Sunday Igboho's latest on Oduduwa Republic: Ìràn Yorùbá ò ní ìṣọ̀kan rárá ló ń fa gbogbo èyí

Àkọlé fídíò, Báa ṣe lọ́pọlọ tó, ẹnu Yorùbá ò kò, ọgbọ́n táa gbúdọ̀ dá rèé - Ìpàdé àgbààgbà Yorùbá n'Ibadan

Awọn agbaagba ilẹ Yoruba ti korajọ nilu Ibadan, ipinlẹ Oyo láti jọ jiroro lorii aṣeyọri orilẹede Yoruba ti wọn n ja fun.

Alagba Taiwo Oyerinde to jẹ ọkan lara wọn ni ọpọlọpọ ọmọ Yoruba lo ti kọ iwe si ajọ isọkan agbaye ti wọn n pe ara wọn ni oniruuru oye tori onikaluku fẹ maa gba oriyin, "wọn o ṣe e tori ilu, bikoṣe tori orukọ wọn".

Ipade naa waye laarin apapọ gbogbo ẹgbẹ Yoruba lagbaye ni ilu Ibadan tii ṣe olu ilu ipinlẹ Oyo.

"Awọn kan wa to jẹ pe wọn ti jẹ dodo wọn le sọ ododo mọ tori nkan ti wọn fẹ da".

O ni gbogbo eyi lo maa n mu ọrọ alunfanṣa jade lẹnu awọn Yoruba sirawọn.

Ẹlomiran ni aisi ifọwọsowọpọ lo n fa aisi irẹpọ laarin iran Yoruba.

Wọn tun ṣepade yii lori pe wọn ni lati pawọpọ ki awọn ipenija to n koju iran naa le di afisẹyin bi eegun ṣe n fi aṣọ.