RCCG members kidnap: Ọlọ́pàá ní àwọn kò gbọ́ ohun kan nípa bó yá àwọn agbébọn jí ọmọ ìjọ RCCG mẹ́jọ

Ọkọ ijọ RCCG

Oríṣun àwòrán, Facebook/Eje Faraday

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna ti sọ pe ko si ohun to jọ iroyin to lu ori ayelujara pe awọn agbebọn ajinigbe tun ti ji ọmọ ijọ Redeemed Christian Church of God(RCCG) mẹjọ gbe lọ.

Iroyin naa to gbalẹ kan lori ayelujara sọ pe awọn eeyan ti wọn jigbe naa jẹ ọmọ ijọ RCCG ti ẹkun Trinity Sanctuary niluu Kaduna.

Iroyin naa sọ pe iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ lọjọ Ẹti nigba tawọn ọmọ ijọ RCCG ọhun n rinrin ajo lopona Kachia nibi ti wọn ti n lọ fun eto kan.

Ọgbẹni Eje Faraday lo fọrọ naa lede loju opo Facebook rẹ ni bii ago meje ọjọ Ẹti.

Ọgbẹni Faraday sọ loju opo Facebook rẹ pe gbogbo ero to wa ninu ọkọ bọọsi tawọn ọmọ ijọ RCCG naa wa ni wọn jigbe lọ tan.

Ẹnikan to tun jẹ oṣiṣẹ ijọ RCCG sọ fun iwe iroyin Punch pe awọn ọmọ ijọ naa n lọ fun eto ijere ọkan fun Ọlọrun nigba ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.

O ni awọn agbebọn naa ni ki wọn kuro ninu bọọsi ti wọn wa pe ki wọn wọ eleyii tawọn gbe wa.

Ṣugbọn agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa to ba BBC Yoruba sọrọ, ASP Muhammad Jalige ṣalaye pe ko si ohun to jọ bẹẹ.

''Lati ọjọ Ẹti ọjẹ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹta lawọn akoroyin ti n pe mi ni mẹsan mẹwaa lori iroyin ijinigbe ni Kaduna.

Ko si ẹni to mọ ohun kan nipa iṣẹlẹ ijinigbe awọn ọmọ ijọ RCCG kankan ni Kaduna.

Ohun to ya mi lẹnu ni pe ipinlẹ Eko nikan lawọn akọroyin ti n pe mi".

Alukoro ọlọpaa naa ni akọroyin to wa ni Kaduna ati apa ariwa orilẹede Naijiria ko pe oun, ki lode to fi jẹ pe lati ilu Eko nikan ni wọn ti n pe oun.

"Amọ, ti ileeṣẹ ọlọpaa ba gbọ ohun kan nipa iṣẹlẹ yii, n o jẹ ki ẹ gbọ,'' ASP Jalige lo ṣalaye bẹẹ.

Ijọ Redeem Christian Church of God jẹ ijọ nla to si ni ẹka kaakiri orilẹede Naijiria. Iya ijọ naa kalẹ si Ebute Mẹta ni ilu Eko.