọba wa wọrọkọ fi ṣada lori ọju ọna yi.
Bi ọrọ naa ṣe wọwa
Iroyin to mu arinyanjiyan yii waye ni eleyi ti a gbọ pe Sanwoolu ṣe ileri naa lasiko apejẹ kan lọjọ kejidinlogun oṣu karun nigba ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan an gẹgẹ bii Gomina.
Nibi apejẹ naa ti o ṣe pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn jijọ kawe gboye ni ile iwe fasiti ilu Eko laarin ọdun 1998/2000,iroyin kan pe Sanwoolu ṣeleri pe oun yoo mu opin ba sunkẹrẹ fakẹrẹ Apapa laarin ọgọta ọjọ.
O sọ gẹgẹ bi iroyin naa ti ṣe sọ, o ni lailai fi ti oṣelu ṣe, oun yoo palẹmọ awọn ọkọ agbepo nla to n ṣokunfa idiwọ lilọ bibọ lagbegbe naa.
Amọ ṣa gbogbo ọrọ yipada nigba ti Sanwoolu lọ si Abuja lati kopa ninu ipade awọn Gomina APC pẹlu Aarẹ Buhari.
Nibẹ lo ti wa sọ pe ọna abayọ lati di sunkẹrẹ fakẹrẹ Apapa ku ni ki wọn mu adinku ba igbokegbodo to n waye ni Apapa.
Ẹwẹ , ijọba apapọ Naijiria ti sun gbedeke ti igbimọ to n mojuto pipalẹmọ oju ọna Apapa mọ gbe kalẹ siwaju si .
Oṣe meji ni ijọba apapọ buwọlu lẹyin ti igbimọ naa tọrọ aye si lọdọ ijọba..
Igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo lo fọwọ si isunsiwaju yi lẹyin ipade kan to waye laarin oṣẹ gẹgẹ biatjade kan ti o tẹ ile iṣẹ BBC Pidgin lọwọ.
Igbimọ naa to bẹrẹ iṣẹ wọn ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu kaarun yoo wa fi esi iwadi wọn ṣọwọ si ijọba lọjọ kerinlelogunoṣu Kẹfa bayii.













