Dibu Ojerinde: Ìdí ti ICPC fi fi panpẹ́ ọba mú ọ̀gá àgbà àjọ Jamb tẹ́lẹ̀ rí.

Prof. Dibu Ojerinde: Ìdí ti ICPC fi fi panpẹ́ ọba mú ọ̀gá àgbà àjọ Jamb tẹ́lẹ̀ rí.

Oríṣun àwòrán, Jamb

Àjọ tó n ri sí ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà ti fi panpẹ́ ọba mú alákoso àgbà fún àjọ tó n rí sí ìdáwò ìgbàníwọlé si fásitì (JAMB) tẹ́lẹ̀ rí ọjọ̀gbọ́n Dibu Ojerinde.

Wọ́n fi ẹ̀sùn kan pé ó ṣe owó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún mílíọ̀nù náírà mọ́kumọ̀ku lásìkò tó n ṣe adari àjọ JAMB.

Ọjọ́ ajé ni ikọ̀ ICPC mú Dibu Ojerinde ni ìlú Abuja pé ó kó owó Jamb àti Neco jẹ́.

Àkọlé fídíò, Farmers Herders Crisis: Rẹ́rẹ́ rún, ẹ̀mí àti dúkìá ṣòfò lágbègbè Ariwa Yewa

Wọn ti ti mọ́ àgọ́ ICPC fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún oníruurú ẹ̀sùn to fi mọ́ pípe ara ẹni ti ǹkan ti kò jẹ́, ṣíṣi agbára lò, kíko owo ilú pama lanà àìtọ́, àisan owó orí àti píparọ fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba.

Wọ́n tun fẹ̀sùn kán péó n gbé kọngila irọ́ fún ilẹ́ iṣẹ́ Shell ti kò si ọ̀nà láti wádìí.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde ti ICPC fi síta lọ́sàn òní láti ọwọ́ agbẹ̀nusọ rẹ̀, Azuka Ogugua, ó ni Ojerinde gbé kọngila láti pèsè lẹ́ẹ̀dì àti ìrésà ni irínwo àbọ̀ mílíọ̀nù naira fun ìkọ̀ọ̀kan fún ilé iṣẹ́ Double 07 Concept Limited àti Pristine Global Ltd láàrín 2013 àti 2014 lásìkò tó jẹ́ adarí Jamb.

Àjọ náà tún sọ pé, kò sí ẹ̀rí pé àwọn ilé iṣẹ́ náà pèsè àwọn ǹkan náà, bákan náà ni kò si ẹni tó ri agbaṣẹ́ṣe ọ̀hún

Bákan náà ni ó tún gbé iṣẹ́ fún Solid Figures Limited, Holywalk Limited àti àwọn ilé iṣẹ́ míìràn tí kò si sí ẹni to le tọ́ka sí ṣíṣe rẹ̀.

"Ọ̀jọ̀gbọ́n Ojerinde wà ni àgọ́ wa, à ko sì ni pẹ́ gbe lọ sí ilé ẹjọ́ tí a bá ti pari ìwádìí wa."

Tí ẹ ò bá gbàgbọ́ ìjọba àpapọ ti gba àwọn ǹkan iní rẹ̀ lẹ́yin adájọ́ Ijeoma Ojukwu dá ẹjọ́ pé ki wọ́n gba ǹkan ìní rẹ̀.

Ọjẹrinde ni adari àjọ Jamb lọ́dun 2007 si 2016 sùgbọ́n lẹ́yìn tó kúrò ni Ishaq Oloyede kó bílíọ̀nù márùn náírà fún ìjọba owó ti Oloyede ko kó fun ìjọba ni ọdún mẹ́sàn to fi ṣe àdarí àjọ náà.