Abiola Ajimobi: Ìtùnú tí mo ní nípa ikú ọkọ mi, ni pé Sẹ́nétọ̀ Abiola Ajimobi rí ọ̀run rere wọ̀- Florence Ajimobi

Abiola Ajimobi pẹlu Aya rẹ Florence

Oríṣun àwòrán, Instagram/abiola ajimobi

Iyawo gomina ana ni ipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi to d'oloogbe l'oṣu kẹfa ọdun 2020, arabinrin Florence Ajimọbi ti ṣalaye wi pe itunu kan ṣoṣo ti oun ni lẹyin iku ọkọ oun ni pe o ri ọrun rere wọ lalaafia.

Lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ akọroyin ni ipinlẹ Ọyọ fi bẹẹ wo nilee rẹ to wa lagbegbe Oluyọle nilu ibadan ni arabinrin Florence Ajimọbi sọrọ idaniloju naa.

O ni omi ẹkun n gba oju oun kan nigbagbogbo nitori pe oun a maa ṣe afẹri awọn nnkan to pọ nigba ọkọ oun.

"Mo n sunkun nitori pe mo n ṣafẹri ọkọ mi. Gbogbo nnkan to niiṣe pẹlu rẹ ni mo n ṣafẹri. Ifẹ rẹ, amọran rẹ. Riri i layika mi maa n fun mi ni ọpọlọpọ okun. Oun ni alatilẹyin mi to tobi julọ."

"Ajimọbi wọ ọrun rere, o si wa pẹlu Ọlọrun bayii. Itunu kan ti mo ni niyẹn"

O fi kun un pe, Sẹnetọ Ajimọbi mu iṣẹ iriju rẹ laye ṣẹ.