Yollywood: Ẹ wo àwọn ohun tí ẹ kò mọ̀ nípa Mama Rainbow tó pé 77 lóniìí

Oríṣun àwòrán, MAMARAINBOWOFFICIAL
Idowu Philips, ti apele rẹ n jẹ Mama Rainbow, tabi Iya Rainbow jẹ mọlumọọka oṣere tiatia Yoruba.
Wọn bi Mama Rainbow ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 1942, ni ilu Ijẹbu Ode, ipinle Ogun, to wa ni iwọ oorun orilẹede Naijiria.
Orukọ "Rainbow" ti wọn n pe Idowu Philips wa latinu Oṣumare to jẹ "Rainbow" ni ede Gẹẹsi.
- World Food Day: Wo àwọn oúnjẹ ìṣẹ̀mbáyé Yorùbá tó ti ń di àpatì
- Ẹ gbà mi o! Wọ́n tún ń lépaà mi o! - Kemi Afolabi
- Àwọn ọmọ Nàíjíríà ń bèèrè pé taa ní ààrẹ Nàíjíríà ní Aso Rock?
- BBC 100 Women 2019: Wo ọmọ Nàíjíríà kan tó wà nínú wọn
- Njẹ́ o mọ pé N3000 ló o sàn láti gbà kaadi ìdánimọ̀ míì bí tí tẹ́lẹ̀ bá sọnù?
Orukọ naa si wa lati orukọ ẹgbẹ tiata ọkọ Mama Rainbow tẹlẹ ri.
Ọkọ Mama Rainbow ni Augustine Ayanfemi Phillips, to ṣe iṣe pẹlu aṣaaju-ọna ninu iṣẹ oṣere tiata, Sir Hubert Ogunde, fun ọpọ ọdun.
Iya Rainbow kawe alakọbẹrẹ ati girama ni Ijẹbu Ode, ni ilu kan naa si lo ti lọ ile iwe awọn nọọsi.
Iṣẹ nọọsi ni agba oṣere yii n ṣe fun ogun ọdun o le diẹ, ko to dara pọ mọ ẹgbẹ oṣere tiata.
Ọlọrun fun Iya Rainbow ni ọmọ marun un.
Lẹyin ti Augustine Ayanfemi Phillips to jẹ ọkọ Iya Rainbow jẹ Ọlọrun nipe ni o darapọ mọ iṣẹ oṣere tiata ni kikun.

Oríṣun àwòrán, MAMARAINBOWOFFICIAL
Ere agbelewo ti Mama Rainbow kọkọ ṣe ni Ẹru, lẹyin naa lo kopa ninu Ajẹ Niya mi, ṣugbọn ere tiata to sọ ọ di mọlumọọka ni Aṣiri Nla.
Mama Rainbow ti kopa ninu ọpọlọpọ ere agbelewo ati ere ori itage.
Lara awọn ere agbelewo ti Iya Rainbow ti kopa ni Back to Africa, lọdun 1997, Lagidigba, to jade lọdun 2000, Kootu Ọlọrun, lọdun 2007, Taiwo Taiwo apa kini ati apa keji to jade lọdun 2008, Oga Bolaji to jade lọdun 2018, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Mama Rainbow ti kopa ninu ere to le ni ẹẹdẹgbẹta, ọpọlọpọ lara awọn ere naa jẹ ni ẹde Yoruba, ṣugbọn o tun ma n kopa ninu ere ti wọn ti n sọ ede Gẹẹsi.













