Amotekun Ondo: Màálù tó bá wọnú oko àgbẹ̀ tó ba ǹkan oko jẹ yóò di títà ní gbàǹjo- ikọ̀ Amotekun

Oríṣun àwòrán, @Amotekun
Ikọ ẹsọ alaabo Amotekun ni ọjọ Aiku kede pe ọwọ wọn ti tẹ awọn maalu ojilenigba le mẹwaa kan to ba oko jẹ ni Ipogun Ilaramokin ati ni Owena ti ijọba ibilẹ Ifedore.
Bẹẹ naa ni wọn ni awọn mu awọn darandaran meji to n dari awọn maalu wọn yi.
Iroyin naa ni oko ti wọn baje to ẹkita ọọdunrun.
A ri gbọ pe nkan oko bi ẹgẹ, koko, ọgẹdẹ agbaagba ati agbado wa lara awọn nkan oko ti awọn maalu wọn yi bajẹ.
Adari ikọ Amọtẹkun ni Ondo, Oloye Adetunji Adeleye sọ fun awọn akọroyin pe kede ti awọn kẹfin lilọ bibọ awọn darandaran lagbegbe wọnyi lawọn ti da ọmọ ikọ wọn sita.
- Amotekun gbàràdá ní ìpínlẹ̀ Oyo
- Orúkọ àwọn tó yege láti darapọ̀ mọ́ ikọ̀ Amotekun ní ìpínlẹ̀ Oyo ti jáde
- Àwọn jàndùkú ṣá ẹ̀ṣọ́ Amotekun àti ọlọ́pàá ní àdá àti àáké n'Ibadan
- Ẹ̀bùn ọdún tuntun tó yááyì ni ikọ̀ Amotekun - Soyinka
- Ànfààní ńlá wà nínú ètò Amọtẹkun, àwọn agbẹjọ́rò ló lè sọ bó yá kò bá òfin mu- Olu Falae
Oloye Adetunji ni: O jẹ iyalẹnu fun wa pe iru ijamba ti awọn maalu wọnyii se soko awọn agbẹ.
Awọn darandaran yii kọkọ doju ija kọ wa sugbọn wọn pada sa lọ.
Amọ sa a ribi mu awọn meji ninu wọn pẹlu maalu ti wọn da wọ inu oko oloko''.
Adeleye salaye pe awọn ko ni ba awọn darandaran yi ja lati le ri itanran gba fawọn agbẹ.
O ni bẹrẹ lati isin, eyikeyi maalu ti awọn ba ri gba pe wọn fi ba nkan oko jẹ, wọn yoo gbe wọn lọ si ileẹjọ ti wọn yoo si ta wọn ni gbanjo'',
''Ileẹjọ la o gbe wọn lọ taa si lu awọn maalu naa ni gbanjo.Ipinnu ijọba ipinlẹ Ondo ati ikọ Amọtẹkun ree lati wakati ọwọ yi lọ''
Ọkan lara awọn agbẹ ti maalu ba oko rẹ jẹ, Ogbẹni Joseph Adeyemi sọ pe nise lawọn darandaran naa gbe maalu wọn wa lati wa jẹ oko.
O ni iru iwa bayi ko sẹsẹ maa waye ati pe ''Lati nkan bi ọdun marun un sẹyin ni wọn ti n se bẹẹ''
Alaga ẹgbẹ Miyetti Allah Alhaji Garba Bello to ba ileesẹ iroyin abẹle Punch sọrọ lori isẹlẹ yi ni awọn setan lati san owo itanran ati ki wọn si jijọ fọwọsowọpọ pẹlu ijọba.
Gẹgẹ bi ohun ti a ri gbọ, wọn ti saaju buwọlu adehun pẹlu ijọba pe awọn darandaran ko ni da maalu wọ inu oko ati pe ti iru rẹ ba waye, wọn yoo san owo itanran.
- "Iṣẹ́ fọga ni mo fi kọ́ ilé ńlá méjì, ti mo sì fi rán àwọn ọmọ mi lọ fásitì"
- Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa líìgì bọ́ọ̀lù tuntun tí ó fẹ́ jáde ní Yúróòpù
- PDP borí ìdìbò káńsù ní Rivers, AAC, SDP fárígá
- Ọwọ́ tẹ àwọn ọmọ ogun méje tó ń pèsè ohun ìjà fún àwọn agbésùmọ̀mí
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ afurasí 45 lórí ọ̀rọ̀ ìkọlù ẹgbẹ́ òkunkùn tó wáyé ní Ikẹrẹ Ekiti- Agbẹnusọ Ọlọ́pàá
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Makinde pàṣẹ pé kí wọ́n wó iléègbé àwọn òṣìṣẹ́ BCOS ní Ibadan?




















