INEC: Lẹyìn tí ọ̀jọ̀gbọ́n fásítì tó yí èsì ìbò Sẹnẹto Akpabio f‘ẹ̀wọ̀n jura, kí ló kàn fará yoku?

Oríṣun àwòrán, Google
Oju opo Twitter ti n gbana jẹ lori iroyin pe wọn ti dajọ ẹwọn fun ọjọgbọn to yiwe esi ibo ti Sẹnẹtọ Godswill Akpabio kopa ninu rẹ lọdun 2019.
Iroyin yi lu sita lỌjọbọ pe ọjọgbọn Peter Ogban ti fasiti Uyo yoo fi aṣọ penpe roko ọba nitori yiyi iwe esi idbo .
Labẹ ofin INEC ẹwọn ọdun mẹta lo wa fun ẹnikẹni to ba jẹ adari idibo to mọọmọ yi iwe tabi abajade ibo.
Ko si owo itanran kankan lori ẹsun yi bi kii ṣe pe ki onitoun ṣẹwọn.
Loju opo Twitter awọn eeyan ti n sọrọ lori idajọ yi ti wọn si n beere pe ki wa ni yoo ṣẹlẹ si ẹni to jẹ anfaani wuruwuru ibo yi botilẹ jẹ wi pe ko pada jawe olubori.
Die ree ninu ọrọ wọn yi.

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Lopin igba ti ko ti si ẹri to ṣafihan ilẹdiapopọ laarin Ọjọgbọn naa a ti Ṣẹnẹtọ Akpabio eyi to sunmọ ko ṣẹlẹ ni pe Ọjọgbọn yi yoo da jẹ iya rẹ ni.
Ka ni pe makaruru ibo yi gbe Akpabio wọlẹ ni a o ba tiẹ maa sọ pe ki wọn gbe ipo rẹ fun ẹni ti wọn jijọ dije dupo amọ ọrọ ko ri bẹẹ.
Ki ni ẹkọ to wa fun wa lori ẹjọ Ọjọgbọn yi nipa oṣelu
INEC ki ba maa ba Ọjọgbọn to yiwe idibo fun Akpabio ṣẹjọ ṣugbọn ọjọgbọn yi fun ara rẹ lo ni ki agbẹjọro rẹ kan si INEC pe ki wọn maa ṣe ni koun wa jabọ eto idibo to yi.
Oun nikan kan ni INEC pe ti awọn mii ninu wọn naa si kọ lati wa jabọ esi idibo.
Abalọ ababọ, INEC pinu lati gbe ọjọgbọn yi lọ si ileẹjọ ti adajọ si pada dajọ ẹwọn oṣu mẹrindinlogoji fun.
Ninu gbogbo ohun to ṣẹlẹ yi, o fi n han pe ireti wa fawọn to n beere idajọ to yẹ fun ẹnikẹni toba ṣe makaruru eto idibo.












