60 years married Benjamin Awoyemi: Ó dá mi lójú pé kò sí ẹni tí ọkọ mi ń ro ẹjọ́ mi fún
Ifẹ ẹlẹyẹle gaan leyii to jẹ pe afori afọrun ki n maa ba ẹ lọ ni titi ayeraye.
"Gbogbo ija wa, ori bẹẹdi ni yoo ti bẹrẹ, ori bẹẹdi naa si ni yoo ti pari. A o ki n joko ro ẹjọ ara wa fun mọlẹbi kankan tabi ọrẹ".

Idile Benjamin Awoyẹmi ti wọn ti ṣe igbeyawo fun odindi ọgọta ọdun gba BBC Yoruba lalejo ni ile wọn.

Baba Benjamin ni lati igba ti awọn fẹ ṣe iyawo lawọn ti wo bi igbesi aye ẹda ṣe maa n ri ti awọn si ti kọ iwa ara awọn lati mọ bi wọn ṣe lee ba ara wọn gbe.
Afọkansi ati igbọraẹniye ṣe pataki ninu igbeyawo gẹgẹ bi baba ati mama Benjamin ṣe sọ ọ.
Gbogbo ohun ti iyawo mi ba ti ṣe, a jọ mọọ ni, ko sohun to jọ pe ki n ma mọ nipa nkan ti iyawo mi ba ṣe.
Ni ti mama Benjamin, o ni oun ṣa n gbadura pe ki Ọlọrun tọ oun sọna nigba ti baba Benjamin kọ inu ifẹ si i, Ọlọrun si lo tọka rẹ si i ti oun ṣe fẹ ẹ.
- Ọlọ́pàá kò tíì gbọ́ bóyá wọ́n jí àwọn ọmọ ìjọ RCCG mẹ́jọ gbé! Àmọ́ ohun táa mọ̀ rèé
- Kò sí olóṣèlú tí wọ́n fi tọ́ lẹ́nu wò pé kó di ààrẹ Naijiria ní 2023 tí kò ni tọ ọ́ lá - Fayemi
- Àjọ elépo rọ̀bì, NNPC sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀kúnwó epo tuntun
- Oríire déé! Ilé aṣòfin ti buwọ́lu Adewale Adeyemo ẹni ọdun 39 bíi igbákejì adarí ẹ̀ka ètò ìsúná ní ilẹ̀ Amẹrika
- Gómìnà Sanwo-Olu gba gómìna tuntun fún ìpínlẹ̀ Eko lálèjò
- Ìdí tí NIN rẹ fi ṣe pàtàkì láti forúkọsílẹ̀ fún ìdánwò JAMB 2021 rèé
"Ó kéré ó tóbi, ko si iru igbeyawo teeyan le ṣe ti ko ni ni iṣoro". Amọ Iyaafin Benjami ni bo ba ṣe n yọju ni Ọlọrun n mu ọna abayọ ati ojuu wa.
Iriri awọn mejeeji yii kọja ohun ti eeyan le lọ san owo lati jokoo si kilaasi maa kọ. Ẹkọ pọ ti ẹ le kọ ti gege wa o ni lee kọ tan afi ki ẹ wo o ninu fidio naa.

