NIPOST àti FIRS ń fi ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tú ara wọn làṣìírí lórí ayélujáraTwitter

Oríṣun àwòrán, @firsNigeria/NipostNGn
Ori ayelujara Twitter ti n gbona janjan lẹyin ti ileeṣẹ ijọba apapọ to n mojuto ọrọ owo ori, ati ileeṣẹ abanifi nkan ranṣẹ NIPOST, fi ọrọ kobakungbe ranṣẹ si ra wọn.
Ọrọ owo naa lo da awuyewuye yii silẹ.
Alaga ileeṣẹ NIPOST, Arabinrin Maimuna Abubakar, lo kọkọ fi ọrọ sita pe ajọ FIRS, n gba ojuṣe NIPOST ṣe, nipa tita ontẹ ijọba fun fifi ẹru ranṣẹ, postage stamp.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Arabinrin Maimuna sọ pe ọna ti ko tọ ni FIRS n gba ta ontẹ naa ko ba ofin mu. O sọ pe NIPOST nikan lo ni aṣẹ lati ta a, tabi gba ileeṣẹ ti yoo maa ba a ta.
Kinni o sọ ọrọ yii si ni, iṣọrọ nigbesi ni ileeṣẹ FIRS fi ọrọ naa ṣe.
Oludari ẹka ibaraẹnisọrọ nileeṣẹ FIRS, Abdullahi Ismaila Ahmad, to fi esi naa sita sọ pe rọ òpè ati alaini oye ni Arabinrin Abubakar sọ, ati pe awọn ko ba ma fun ni esi, ṣugbọn pataki ọrọ naa lo mu ki oun fun ni esi.
O ni o ṣeni laanu pe Alaga ileeṣẹ NIPOST ko mọ iyatọ laarin iwe ontẹ 'postage stamp' ati owo ori 'Stamp Duty', ti ijọba ni ki FIRS o ma a gba fun fifi iwe ranṣẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
"Iyalẹnu lo jẹ fun wa pe ọdọmọbinrin to ni anfaani banta-banta lati jẹ adari NIPOSt, bọ si gbangba lati ta ẹrẹ si aṣọ ala ileeṣẹ FIRS ati ile aṣofin to ṣe ofin to gbe ileeṣẹ mejeeji kalẹ."
Oni oun rọ awọn ọmọ Naijiria, lati ma a gbọ ọrọ ijọgbọn, ati aṣinilọna ti Arabinrin Maimuna Abubakar, sọ ni gbangba.
Bakan naa lo sọ pe ileeṣẹ FIRS, yoo ri daju pe gbogbo awọn to ba lọwọ ninu inakuna owo ti NIPOST n pa lori Stamp duties to n gba lọna aitọ, fi oju wina ofin.
Igba akọkọ kọ niyii ti awọn ileeṣẹ ijọba Naijiria n fi ija pẹẹta lori ayelujara, lori ọrọ ti ọpọ gbagbọ pe o yẹ ki wọn o yanju ni ikọkọ.
Nipost, tíí ṣe orogún wa, kò lẹ́tọ̀ọ́ láti díye lé wa - Iléeṣẹ́ abáni fi ẹrù ránṣẹ́ yarí
Ọkan lara awọn onileesẹ abani fi ẹrun ransẹ ti salaye pe, bi igba ti wọn fẹ ẹ fi ara ni araalu, ni afikun owo fawọn onileesẹ naa.
Ọgbẹni Adewale Adeniran, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori igbesẹ ijọba naa ni, eyi yoo mu ki afikun owo ọjà ati iye ti wọn n ba ni fi nkan ránṣẹ.
