Ọjọ kẹsan an, oṣu kẹfa ọdun 2019 lo yẹ ki saa wọ́n wà sópin

Oríṣun àwòrán, @NGRSENATE
Yoruba bọ, wọn ni ibẹrẹ kii ṣe oniṣẹ, ọpọ ọmọ Naijiria ló n woye ibi ti awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin kẹjọ yii ba iṣẹ ilu de.
Bẹẹ, Ka pilẹ nnkan ko si tumọ si pe ẹni naa ni yoo pari rẹ.
Ọrọ yi ṣe bi ẹni ba ẹka aṣofin orile-ede Naijiria mu pẹlu awọn nnkan ti wọn dawọlẹ ti o jọ bi ẹni pe wọn ko ni le pari ki saa iṣejọba kẹjọ ti wọn n lo lọwọ yi yoo fi wa si opin.
Lara ojuṣe ti iwe ofin la kalẹ fun ẹka aṣofin ni ki wọn sagbatẹru awọn ofin eleyi ti yoo mu idagbasoke ati alafia ba awọn ara ilu.
Pẹlu ojuṣe yi lawọn omiran bi ki wọn ṣe ayẹwo finifini fun awọn ti ẹka alaṣẹ ijọba wa eleyi ti wọn a ma ṣe nigbadegba.
Ni bayi ti o ku ọjọ diẹ ki wọn pari saa wọn, a fẹ ṣe ayẹwo awọn nnkan ti wọn dawọle kọọkan ti ko daju pe wọn yoo ribi pari wọn ati iru ipa ti eleyi yoo ni lara iṣejọba ati igbayegbadun awọn ara ilu.
Aba isuna 2019.
Eleyi jẹ ọkan gboogi ninu igbesẹ ile aṣofin Naijiria kan ti wọn ko ti ribi ba de ibi to yanju ti ko si daju pe wọn yoo ri yanju ki saa ijọba wọn to pari.
Lootọ, ẹka alaṣe lo bẹrẹ irinajo aba yii ṣugbọn lọdọ awọn aṣofin ni o yi wa bayi lẹyin ti wọn ti ka a fun igba ekeji ti wọn si ti gbe e fun awọn igbimọ lati tubọ ṣe ayẹwo finifini aba naa.

Oríṣun àwòrán, Christian C. Ozor
Idibo gbogboogbo to waye wa lara awọn ohun ti mu ifasẹyin ba aba naa ti ko si daju pe bi awọn aṣofin ti ṣe n palẹmọ lati pada sile wọn yoo ribi joko yẹ aba naa wo mọ.
Ti a ba n kàá ni meni meji, o yi ku ipele bii mẹta ki aarẹ to buwọlu abadofin yi ko si daju pe wọn yoo rii ṣe ki saa ijọba yi to pari.
Ọrọ fifi ontẹ jan iyansipo Magu
Titi di bi a ti ṣe n sọrọ yi, Ibrahim Magu ṣi n ṣe adele ipo alaga ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra ni Naijiria EFCC.
Lẹẹmẹji ni ile aṣofin agba Naijiria tako iyansipo Ibrahim Magu gẹgẹ bi alaga ajọ EFCC.

Oríṣun àwòrán, Efcc/Facebook
Ninu alaye wọn, wọn ni iroyin ti awọn ileeṣẹ ọtẹlẹmuye fun awọn nipa Magu lo mu ki awọn ṣe lodi sí iyansipo rẹ.
Ẹka alaṣẹ ko wule gbiyanju lati ni ki Magu yọju nigba kẹta .
Bi nnkan ti ṣe ri lọwọ yi, o ṣeeṣẹ ki ile asofin ma yanju ọrọ Magu ki Magu si ma ba isẹ rẹ lọ titi ti awọn asofin mii yoo fi wọle.
Estimated Billing
Owo ina ọba ti ara ilu n san jẹ ọrọ kan pataki ti ile asofin eẹlẹẹkẹjọ lorile-ede Naijiria ko tii ribi yanju.
Ohun to si jẹ awọn ara ilu logun nipa ọrọ yi ni bi awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ mọnamọna ti ṣe n bu owo gọbọi fun awọn ti ko ni ẹrọ to n ka iye owo ina ti wọn kò lo 'pre paid meter'.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Femi Gbajabiamila
Asofin Femi Gbajabiamila lo sagbatẹru aba kan eleyi ti yoo yanju aawọ ọrọ owo ina ti ọpọ ara ilu n ke irora si sugbọn aba naa ko ti di ofin.
Orukọ abadofin naa ni Electric Power Sector Reform Act (Amendment) Bill, 2018; ti ireti si wa wi pe yoo sọ di ẹsẹ fun ẹnikẹni lati ma bu owo lu awọn ara ilu fun lilo ina ọba .
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Wọn ti ka abadofin yin fun igab ẹkẹta nile asoju sofin ti irinajo rẹ́ ṣi yi jina diẹ ki o to di ofin ti yoo mu irọrun ba ra ilu.
Awọn nnkan ti ile asofin ti ba de ibi to lami
Lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹta ọdun 2018, ile asofin Naijiria kede awọn aba ti wọn ti ṣiṣẹ lori tabi ti wọn buwọlu lati igba ti wọn ti bẹrẹ saa kẹjọ lọdun 2015.
Ikede yi wa lasiko igba ti awọn eeyan n faraya lẹyin ti akara tu sepo nipa iye owo osu ti awọn asofin n gba eleyi ti aṣofin Sheu Sani lati ipinlẹ Kaduna bẹ sita.
Ọrọ pọ ninu iwe kọbọ iṣẹ ti wọn lawọn ti ṣe ṣugbọn diẹ lara wọn re e.
Lara awọ́n nnkan ti ile ti yanju de ibi to lapẹrẹ lati ri:
- Bibuwọlu sisan ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira gg bi owo osu to kere julọ f'oṣiṣẹ
- Gbigbe igbesẹ lati mu opin ba didẹyẹ si awọn akẹkọ jade ile ẹkọ giga gbogboniṣe nipaiwe eri wọn pẹlu ti awọn akẹkọjade fasiti.













