Oduduwa Nation: Àwọn tó ń polongo Oduduwa Nation fẹ́ ba àláàfíà, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ ni- YWG

Ami idanimọ ẹgbẹ́ YWG

Oríṣun àwòrán, YWG

Ọjọ Satide, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2021 ni oriṣiriṣi ẹgbẹ ko ara wọn jọ ni gbọngan Mapo, ni agbegbe Ọja-Ọba nilu Ibadan, lati tubọ polongo idasilẹ Oduduwa Nation.

Ṣugbọn ṣa, ẹgbẹ to wa fun igbaye-gbadun ẹya Yoruba, Yoruba Welfare Group, YWG, ti sọ pe awọn eeyan to n polongo igbesẹ yii ko le paṣẹ nkan ti Yoruba o sẹ.

Aarẹ ẹgbẹ YWG, Abdulhakeem Alawuje, ninu atẹjade to fi sita ni ọjọ Satide, fi ẹsun kan awọn to n polongo idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa, pe wọn fẹ ẹ ba alaafia, ifẹ ati iṣọkan to wa nilẹ Yoruba jẹ ni.

O ni nkan ti ko ni i bojumu, ni ki awọn ọdọ ati araalu yọnda ara wọn lati jẹ ohun elo idaluru, lọwọ awọn iranṣẹ Satami.

"Igba ikẹhin re e ti a o fi ikilọ sita fun awọn to wa nidi ijijagbara oṣelu, pe ki wọn o dẹkun radarada ti wọn n ṣe nilẹ wa.

"Ilẹ Yoruba ko le jẹ ibi ti wọn o ti ma a pilẹ iwa ọdaran."

Àkọlé fídíò, hhhhhh

Bakan naa ni Alawujẹ ke si gbogbo awọn ọba nilẹ Yoruba pe ki wọn o fi ewe ọmọ mọ awọn eniyan naa l'eti, nitori pe "ko ni i bojumu ki a maa gbe igbesẹ tako ara wa ni ẹkùn kan naa".

O fi ẹsun kan pew awọn to n lewaju awọn eeyan naa, paapaa Ọjọgbọn Banji Akintoye, n ṣe bẹ ẹ nitori imọtara ẹni nikan.