Oduduwa Republic: Oba Yoruba Bauchi ní wíwọ ara wọn Yorùbá àti Hausa kò ní kí Yorùbá má ya kúrò ní Nàìjíríà

Awọn ọmọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, Amani

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Oba Yoruba ni Bauchi, Alhaji Tirimisiyu Adegoke ti fesi si ọrọ ọmọ ẹgbẹ Yoruba, Yoruba welfare group (YWG) to sọ pe awọn ko fẹ Oduduwa Republic.

Oba Yoruba Bauchi sọ pe lootọọ ni Hausa ati Yoruba ti wọ inu ara wọn, amọ iyẹn ko ni ki Yoruba maa yapa kuro lara orilẹede Naijiria.

Oba Adegoke ni ti Yoruba ba maa lọ, wọn ni lati joko pẹlu awọn Hausa ki wọn jọ sọ asọyepọ lọna ti ko ni fa ija.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Ogun ni emi ko fẹ, ti aṣoyepọ ba le waye, Yoruba ni lati fi ọgbọn ṣe ọrọ naa ko maa ba mu wahala dani.

Àkọlé fídíò, Onpetu Ijeru: Akala ní torí Aláàfin kò ṣúgbàá òun fún sáà kejì, ló ṣe ní kí pín ipò alága

Otitọ ni pe ọpọ Hausa ti fẹ Yoruba ni iyawo, awọn Yoruba naa ti fẹ Hausa, a ti wọ ara ra ṣugbọn a gbọdọ sọ asọyepọ,'' Oba Adegoke lo sọ bẹẹ.

Oba Yoruba Bauchi ko ṣai sọ pe oun ko mọ ohun kan nipa ẹgbẹ Yoruba YWG ti wọn sọrọ yii gan an.

O fikun ọrọ rẹ pe, ko si ọba Yoruba ni Kaduna ti ẹgbẹ YWG ti bawọn akọroyin sọrọ.

Sunday Igboho, àwa Yorùbá lókè Ọya kò wálé, a kò fẹ́ Oduduwa Republic - YWG

Awọn Yoruba loke ọya

Oríṣun àwòrán, Abdulhakeem Adegoke Facebook

Ẹgbẹ ọmọ Yoruba nipinlẹ mọkandinlogun to wa lapa ariwa orilẹede Naijiria, Yoruba welfare group (YWG) ti sọ pe awọn ko faramọ yiyapa kuro lara Naijiria, lati da Oduduwa Republic silẹ.

Nibi ipade awọn akọroyin to waye lọjọ Aiku niluu Kaduna, aarẹ ẹgbẹ YWG, Abdulhakeem Adegoke sọ pe, awọn Yoruba to wa nilẹ Hausa ko fẹ orilẹede mii lẹyin orilẹede Naijiria.

Ọgbẹni Adegoke ṣalaye pe, awọn Hausa ti gbawọn Yoruba tọwọ tẹsẹ lati igba tawọn ti n jọ n gbe papọ.

''A n sọrọ gẹgẹ bi aṣoju gbogbo ọmọ Yoruba to wa ni ipinlẹ mọkandinlogun nilẹ loke Oya pe, ọmọ Naijiria ni wa, a ko si si lara awọn to n beere fun Oduduwa Nation.

Àkọlé fídíò, Bed Wetting: Tolulope Joseph ní ò lé ní ogún ọdún tí òun fi tọ̀ sílé kí ìwòsàn tó dé

Awọn Yoruba atawọn Hausa ti wọ inu ara wa wọn, awọn baba nla wa nilẹ Yoruba ti wa nilẹ Hausa fun bii igba ọdun.

Ọpọ ninu wa lo ti fẹ awọn Hausa gẹgẹ ọkọ tabi iyawo, bakan naa lawọn Hausa ti fẹ Yoruba.

Ati pe, okoowo wa nilẹ Hausa ju tiriliọnu marun un lọ, gbogbo awa Yoruba ti a wa nilẹ Hausa si tun ju ipinlẹ mẹta nilẹ Yoruba lọ.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Nitori naa, a ko le lọ darapọ mawọn ti ko bikita nipa ẹmi ati dukia wa lasiko yii,'' Ọgbẹni Adegoke lo ṣalaye bẹẹ.

Eekan ilẹ Yoruba, Ọjọgbọn Banji Akintoye ati ajijagbara Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho wa lara awọn aṣaaju to n beere fun yiyapa Yoruba kuro lara Naijiria lati da Oduduwa Nation silẹ.