Alcohol Sanitizer: Èèyàn 86 tó mu ọtí ayédèrú d'èrò ọrùn ní India, ìwádìí bẹ̀rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan eeyan mẹrindinlaadọrun lo ti dero ọrun lẹyin ti wọn mu ọti agbelẹrọ ni ipinlẹ Punjab to wa ni ariwa orileede India.
Lọjọ Abamẹta, awọn ọlọpaa yabo awọn ibudo ti wọn fura si pe wọn ti n ṣe ọti wọnyi ti wọn si mu eeyan marundinlọgbọn.
Lẹnu ọjọ mẹta yii, niṣe ni iye awọn to n ku latari mimu gbarọgudu ọti naa n pọ sii.
- Iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ọlọ́pàá ọ̀mùtí ní ìlú Eko
- Dókítà ọmuti ṣe iṣẹ́ abẹ tó pa olóyún àti ọmọ rẹ̀
- Ó ṣeésẹ kí ọkùnrin tó n mu àmujù ọtí ó maa lo ìwà ipá pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀
- Ẹ̀kọ́ mẹ́jọ tó yẹ kí ilẹ̀ Afirika kọ́ lára àjàkálẹ̀ aàrùn coronavirus
- Ọjọ́ orí wo ló yẹ kí ikùn ẹ̀dá bẹ̀rẹ̀ sí tóbi?
- Mu pàrágá wakọ̀ l'Oyo, kóo kó sí gbaga ìjọba

Oríṣun àwòrán, EPA
Lọdọọdun ẹgbẹgbẹrun awọn eeyan ni o maa n padanu ẹmi wọn nitori pe wọn n mu awọn ayederu ọti wọnyii.
Lasiko arun Covid-19 yi ti awọn ile ọti wa ni titi pa, pupọ lo bẹrẹ si ni mu awọn ọti ayederu yi lati fi rọpọ ọti gidi.
Lọjọ Ẹti, Minisita agba Amarinder Singh pe fun iwadii lori ohun to n ṣeku pa awọn eeyan.
Iroyin sọ pe o ṣeeṣe ki awọn to n pọn ọti gbarọgudu yii ti ṣe ọpọ rẹ kalẹ ti wọn si ti n ta fawọn olounjẹ lẹgbẹ titi ati awọn eeyan lawọn igberiko.
Lọjọ Ẹti, iroyin to kọkọ gbode ni eyi to ni ṣe pẹlu awọn eeyan mẹwa to ku lẹyin ti wọn mu ọti ti wọn fi "Hand sanitiser" po pọ ni ipinlẹ Andra Pradesh to wa ni guusu orileede India.
Lawọn igberiko lorileede India, iku ọwọọwọ nipasẹ mimu ọti ayederu ko jẹ nkan tuntun.
Awọn to n po ọti wọnyii a ma saba lo kẹmika kan ti orukọ rẹ n jẹ Methanol' lati le jẹ ki ọti naa lagbara si.
Bi eeyan ba mu Ethanol, koda ko jẹ diẹ lo mu, o le ṣokunfa ki oju onitọun fọ, ki ẹdọ rẹ bajẹ tabi ki ẹni naa ku.














