Olufon: Ọba Almaroof Adekunle Magbagbeola Olumoyero II, òsìṣẹ̀ àjọ NNPC tó di ọba Ifọn

Oríṣun àwòrán, @NigNewspapers
Olufon ti ilu Ifon-Orolu ni ipinlẹ Osun, Ọba Almaroof Adekunle Magbagbeola Olumoyero II ti tẹri gbaṣọ.
Ori ade naa waja lọjọ Iṣẹgun, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2021 ti a wa yii.
Iroyin ti a gbọ sọ pe Kabiesi mi imi ikẹyin rẹ nile iwosan kan lẹyin aisan ranpẹ.
Wọn bi Ọba Almoroof Adekunle Magbagbeola ni bi i ọdun 1950.
Bo tilẹ jẹ pe ọmọ Yoruba ni, to si jẹ ọmọ Naijiria, orilẹ-ede Ghana ni wọn bii si, nitori pe ibẹ ni awọn obi rẹ fi ṣe ibugbe lasiko naa.
Ọdun 1964 ni igba akọkọ to wa si orilẹ-ede Naijiria lẹyin ti iya agba rẹ sọ pe dandan ni fun un lati pada si Naijiria.
Nitori naa si lo ṣe fi Ghana silẹ, to wa si ilu Oṣogbo lati ma a gbe pẹlu iya agba naa.
Ṣugbọn lẹyin to pari ileewe alakọbẹrẹ, Magbagbeọla sa pada si Ghana, nitori pe ko gbọ, bẹẹni ko le sọ ede Yoruba daadaa.
Ede Ashanti ati Gẹẹsi lo mọ.
Itan sọ pe awọn obi rẹ ni ile to pọ ni Ghana, ṣugbọn wọn fi gbogbo rẹ tọrẹ nigba ti wọn fẹ ẹ pada si Naijiria lọdun 1967 lasiko ti awọn alaṣẹ Ghana paṣẹ pe ki gbogbo ọmọ Naijiria to wa nibẹ pada si orilẹ-ede wọn.
Idile marun-un lo maa n jẹ ọba ni ilu Ifon-Orolu, lara wọn ni Olumoyero ti Ọba Magbagbeọla ti wa.
Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2007 ni wọn fi jọba ilu Ifon nipinlẹ Ọṣun.
Ṣugbọn ṣaaju asiko naa, oṣiṣẹ ajọ to n mojuto epo rọbi ni Naijiria, NNPC ni. Ipo alamojuto (supervisor) lo wa ni ẹka iṣakoso ileeṣẹ NNPC nilu Warri, nipinlẹ Delta.
Ọdun mẹẹdọọgbọn lo fi ṣiṣẹ pẹlu NNPC.
Yatọ si pe o jẹ ọba ilu Ifọn nipinlẹ Ọṣun, oun naa tun ni ọba ilu Ilobu ati Erin-Osun.
- Ọba tí wọ́n jí gbé l'Ekiti gba òmìnira lọ́wọ́ àwọn ajínigbé
- A ti ṣetán láti fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún òmìnira ilẹ̀ Yoruba, a ò níbi kankan ti a fẹ́ sálọ - Ọba Adetokunbo Tejuosoho
- Wọ́n ti kéde ọmọ Ààrẹ Chad tẹ́lẹ̀, Kaka Deby gẹ̀gẹ́ bíi Ààrẹ fìdíhẹ tuntun
- Iléẹjọ́ da ẹjọ́ Jegede, olùdíje PDP l'Ondo nù, Ó ní Akeredolu ni gómìnà
- Ọkọ̀ agbépò gbiná ní Benue, ẹni mẹ́sàn án kú, ṣọ́ọ̀bù 72 ọlọ́já iyebíye jóná
- Màálù 250 tasẹ̀ agẹ̀rẹ̀ wọ oko ní Ilaramọkin, ní ikọ̀ Amotekun bá sọ Màálù àti olówó rẹ sí gbaga

Oríṣun àwòrán, @insightlinkstv
Ẹwẹ, awọn abanikẹdun, ti ọpọ ninu wọn jẹ ọmọ ilu ti kabiesi naa jọba le lori nigabaye rẹ ti n korajọ si aafin rẹ lati ṣedaro.
Adura wa ni pe ki Ọlọrun tẹ baba si afẹfẹ rere, ẹyin ti wọn fi silẹ ko si ni bajẹ.
- Wo àwọn ìkọlù àgọ́ ọlọ́pàá tó ti wáyé lẹ́kùn àríwá gúúsù Nàìjíríà ní lọ́wọ́ yì
- Wo àtúpalẹ̀ nkan tí òmìnira tí àwọn gómìnà fi ọwọ́ sí fún ẹ̀ka ìdájọ́ Naijiria túmọ̀ sí
- Ṣé lóòtọ́ ni Sotayo Gaga ti di ìyá Ọba nílẹ̀ Hausa?
- Àwọn ọlọ́pàá ti dóòlà ọmọbìnrin tí àwọn òbí rẹ̀ so mọ́lẹ̀ fún ọdún 10
- Kí ni ìdí tí àwọn ọmọ Naijiria ṣe fẹ́ kí Isa Pantami kọ̀wé fi ipò sílẹ̀?




















