Ẹ̀rù ló n bà NEDG ni kò jẹ́ kí wọ́n pè mí sí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ f'áwọn olùdíje

Ọmọyẹle Ṣoworẹ

Oríṣun àwòrán, @yelesho

Àkọlé àwòrán, Ṣoworẹ sọ pe oun yoo sọ tita ati lilo igbó di ohun to ba ofin mu ni Naijiria ti oun ba fi di aarẹ

Oludije fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu African Action Congress, (AAC) ninu eto idibo aarẹ Naijiria l'ọdun 2019, Ọmọyẹle Ṣoworẹ sọ pe ẹrù ni ko jẹ ki ẹgbẹ to n ṣeto ifọrọwerọ lasiko eto idibo ni Naijria, Election Debate Group (NEDG) pe oun si ibi ifọrọwerọ laarin awọn oludije fun ipo aarẹ.

Ṣoworẹ sọ ọrọ yii ninu ọrọ to ba BBC Pidgin sọ lati fesi si bi NEDG ko ṣe fun l'anfaani lati kopa ninu ifọrọwerọ na

Àkọlé fídíò, Sòwòrẹ́: Èmi kò leè bá jẹgúdújẹrá APC àti PDP se pọ̀

Oludije maarun pere ninu eyi ti Aarẹ Muhammadu Buhari ati alatako rẹ̀ gboogi, Atiku Abubakar, ni ẹgbẹ NEDG ati Ẹgbẹ agbohunsafẹfẹ, Broadcasting Organization, pe fun ifọrọwerọ laarin awọn oludije fun ipo aarẹ.

Oṣu Kinni, ọdun 2019 ni eto naa yoo waye.

Awọn nkan mẹta ti awọn ọmọ Naijiria yoo ṣafẹri ninu ohun ti oludasilẹ ileeṣẹ iroyin Sahara Reporters Òun i ba sọ nibi ifọrọwerọ naa.

1.Ominira lati lo tabi ta igbó - Ṣoworẹ ti sọ tẹlẹ pe ọpọlọpọ orilẹede l'agbaye ti mọ anfaani to wa ninu igbo lilo ninu eto iwosan ati ọrọ aje, nitopi pe o le p'awo wọle. Eyi lo mu ki Ṣoworẹ sọ pe oun yoo sọ tita ati lilo igbó di ohun to ba ofin mu. Nibi ifọrọwerọ yii ni ko ba ti l'anfaani lati ṣalaye ọna to fẹ ẹ gbe gba.

2.Ọgọrun ẹgbẹrun Naira owo oṣu oṣiṣẹ to kere ju - Awọn gomina ipinlẹ ati ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣi n jiyan lori ọgbọn ẹgbẹrun Naira ti awọn oṣiṣẹ n fẹ gẹgẹ bi owo oṣu to kere ju. Ṣugbọn, Ṣoworẹ sọ pe ọgọrun ẹgbẹrun Naira l'oun yoo san ti oun ba di aarẹ, nitori pe Naijiria ni owo lati san an. Nibi ifọrọwanilẹnuwo naa ni ko ba ti raaye sọ bi yoo ṣe ṣe e.

3.Ẹgbẹrun mọkanlelogun agbara ina (Megawatts) laarin ọdun kan - Oludije naa ko ba lo anfaani lati ṣariyan-jiyan lori ohun to fa a ti orilẹede Naijiria ṣi fi n lo ẹgbẹrun mẹta agbara ina mọna-mọna, nigba to yẹ ko ti tayọ ọ rẹ. Oludije naa sọ pe erongba oun ni lati fi ẹgbẹrun mọkanlelogun kun, ti yoo si jẹ ẹgbẹrun mẹrinlelogun laarin ọdun kan ti oun ba di aarẹ.