"Miliọnu meji owo ìwé àṣẹ ti wọn ni ka ma a san ti pọju fun awọn to n ba n fi nkan ránṣẹ labẹle ni Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho yarí, ó fohùn ránsẹ́ sáwọn èèyàn tó ń pẹ̀gàn rẹ̀
- Àwọn iléesẹ́ abáni fi ẹrù ránṣẹ bẹ̀rẹ̀ ìyaṣẹ́lódì tako àfikún owó Nipost
- Ìkúnlẹ̀ ló bá dé fún Oshiomole, Ize-Iyamu láti bẹ̀bẹ̀ fún ìbò aráàlú ní Edo
- Sunday Igboho yari, o fohun ransẹ sawọn eeyan to n pẹgan rẹ
- Ikú Barakat Bello ní Akinyele gbé aláàánú pàdé ẹ́bí rẹ̀
- A ṣe ọdún Ọ̀ṣun lásìkò yìí láti kó Coronavirus lọ ni - Ooni ṣàlàyé
- Wo àwọn nǹkan tí o kò mọ̀ nípa 'Church of Satan'
Ọrọ naa da bi igba ti wọn ko fẹ ki awọn ọdọ ri isẹ ṣe ni.
Ọgbẹ́ni Adewale sọ pe, kii ṣe pe awọn ni ki ijọba mase gba owó, sugbọn o yẹ ki wọn o ṣe diẹ diẹ ni.
"Aikoju oṣuwọn ileesẹ NIPOST lo mu ki awọn ileesẹ abani fi nkan ránṣẹ kee kee ke bẹrẹ ni Naijiria.
Ka ni wọn n ṣe iṣẹ wọn daadaa ni, ko ni i ribẹ."
Bakan naa, ko yẹ ko jẹ NIPOST ni yoo ma a mojuto bi awọn ileesẹ yii ṣe n sisẹ, nitori pe oun fúnra rẹ jẹbi.
"Abi eelo ni awọn paapa ń san si apo ijọba l'ọdun?"
Ero Arabinrin Esther Ojo, toun naa jẹ onileesẹ abani fi ẹru ransẹ, nipa igbesẹ ijọba naa, ko yatọ si ti akẹẹgbẹ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/ NIPOST
O sọ fun BBC pe, ajọ NIPOST ni lati salaye nnkan ti owo naa wa fun, nitori pe ijọba ipinlẹ Eko ati awọn ijọba ibilẹ, naa n gba owó lọwọ àwọn.
"Aisi isẹ nilu lo mu wa bẹrẹ isẹ abani fi nkan ránṣẹ. Owo ti a n pa lọdun, ko to miliọnu meji ti NIPOST sọ pe ka mu wa.
Wọn ni "isẹ wa lara ni. A bẹ wọn, ki wọn o ba wa mu adinku ba."
Àwọn iléesẹ́ abáni fi ẹrù ránṣẹ bẹ̀rẹ̀ ìyaṣẹ́lódì tako àfikún owó Nipost
Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ileesẹ to n báni fi nkan ránṣẹ 'logistics', ti bẹrẹ iyansẹlodi lọjọ Aje.
Eyi ko sẹyin ofin tuntun ti ileesẹ ìjọba Naijiria to wa fun fifi nkan ránṣẹ, NIPOST, fi sita pe awọn ileesẹ naa yoo ma san awọn owo kan bayii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho yarí, ó fohùn ránsẹ́ sáwọn èèyàn tó ń pẹ̀gàn rẹ̀
- Ìkúnlẹ̀ ló bá dé fún Oshiomole, Ize-Iyamu láti bẹ̀bẹ̀ fún ìbò aráàlú ní Edo
- Sunday Igboho yari, o fohun ransẹ sawọn eeyan to n pẹgan rẹ
- Ikú Barakat Bello ní Akinyele gbé aláàánú pàdé ẹ́bí rẹ̀
- A ṣe ọdún Ọ̀ṣun lásìkò yìí láti kó Coronavirus lọ ni - Ooni ṣàlàyé
- Wo àwọn nǹkan tí o kò mọ̀ nípa 'Church of Satan'
- Àwọn afurasí ajínigbé tó tan oníṣòwò jáde ní ṣọ́ọ́sì wọ gàù Ọlọpaa
Diẹ lara awọn ileesẹ naa to fi ikede si oju opo ayelujara Instagram wọn sọ pe, iyansẹlodi naa tun jẹ ọna ti awọn fẹ ẹ fi tako bi awọn oṣiṣẹ ajọ amusẹya 'task force' atawọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ, ṣe n gba owó ti ko tọ ọ lọwọ wọn.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Opin ọsẹ to kọja ni ileesẹ NIPOST fi ikede naa sita. Lati igba naa si ni awuyewuye ti n waye lori rẹ.
