Fasiti Ọbafẹmi Awolowo University, Ọọni ile ifẹ takorawọn lórí ẹ̀sùn májèlé táwọn kan dà sómi iléèwé náà
Ile ẹkọ to gbajumọ lagbaye ni ileewe Ọbafẹmi Awolọwọ University, OAU to fi ikalẹ si ilu ile ifẹ ni ipinlẹ Ọṣun ṣugbọn ni aipẹ yii ni okiki kan pe awọn eeyan kan ti lọ da majele si odo omi ti ileewe naa n lo fun mimu ati ọpọlọpọ iṣẹ iwadi imọ ijinlẹ gbogbo.
Iroyin sọ pe awọn eeyan kan lo ṣa dede lọ pẹlu awọn ohun ija oloro ti wọn si da majele si inu odo naa ti wọn fi n pese omi ẹrọ fawọn akẹkọ ati olugbe inu ileewe naa.
Gẹgẹ bii ọrọ ti alukoro ileewe naa, Biọdun Ọlarewaju ba BBC News Yoruba sọ, awọn oṣiṣẹ alaabo ileewe fasiti naa to ri awọn eeyan naa ni ibi ti wọn ti gbe n ṣiṣẹ laabi yii lo pariwo sita ti awo ọrọ naa si fi lu sita faye gbọ.
O ni gbogbo awọn ohun abẹmi inu odo naa lasiko ti wọn da majele naa sii lo fara gba ninu rẹ. Amọṣa o ni ojo arọọrọda ọjọ meji to rọ ni ilu ile ifẹ lo dẹkun wahala ti ko ba waye lori iṣẹlẹ ọhun.
Nibayii, giwa ileewe fasiti naa, Ọjọgbọn Eyitọpẹ Ogunbọdẹde ti kọ iwe ẹhonu si awọn agbofinro-ọlọpaa ati ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS lati ṣewadii ọrọ ọhun.
Ninu ọrọ to fi sita, Ọọni ile ifẹ ti ṣe akawe ọrọ ọhun gẹgẹ bii eyi ti ko fidimulẹ.
Ninu atẹjade kan eleyi ti agbẹnusọ fun ọọni ile ifẹ, Moses Ọlafare fi sita, o ni ko si bi awọn ọmọbibi ilu ile ifẹ yoo ṣe gbaa lero tabi huu ninu iwa lati gbe majele lọ da si inu omi ti awọn akẹkọ n lo fun mimu.
"Ẹsun naa ko lẹsẹ nlẹ rara. Ohun ti ko tilẹ ṣee gba lero ni nitori, bawo ni eeyan ti ọpọẹọ rẹ pe kan yoo ṣe gba ẹsun yii gbọ? Ilu ile ifẹ ati ileewe giga fasiti OAU ti n gbe pọ fun ọjọ pipẹ to le ni aadọta ọdun paapaa, nitori naa ko si si igba kan ti iru nnkan bayii waye."
Amọṣa awọn alaṣẹ ileewe fasiti OAU ni ọrọ ilẹ ti awọn eeyan kan fẹ gba mọ ileewe naa lọwọ lo n fa igbesẹ yii.

Oríṣun àwòrán, citymirrornews.com
Gẹgẹ bii ọrọ ti Abiọdun Ọlarewaju, alukoro fasiti naa sọ, ilẹ ti ijọba ti fun fasiti naa lati aye Ọọni Adesọji Aderẹmi lawọn eeyan kan fẹ gba pada.
O wa fi da awọn obi ati alagbatọ to fi mọ akẹkọ leti pe wọn ti wojutu si majele naa, ayẹwo imọ ijinlẹ ti waye eleyi to ti fidi rẹ mulẹ pe o ti daa fun mimu bayii.
Akitiyan ṣi n lọ lọwọ lati kan si awọn agbofinro lori ibi ti iṣẹ iwadii de duro lori iṣẹlẹ ọhun.














