Abiola Ajimobi: Igbákeji ààrẹ sàbẹwò sí ìyàwó Ajimọbi

Eto adura fun Ajimobi

Oríṣun àwòrán, others

Ọjọ nii pẹ, ipade kii jinna, ki Ọba oke maṣe jẹ ka jẹ gbese.

O ti pe ogoji ọjọ lonii Ọjọbọ ti gomina ana nipinlẹ Oyo, Sẹnetọ Abiola Ajimobi dagbere faye.

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2020 ni opo nla nipinlẹ Oyo naa yẹ, ti erin Ajimobi subu lai le e dide.

Niwọn igba to si jẹ pe ti ọdẹ ba ku, ọdẹ nii soro lẹyin ọdẹ, idi ree ti ẹbi, ara, ojulumọ, atawọn alajọṣepọ rẹ ninu oselu fi korajọpọ sile rẹ l'Ọjọbọ lati sami ogoji ọjọ to dagbere faye.

Eto adura fun Ajimobi

Oríṣun àwòrán, others

Ninu waasi ti wọn gbe kalẹ lati gba awọn eeyan niyanju níbi eto naa, Sheikh Muideen Ajani Bello atawọn agba Alfa to wa nibẹ gba awọn ololufẹ Ajimobi nimọran lati mase jẹ ki ogun rere to fi silẹ parun.

Bakan naa ni awọn eeyan to peju síbi eto naa yonbo iwa rere oloogbe naa, bẹẹ ni wọn ṣe apejuwe rẹ bii Araba nla to n mi igbo kijikiji lagbo oselu ipinlẹ Oyo ati lorile-ede Naijiria lapapọ.

Lara awọn eekan ilu to peju síbi adura ọjọ mẹjọ to waye nile Ajimobi to wa ni Oluyole nilu Ibadan ni Gomina Ipinlẹ Kano, Abudullahi Ganduje ati aya oloogbe, Florence Ajimobi.

Awọn yoku ni igbakeji gomina Ajimobi, Moses Adeyemo, Sẹnetọ Teslim Folarin, Asofin Segun Odebunmi, Adebayo Adelabu atawon agba Alfa loniruuru.

Ṣugbọn ìjọba ipinlẹ Oyo ko peju tabi fi asoju ransẹ sibi adura ọjọ mẹjọ fun Abiola Ajimobi.

Ni ibẹrẹ ọsẹ yii ni igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Rauf Ọlaniyan ṣalaye pe oun ko fi igba kankan binu si iyawo gomina ana ni ipinlẹ naa, Arabinrin Florence Ajimọbi lori awọn iṣẹlẹ gbogbo to ṣẹlẹ lẹyin iku ọkọ rẹ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi.

Ninu ọrọ kan to ba awọn oniroyin sọ ni ile rẹ ni Onimọẹrọ Ọlaniyan ti sọrọ yii.

O ni oun mọọmọ paṣẹ fun awọn ẹṣọ oun lati maṣe fi ọwọ kan ẹnikẹni ni ni kete ti oun ri bi nnkan ṣe fẹ maa lọ nigba naa.

"Mo mọ iru ipo ibanujẹ ti aya gomina ana naa wa, mi o si binu sii lẹyin iṣẹlẹ ọjọ naa. Iwa ọmọluabi gbọdọ wa lara wa.

Mi o ni ko wa tọrọ aforiji o, nitori pe ko si ẹni to gbadura pe ki oun wa ni iru ipo to wa nigba naa, Ibanujẹ lo ṣokunfa ohun to ṣẹlẹ nigba naa.