NIPOST sọ pe ofin tuntun naa yo ṣe iranlọwọ fun awọn 'ojulowo' ileesẹ abani fi nkan ránṣẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
"Àwọn ileesẹ abani fi nkan ránṣẹ nla ni ofin wà fun tẹlẹ, sugbọn ni bayii ti awọn ileesẹ kéékèèké ti darapọ mọ wọn, ofin naa ti gba afikun ati atunse.
" A gbe igbesẹ yii lati mu ki awọn ileesẹ keekeeke o le dagba, ati fun aabo ẹrù awọn onibaara wọn. "

Oríṣun àwòrán, Others
Ofin tuntun naa ni yoo risi eto iforukọsilẹ, gbigba ontẹ ijọba, owo ori, ati ilana fun iṣẹ ṣíṣe.
Botilẹjẹ pe Minisita fun eto ibaraẹni sọrọ ati eto ọrọ aje lori ayelujara Isa Pantami, sọ pe ki ileesẹ NIPOST, dawọ duro l'ori ofin naa, NIPOST kò ti i kede boya oun ti ṣe bẹ ẹ.
Pantami sọ pe igbesẹ NIPOST tako ọrọ ajọ sọ to wa laarin oun ati awọn oludari NIPOST.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Mínísítà àti iléèṣẹ́ Nipost ń jiyàn lórí àfikún owó ìfìwéránṣẹ́ tuntun
Ijọba apapọ ni òun kò lọ́wọ́ sí àfikún owó tí ilé iṣẹ́ NIPOST ń gberò láti fi lé owó àwọn ilé iṣẹ́ tó ń ba ènìyàn fí ẹrù jíṣẹ́, tí ilé iṣẹ́ Nigerian Postal Service kédé láìpẹ́ yìí.
Mínísítà fún ìbáraẹni sọ̀rọ̀ àti ètò ọ̀rọ̀ ajé, Isa Pantami, ló sọ èyí di mímọ̀ nínú ọ̀rọ̀ to kọ sórí àtẹjíṣẹ́ twitter rẹ̀ lówùrọ̀ sátide.
Ó ní àfikún owó náà kò sí nínú ǹkan tí òun búwọlù fún wọ́n ní ọjọ́ Jímọ̀, ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kéje ọdún yìí.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5
Ó fi kun pé, òún sọ fún alága NIPOST àti àdari ilé iṣẹ́ náà lọ́jọ́ Ẹtì pé, kí wọ́n ṣì dá ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ dúró náà kí wọ́n sí fí abájáde wọ́n ránṣẹ́ si ilé iṣẹ́ tọ n dari wọ́n lọ́jọ́ Ajé."
Afíkún owó láti bẹ̀rẹ̀ ilé iṣẹ̀ ìfẹrù ránṣẹ́, yóò mú kí fífí ẹrù ránṣẹ́ láti ibì kan sí omíran gbé owó lórí síi ní orílẹ̀ -èdè Nàìjíríà.
Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ni gba ọ̀rọ̀ náà bí ẹni gba igbá ọtí lórí ayélujára.
- Ikú Barakat Bello ní Akinyele kó oríire bá mọ̀lẹ́bí rẹ̀
- Ìpolongo ìbò Obaseki mú làásìgbò lọ́wọ́ láàfin Ọba Benin, èèyàn mẹ́wàá farapa
- Wo àwọn nǹkan tí o kò mọ̀ nípa 'Church of Satan'
- Lizzy Anjọnrin fẹ̀si fáwọn agbọ́yì-sọ̀yí lórí ìgbéyàwó rẹ̀, Madam Sajẹ dasójú ilé iṣẹ́, àti àwọn ǹkan míràn tó ṣẹlẹ̀ lágbo tíátà lọ́sẹ̀ yìí

Oríṣun àwòrán, Twitter/ Barr Bisi Adegbuyi
Kí ló dé tí wọ́n ṣe fi owó kún NIPOST?
