JAMB news 2021: Ìdí tí NIN rẹ fi ṣe pàtàkì láti forúkọsílẹ̀ fún ìdánwò JAMB rèé

Oríṣun àwòrán, Prof. Ishaq Oloyede
Oludari ajọ to n ri si idanwo aṣewọle iwe giga JAMB, Ọjọgbọn Ishaq Oloyede ti ṣalaye pe idi ti ajọ naa fi paṣẹ pe ki awọn aṣedanwo maa lo nọmba idanimọ NIN fun iforukọsilẹ ni lati dẹkun magomago idanwo.
Ọgbẹni Oloyede sọ eyi lasiko ipade ori ayelujara kan to ṣe plu alakoso ibudo idanwo ori ẹrọ ayarabiaṣa (Computer Based Test) pe aṣẹ lilo nọmba NIN lọdun yii wa latọdọ minisita eto ẹkọ, Adamu Adamu ati pe idi mii ni lati bojuwo ọrọ abo lorilede Naijiria.
Eyi ko waye lasiko idanwo JAMB ti ọdun 2020.
"Nitori abo ni. Fun ipele tiwa yii, yoo ṣeranwọ lati lodi si biba eeyan kọ idanwo amọ idi ti wọn gbojule ju ni ipenija aabo lorilẹede Naijiria a si mọ pe ọpọlọpọ iṣoro taa ni lo ni ṣe pẹlu iṣoro idanimọ tori ao le da gbogbo araalu mọ..."
JAMB ti kede pe ọjọ kẹjọ oṣu kẹrin ni wọn da fun iforukọsilẹ idanwo tdun yii wn si ni yoo pari ni ọjọ kẹẹdogun oṣu karun ọdun 2021.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

Oríṣun àwòrán, Pulse
Awọn ti ko wa ni nọmba NIN tabi siimu kaadi n kọ?
Oloyede sọ nibi ipade ọhun pe awọn aṣedanwo gbudọ lo siimu to si n ṣiṣẹ ti wn o si tii lo ri ṣaaju akoko iforukọsilẹ wọn.
O fi kun un pe ajọ JAMB n ba minisita to n ri si ibanisọrọ ṣepade lati fun awọn ni aṣ idariji fun ida ogun aṣedanwo ti ko ba ni siimu.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
"Kii ṣe gbogbo aṣedanwo ni ko ni siimu, ida ọgọrin lo ti nọmba wọn, torinaa a n sọrọ ida ogun bayii taa ba si ri anfani ati gba aṣ idariji yii latọdọ minisita, ao rii daju pe awọn eeyan tẹle ofin tori ijọba ti ni gbogbo nkan yii ni o le ṣamojuto aabo fun gbogbo wa.
Elo ni owo iforukọsilẹ JAMB?
Ajọ JAMB loju opo Twitter wọn kede pe ẹgbrun mẹta abọ Naira (N3,500) ni owo idoruksilẹ ati ẹẹdẹgbẹta naira (N500) fun awọn iwe to yẹ ni kika fun idanwo naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3

!["ASUU Strike update today": [is ASUU strike still going on?] Asuu begins indefinite strike?](https://ichef.bbci.co.uk/ace/ws/660/cpsprodpb/20AA/production/_117726380_asuustrikeupdatetoday-isasuustrikestillgoingonasuubeginsindefinitestrike.jpg.webp)