2019 Budget: Ètò àbò, ètò ẹ̀kọ́, gbégbá orókè nínú àbádòfin N8.83 trillion tí Buhari gbé kalẹ̀

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmad
Aarẹ muhammadu Buhari ti gbe abadofin iṣuna fun ọdun 2019 jade, o si ti gbe e kalẹ siwaju awọn aṣofin apapọ.
Iṣuna to din diẹ ni triliọnu mẹsan naira ni aarẹ gbe kalẹ.
Amọṣa, ẹka ileeṣẹ ọrọ abẹle, ọrọ abo, eto ẹkọ ati ilera ni o lewaju ninu ipin owo lẹkajẹka ninu eto iṣuna naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ninu agbekalẹ aarẹ lori iṣuna ọdun 2019, ileeṣẹ ọrọ abẹle lo gba ipin owo ti o pọju pẹlu ẹẹdẹgbẹta biliọnu naira o le diẹ, (N569.07bilion), ileeṣẹ ọrọ abo yoo gba ojilenirinwo o din marun un biliọnu naira (N435.62b), ọtalenirinwo o le meji biliọnu naira (N462.24b) fun eto Ẹkọ ati okoolelọọdunrun o din marun naira (N315.62b) fun eto ilera.
Aarẹ ni eto abo ati idagbasoke ọmọniyan wa lara koko ohun ti iṣuna naa yoo mu gbọ julọ.

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmad
O fi kun un pe iṣuna to din diẹ ni triliọnu mẹsan naira naa ni wọn pin si owoona atigbadegba (Recurrent N4.04 trn), owoona lori sisan gbese (Debt Servicing N2.14trn), Owoona lori awọn iṣẹ pataki gbogbo (Statutory transfer N492.36b), owoona lori awọn akanṣe iṣẹ (Capital Expenditure N2.031trn)
2019 Budget: Ààrẹ Buhari gbé àbádòfin N8.83 trillion kalẹ̀
Aarẹ Muhammadu Buhari gbe abadofin iṣuna ti o din diẹ ni triliọnu mẹsan naira kalẹ fun ọdun 2019.
Aarẹ kede eyi lasiko ti o fi n gbe abadofin iṣuna naa kalẹ niwaju awọn aṣofin apapọ ni ọjọru.
Aarẹ Buhari ni afojusun abadofin naa ni lati tubọ fi ẹsẹ eto ọrọ aje Naijiria rinlẹ ni oju ọna ọrọ aje ti o ko akoyawọ lati mu awọn ọmọ orilẹede Naijiria kuro ni ọgbun oṣi ati iṣẹ.
Aarẹ Buhari ni abadofin oju awo lawo fi n gbọbẹ lawọn fẹ fi eto iṣuna ọdun 2019 ṣe.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ori ọgọta dọla lori jala epo kan ni wọn gbe eto iṣuna naa pẹlu ireti pe orilẹede Naijiria yoo maa pọn jala epo rọbi ti o le ni miliọnu meji lojumọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Bakan naa ni o fi kun un pe iṣuna naa yoo da lori paṣiparọ owo ni naira marunlelọọdunrun si dọla owo ilẹ Amẹrika kan.
Aarẹ Buhari ni awọn aṣepati akanṣe iṣẹ ti o wa nilẹ ni wọn yoo tubọ mojuto ni inu saa eto iṣuna ọdun 2019 gẹgẹ bi ijọba apapọ ṣe ṣe ni saa iṣuna 2018 ti o n pari lọ.












