Ibrahim Magu: Ọ̀gá àgbà báńkì tẹ́lẹ̀ rojọ́ tako alága EFCC tẹ́lẹ̀, ó fẹ̀ṣùn ìbàjẹ́ kàn-án

Ibrahim Magu

Oríṣun àwòrán, EFCC

Àkọlé àwòrán, Oniruuru ọmọ Naijiria ni Ibrahim Magu ti yẹ idi wọn wo lori ẹsun iwa ibajẹ

Ẹlẹ́rìí miran tun ti rojọ tako adele alaga ajọ EFCC, Ibrahim Magu, to n koju iwadii lori ẹsun iwa ibajẹ.

Ẹni naa, Dauda Lawal, to ti fi igba kan jẹ Ọga Agba ni ile ifowopamọ First Bank, fun'ra rẹ n jẹjọ lọwọ nile ẹjọ giga ijọba apapọ.

Ẹsun pe o gba miliọnu mẹẹdọgbọn Dọla, ninu miliọnu mẹtalelaadoje Dọla, ti wọn ni Minisita tẹlẹ fun epo rọbi, Diezani Alison-Madueke, ji ko, lo n jẹjọ le lori.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbimọ to wadii Magu lo ránṣẹ pe Lawal, lati jẹri lori awọn ẹsun àṣemáṣe to waye ninu isakoso Magu gẹgẹ bi alaga ajọ EFCC.

Lawal sọ pe, oun ko deede gba owo naa. O ni ọrẹ oun kan lo ni ki oun ba oun san owo naa si apo àsùnwọ̀n kan, eyi ti ko tako isẹ oun gẹgẹ bi oṣiṣẹ banki.

Aworan alaga EFCC Ibrahim Magu

Oríṣun àwòrán, EFCC

Àkọlé àwòrán, Aawọ ko sẹsẹ maa waye laarin awọn osisẹ ijọba apapo

O ni sugbọn, oun ko mọ orisun owo naa, ko si han si oun.

Bakan naa lo sọ pe iyalẹnu lo jẹ fun oun, nigba ti EFCC mu oun de ọfiisi won, ti ajọ naa sọ pe, miliọnu marunlelọgọta Dọla ni oun gba, dipo mẹẹdogun.

Koda, o ni wọn fi tipátipá mu oun san owo ti oun ko gba si apo àsùnwọ̀n ajọ naa.

O ni lẹyin ọjọ mọkanla ni akata EFCC, ni awọn oluwadii ajọ naa sọ pe oun gbọdọ san ogoji miliọnu Dọla ti wọn fi kún un.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Coronavirus di adákẹ́jà ní Somalia, ikú ọ̀wọ́ọ̀wọ́ ń peléke si

"Nise ni mo ya owó ni banki ti mo ti n sisẹ, ati lọwọ awọn ojulumọ mi, ki n to ri ìdá aadọta owo naa kó fun wọn nipasẹ agbejọro mi.

Lẹyin naa ni wọn tu mi silẹ ni ogúnjọ, oṣu Karùn-ún, ọdun 2016."

Lawal sọ pe, o le ni biliọnu mẹ́sàn-án Naira (9.8bn) ti oun san si àsùnwọ̀n ti EFCC n ko owo pamọ si ni Banki Apapọ, laarin ọjọ, oṣu Karùn-ún, si ọjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2016.

Eyi lo mu ko kọ iwe ẹsun mọ ajọ EFCC, nile ẹjọ, botilẹjẹ pe igbẹjọ si n lọ lori ọrọ ti ẹ naa.

Àkọlé fídíò, Working religious women: Ẹ̀lẹ́hàá kìí ṣe ọ̀lẹ- Aminat Adegoke

Sugbọn, agbejọro Ibrahim Magu, Ọgbẹni Wahab Shittu, ti sọ pe oun ko ni i gbà ki ẹnikẹni tun fi ẹsun kan onibaara òun lẹyin awọn to ti wa nilẹ tẹlẹ.

Ati pe gbogbo ẹsun ti wọn fi kan Magu, ni yoo ma wí àwíjàre rẹ le lori ni gbangba bayii.

Magu ati Keyamo ri'binu ijọba

Ijọba apapọ Naijiria ti fẹsun kan alaga ajọ EFCC ton gb'ogun ti iwa'bajẹ, Ibrahim Magu, ati gbajugbaja agbẹjọrọ ton ja f'ẹto ọmọniyan, Festus Keyamo.

Ẹsun tijọba fi kan wọn da lori gbigbe alaga ile ẹjọ ton se'dajọ iwa ibajẹ laarin awọn osisẹ ati awọn oselu (CCT), Danladi Umar, lori ẹsun iwa ibajẹ ni orukọ ijọba.

Ileesẹ iroyin PRNigeria sọ wipe ẹda-iwe ẹsun ti wọn kọ si Magu ati Keyamo ti tẹ oun l'ọwọ.

Amin iyasọtọ kan

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Amin iyasọtọ kan

O ni iwe ẹsun naa, ti wọn kọ lọjọ kẹrindinlogun osu keji ọdun 2016, paa lasẹ fun Magu lati f'esi si ẹsun naa, ko si fi ransẹ si minista feto idajọ ko to di ogunjọ osu keji ọdun 2018.

Iwe naa n fẹ ki Magu s'alaye nkan to faa, ti wọn fi f'ẹsun iwa'bajẹ kan alaga ile-ẹjọ CCT naa lẹyin ti EFCC ti safọmọ rẹ ninu ẹsun iwa ibajẹ lẹẹmeji.

Bakannaa, iwe ti wọn kọ si Festus Keyamo ko s'alaye ẹni to paa l'asẹ ati gbe Danladi Umar lo si ile ẹjọ.

Iwe naa si wipe ki Keyamo fi alaye rẹ ranse si minista eto idajọ titi ogunjọ osu keji ọdun 2018.