Gẹ́gẹ́ bí NIPOST ṣe sọ, àwọn ilé iṣẹ́ bi DHL, UPS àti FEDEX tí wọ́n máa ń báni fẹ̀rù ránṣẹ́ sí òkè òkun tàbi gba ẹrù wá láti òkè òkún, yóò maa san ogún mílíọnù náírà, tí wọ́n bá fẹ́ gba ìwé àṣẹ láti bẹ̀rẹ̀ irú ilé iṣẹ́ bẹ́ẹ̀.
Wọ́n yóò sì maa san mílíọ̀nù mẹ́jọ náírà lati sọ ìwé àṣẹ̀ wọ́n dọ̀tun lọ́dọọdún.
Àwọn ilé iṣẹ́ tó jẹ́ pe abẹ́lé ni wọn tí ń ṣe iṣẹ́ tiwọ̀n, yóò maa san mílíọ̀nù mẹ́wàá Náírà láti gba ìwé àṣẹ, tí wọ́n yóò sì máa san mílíọ̀nù mẹ́rin náírà láti sọ ìwé àṣẹ wọn dọtun lọ́dọọdún.

Oríṣun àwòrán, NIPOST
Ilé iṣẹ́ NIPOST sọ pé ìlànà tuntun yìí ní láti ran àwọn ojúlówó ilé iṣẹ́ ìbáni fẹrù ranṣẹ́ lọ́wọ́ àti láti le àwọn ilé iṣẹ́ arúmọjẹ tó ń ṣe irú iṣẹ́ náà wọle, kí ààyè le gba àwọn ojúlówó .
Agbẹnusọ ilé iṣẹ́ náà, Franklin Alao, nínú àtẹjáde tó fi síta fún àwọn NPO lọ́jọ́ Ẹti ló ti sàlàyé pé, àwọn tó jẹ́ ojúlówó oníṣẹ́ ìfẹrù ránṣẹ́, to mọ ìtumọ̀ iṣẹ́ yìí, kò ni bá wọ́n sí nídi irú ìfẹ̀hónú hàn bẹ́ẹ̀.
"Ìlànà tuntun yìí kìí ṣe láti mú kí nǹkan nira fún àwọn olókoòwò kéékèèké, sùgbọ́n láti mu ìdàgbàsókè bá wọn ni, yóò túbọ mú ki àwọn ti o ni nǹkan ṣe lé fa ojú àwọn oníbàárà wọ́n mọ́ra síi ni"
Ó ní ilé iṣẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti ètò ọ̀rọ̀ ajé ló fún àwọn ni àsẹ fún ìlànà yìí, ti wọ́n si pee ni èyí to ṣe pàtàkì láti mójú tó, ki àwọn náà to gba láti kédé rẹ̀.
Ó ní èyí sì gbà ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrò kí àwọn tó fẹnukò lórí àwọn owó tí àwọn fi síta.

Oríṣun àwòrán, Others
Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló ti bọ́ sórí ayélujára láti fẹ̀hónú hàn lórí ìgbéṣẹ̀ tuntun yìí, wọ́n ni ìgbésẹ̀ yìí lé lé àwọn olókoòwò kéékèké wọlé.
Báwo ní èyí yóò ṣe kan ọlọ́dani àti àwọn olókoòwò?
Nítori àjàkálẹ̀ ààrùn Coronavirus, ti ètò kónílé o gbélé sì wà, ọ̀pọ̀ àwọn olókoòwò ló n ló àwọn ilé iṣẹ́ ìfẹ̀rujíṣẹ́ láti tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ ajé wọn.
Bí owó àwọn ènìyàn yìí bá ga sí, ó túmọ̀ si pé, owó ọja yóò wọ́n sii.
Àwọn ara ìlú yóò maa san owó gọbọi fún ọjà ti wọ́n ba ra nítori owó ti wọ́n fi n gbe ọjà wọlé.
Èyí tún túmọ̀ si pé, àwọn ènìyàn kò ni máa rajà láti ọ̀nà jínjìn mọ nítori owó ati fí ránṣẹ́ yóò ti pọ̀ jù.
Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣiṣẹ́ yìí ni yóò pàdánù iṣẹ́ wọn ti àwọn ènìyàn kò bá ra ọjà tó nílò láti fi ránṣẹ́ si ibò míràn.

















