Bristow Helicopters: Awakọ̀ òfurufú tó lé ní ọgọ́rùn ún pàdánù iṣẹ́ toríi Covid-19

Ọkọ ofurufu Bristow

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọkọ ofurufu Bristow ti kọ iwe lọ gbe ile rẹ fun awakọ ofurufu to le ni ọgọrun lorilẹede Naijiria.

Ileeṣẹ Bristow Helicopters ni ko dun mọ awọn ninu pẹlu bi wọn ṣe gba iṣẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ wọn, amọ ipa ti arun Coronavirus ni lara ileeṣe wọn lo mu ki wọn gbe igbesẹ naa.

Ileeṣẹ Bristow ni atunto ti awọn ṣe ni ileeṣẹ naa, lo fa ki awọn le awọn oṣiṣẹ to le ni ọgọrun naa.

Wọn fikun wi pe kii ṣe awọn ọmọ Naijiria nikan ni ọran naa ba, ati awọn oṣiṣẹ wọn to wa loke okun naa faragba ninu iyoniniṣẹ naa.

Iwadii fihan pe ọna ti ọpọlọpọ ileeṣẹ ofurufu ni Naijiria n pa fi pa owo wọle ni gbigbe epo rọọbi ati afẹfẹ gaasi lọ si oke okun.

Amọ arun Coronavirus ti fa ifasẹyin ba ẹka iṣẹ naa, eleyii to fa idaduro ati airiṣẹ ṣe fun awọn ileeṣẹ ọkọ ofurufu ni Naijiria, eleyii ti Bristow wa lara wọn.

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ awakọ ofurufu, The National Association of Aircraft Pilots and Engineers(NAAPE) ti gun le iyanṣẹlodi lati tako igbese ileeṣẹ Bristow naa, lai fun awon oṣiṣẹ ni ajẹmọnu to tọ si wọn.

Ninu ọrọ wọn, ẹgbẹ NAAPE ni awọn ko ni da iyanṣẹlodi naa duro lai ṣe pe ileeṣẹ Bristow gbe igbese lati yi ipinnu wọn pada.

O ti di ọjọ kẹta bayii ti ẹgbẹ NAAPE naa gunle iyanṣelodi ọhun.

Igbese ileeṣẹ Bristow naa tẹle eleyii ti ileeṣẹ ọkọ ofurufu Air Peace naa gbe pẹlu bi wọn ṣe le awọn awakọ ofurufu to le ni aadọrin, ti wọn si ge owo oṣu awọn oṣiṣẹ kuru.

Ìdí tí Air Peace fi fọwọ́ òsì júwe ilé fún awakọ̀ ààdọ́ta rèé

Balùú

O kere tan awakọ baalu aadọrin ni ileesẹ ọkọ ofurufu Air Peace ni Naijiria wọn ti fọwọ osi juwe ile fun.

Ileeṣẹ naa ninu atẹjade kan ti Stanley Olisa fi sita sọ pe igbesẹ naa nira fawọn ṣugbọn ko si ohun tawọn le ṣe ju pe ki awọn din owo oṣu ku tabi kawọn le awọn eeyan lẹnu iṣẹ.

O ni awọn le awọn eeyan lẹnu iṣẹ ki awọn baa le ribi gbọ awọn bukata miran ti o wọ awọn lọrun lasiko Covid-19 yi.

Ni nkan bi ọsẹ meloo kan ni ọga agba ileeṣẹ naa Allen onyema ke gbajare pe ki ijọba ṣe iranwọ fawọn to wa lẹka ofurufu ki wọn ba fi le lalauyọ lasiko yii.

Ninu owo iranwọ biliọnu mẹfa ti ijọba Naijiria la kalẹ lati si awọn ẹka ọrọ aje pada, awọn to wa ni ẹka ofurufu ko ni ipin ninu rẹ.

Stanley Olisa ṣalaye pe awọn kọkọ ṣe agbeyẹwo adinku owo oṣu ni ida oodo is ogoji ṣugbọn nigba ti nkan koi rọgbọ lawọn ba fi da awọn oṣiṣẹ silẹ.

Toun ti pe ẹka ofurufu ti bẹrẹ iṣẹ pada ni Naijiria ko yi nkan pada nitori pe ipalara ti ba ẹka naa eyi ti ko ni atunṣe.

Ẹgbẹ awọn oniṣẹ irinajo ofurufu lagbaye ti ṣaaju fi ikilọ sita pe awọn eeyan yoo padanu iṣẹ nitori pe pẹlu bi ọjọ ṣe n gori ọjọ ti awọn ileeṣẹ ofurufu ko fi ṣiṣẹ ni Naijiria n padanu miliọnu mẹtadinlọgọrun Naira loṣooṣu.

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuahri

Ààrẹ Buhari wọ́gilé kí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba máa wọ ọkọ̀ bàálù olówó gọbọi

Aarẹ Buhari ti fagile ki awọn oṣiṣẹ ijọba maa wọ ọkọ baalu olowo gọbọi tabi ipele ẹlẹ́yẹ̀ẹ, eleyi ti oloyinbo n pe ni 'Business Class'.

Ṣugbọn eleyii yọ awọn minisita, akọwe agba, olugbaninimọran pataki, oluranlọwọ pataki fun aarẹ, awọn alaga ile iṣẹ, atawọn lọga lọga agba patapata, tori awọn ni tiwọn yoo ṣi maa wọ olowo gọbọi yii.

Wọn ni igbesẹ yii yoo mu adinku ba bi ijọba ṣe n na owo, paapaa fun awọn irinajo to ba iṣẹ lọ.

Ninu ọrọ ti ọfiisi aarẹ fi sita loju opo Twitter, aarẹ ni gbogbo irin to ba jẹ mọ irin okeere gbọdọ jẹ eleyii ti yoo mu anfani ba orilẹede Najiria.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ninu eto tuntun yii, gbogbo ile iṣẹ ijọba ni lati jẹ ki ọfiisi akọwe ijọba apapọ mọ nipa irin ajo ti wọn ba fẹ gun le lọdọdun.

Eleyii yoo mu ki ọfiisi akọwe ijọba le buwọ lu irufẹ irinajo bẹẹ ni ibẹrẹ ọdun, ko to di pe ijọba yoo fi aye gba irin ajo ọhun.

Ọfiisi aarẹ tun ni, ijọba ko ni fọwọ si owo miiran lẹyin ti irin naa ba ti pari.

Ikede tuntun yii ni ọfiisi aarẹ gbe jade lẹyin ti aarẹ Buhari ti kede tiriliọnu mẹwa naira le diẹ, owo iṣuna fun ọdun 2020.

Ninu iṣuna naa ni aarẹ ti kede owo ori tuntun to jẹ ida meje abọ, gẹgẹ bi ọrọ ti ofiisi aarẹ sọ.