Amotekun: Ẹgbẹ́ fijilanté pariwo síta lórí ìlànà ìgbanisíṣẹ́ ikọ̀ Amotekun ní ìpínlẹ̀ Oyo

Oríṣun àwòrán, Western Nigeria security network
Adari ẹka abo oju lalakan fi n ṣọri ni Naijiria, Vigilante Group of Nigeria, VGN, ẹka ti ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Ọladeji Olowolafẹ ti ke gbajare sita lori eto abo ẹkun iwọ orun gusu orilẹede Naijiria ti a mọ si Amọtẹkun.
Ọgbẹni Olowolafẹ ṣalaye pe ọrọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ ti dọwọ ru koda o ti d'ẹsẹ ru bi ẹsẹ telọ.
O ni afaimọ ki iṣẹ ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ maa ja ireti ọpọlọpọ to n foju sọna fun un kulẹ.
- Ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ti ń fi ọtí àmupara bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ní kí ìjọba dẹwọ́ọ òfin títà ọtí lásìkò Covid-19
- 'Ọkọ mi mú ọ̀bẹ jáde lápò, ó sì gé imú mi jábọ́...'
- Èèyàn 78 kú ó lé ní 4000 tó farapa níbi ìbúgbàmù tó wáyé ní Beirut, Lebanon
- Ariwo ayọ̀ sọ nílé Remi Surutu, ọmọ rẹ̀ mú ọkọ wale
- Inú odò ni wọ́n ti rí òkú ọmọ ọdún méjì tó sọnù l'ọ́jọ́ ọdún Eid nílùú Ibadan
- 'Sẹ́nétọ̀ Abiola Ajimobi wà lọ́run rere'
O ni ọna ti awọn alaṣẹ ikọ naa ni ipinlẹ Ọyọ fi n gba awọn eeyan si ikọ naa ko bojumu.
O ni oun ti o yani lẹnu ni bi awọn alaṣẹ ikọ naa ni ipinlẹ Ọyọ ṣe n ni ki awọn to fẹ dara pọ mọ ikọ naa o lọ maa forukọ silẹ ni ori ayelujara.
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, ohun kan to le mu ki ajọ naa o kẹsẹ jari lori eto igbaniwọle fawọn to ba fẹ ba a ṣiṣẹ ni lati ko awọn olori ikọ alaabo oju lalakan fi n ṣọri atawọn alaabo ibilẹ gbogbo lẹsẹ kuku mọra.
O ni kiko awọn fijilante, ọdẹ ibilẹ atawọn ọmọ ẹgbẹ OPC mọra fun ikọ naa yoo mu ko so eso rere daadaa.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, 'gbogbo awọn to lee ṣe iṣẹ ti a la kalẹ fun ikọ Amọtẹkun kii ṣe awọn to lee ṣe ohunkohun lori ayelujara.'
O ni yiyọ ọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ OPC, Agbẹkọya, ọdẹ ibilẹ ati fijilante kuro ninu awo ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ yoo lẹyin.
Esi adari ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ lori ọr naa.

Oríṣun àwòrán, Western Nigeria security network
Ni ọsẹ diẹ sẹyin ti Oludari fun ikọ Amotekun nipinlẹ Oyo, Ajagunfẹyinti Olayinka Olayanju ba BBC sọrọ lori igbesẹ yii, o ni o di dandan kawọn eeyan to ba fẹ dara pọ mọ ikọ Amotekun fi orukọ silẹ lori ayelujara.
Olayanju ni ko si idi fun awọn ọdẹ ibilẹ to fẹ kopa ninu ikọ Amotekun lati tako igbesẹ fifi orukọ silẹ lori ayelujara.
Ajagunfẹyinti Olayinka Olayanju ni ko si ohun to nira ninu fifi orukọ silẹ lori ayelujara nitori ko si ibudo itakun agbaye ti wọn ba lọ lati fi orúkọ silẹ, ti wọn ko ni seranwọ lati ba wọn ṣe e.
"Fọọmu Amotekun naa ko le rara lati ṣe. Ohun ti wọn n beere ni orukọ wọn, adugbo, ẹkun idibo wọn, iriri nipa sise aabo ilu, ẹgbẹ ọlọdẹ ti wọn wa ati Baalẹ wọn."
Bakan naa ni oludari ikọ Amotekun nipinlẹ Oyo fikun pe awọn to ba fi orukọ silẹ yoo mu fọọmu naa tọ Baalẹ ati asofin to wa lati ẹkun idibo wọn lọ, ti awọn mejeeji yoo si buwọlu u.














