NASS: Àbádòfin 2019 yóò fori sánpọ́n ti mínísìtà ò bá bẹ̀bẹ̀

Oríṣun àwòrán, @NGRSenate
Awọn Asofin ni Ile Igbimọ Asofin ti sọ wi pe awọn ko ni joko ni Ọjọru, ọsẹ to n bọ ti Aarẹ Buhari ni ohun yoo wa salaye bii owo isuna ọdun 2019 yoo se lọ.
Ipinnu awọn asofin yii ko sẹyin bii wọn se fẹsun kan minisita fun ọrọ isuna, sẹnetọ Udo Udoma wi pe o bu ẹnu atẹ lu wọn.
Iroyin ni minisita naa sọ pe awọn asofin n se segesege nitori wọn kọ lati fun ile isẹ ijọba ni ọjọ ti wọn yoo wa sọ nipa eto isuna fun ọdun 2019.
Lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye abẹnugan ile asofin, Họnọrabu Yakubu Dogara wa parọwa si awọn asofin wi pe ti minisita naa ba kọ lati tọrọ àforíjì ki o to di Ọjọ Isẹgun, ọsẹ to n bọ ni awọn yoo gbe igbese lori ọrọ naa.
Ni Ọjọ Isẹgun ọsẹ yii ni Aarẹ Muhammadu Buhari ni Ọjọru, ọsẹ to n bọ ni oun yoo wa salaye bii eto isuna ọdun 2019 yoo se ri.








