Yoruba artists: Ṣé Yomi Fabiyi ti rí ìfẹ́ míràn ni lẹ́yìn tó kọ ìyàwó rẹ̀ òyìnbó tẹ́lẹ̀ sílẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Instagram/realyomi Fabiyi
Oriṣiiriṣii nkan lo ṣẹlẹ lagbo awọn oṣere tiata Yoruba lọsẹ yii.
Lara awọn nkan to ṣẹlẹ lagbo oṣere yii, meji lami laaka ninu wọn.
Wọnyii ni awọn oriṣiiriṣii to ṣẹlẹ lagbo awọn osẹre tiata lọsẹ yii.
- Iya Awero fẹ́rẹ̀ẹ́ bú sẹ́kún níbí tó ti tẹ́wọ́ gba ẹ̀bùn ilé tuntun
- Wo àwọn ọ̀rọ̀ tó ki pọ́pọ́ tí Lateef Adedimeji fi kọrin ọjọ́ ìbí fún Adebimpe Oyebade "Onítèmi"
- 'Ǹkan tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọ̀nà tèmi yàtọ̀ lágbàáyé ni ǹkan tí mò ń lò'
- 'Pẹ̀lú gbogbo ìrìnàjò Dubai mi, ẹ̀sẹ̀ gígún ní Nàìjíríà láti pàdé èèyàn ńlá ńlá tó máa ra àwòrán ṣe pàtàkì'
- Ẹ̀rù bà mí pé òpin iṣẹ́ yìí ti dé lásìkò Covid-19 àmọ́ àwọn àga tó pawó wọlé fún mi rèé - Obìnrin oní fọ́nííṣọ̀
Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi
Ṣe ẹ mọ pe ọrọ ifẹ bi adanwo ni. Fidio kan ti gbajugbaja oṣere tiata, Yomi Fabiyi fi sita ti jẹ ki awọn eeyan maa beere ibeere.
Fidio naa ṣe afihan rẹ pẹlu orekelẹwa obinrin kan nibi ti awọn mejeeji ti n fẹnu ko ara wọn lẹnu.
Ọgbẹni Fabiyi gan an kọ awọn ọrọ ifẹ sori fidio naa loju opo Instagram rẹ.
Fabiyi ni ''ti mo ba nifẹ rẹ, mo gbọdọ fẹnu ko ẹ ni ẹrẹkẹ. Ọrọ ifẹ maa n sọ mi di alailagbara".
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Yomi tun sọrọ lori fido mii to fi soju opo Instagram rẹ pe oun ati ọrẹbinrin oun n lọ si gbọngan idaraya.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
O tun sọ lori fidio naa pe pe kawọn eeyan wo oluranlọwọ oun, eyun-un ni ọmọ pupa roboto kan to wa lẹgbẹ rẹ ninu mọto.
Ẹwẹ, ọpọ awọn akẹgbẹ re lo n ki ku oriire igbeyawo bo tilẹ jẹ pe ko sọ fun ẹnikan pe o ti ṣe igbeyawo.

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi
Fabiyi kede lori ayelujara lọdun 2016 pe oun ti kọ iyawo oun oyinbo ọmọ ilẹ Gẹẹsi, Fran silẹ.
Iya Awero

Oríṣun àwòrán, Gboyega Akosile
Gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, Lanre Hassan ti ọpọlọpọ mọ si Mama Awero di onile lairo tẹlẹ.
Bawo lo ti ṣẹlẹ? Gomina Babajide Sanwo-Olu ipinlẹ Eko lo fi ile oniyara mẹta ta Iya Awero lọrẹ.
Arabinrin Hassan fi idunu rẹ han si gomina ipinlẹ Eko pẹlu oriṣiiriṣii ọrọ iwuri.
"Mi o mọ ohun ti mo le sọ, o ṣi n ya mi lẹnu ṣugbọn inu mi dun lonii, mi o ni le sọ pupọ. Mo dupẹ pupọ lọwọ yin gomina mi".
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Bayii ni Iya Awero ṣe fi idunnu rẹ han si Gomina Sanwo-Olu.
Adebimpe Oyebade
Ilumọọka oṣerebinrin Adebimpe Oyebade ṣe ọjọ ibi, ori ayelujara mi titi.
O ni oun fẹ maa jẹ ẹni to n fi ipo adari to dara han siwaju sii bi oun ṣe n ṣe latẹyin wa.
Mo_bimpe fi ọrọ dupẹ fun bi awọn ololufẹ rẹ ṣe tu yaya lati ki i ku ọjọ ibi rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3
"Ori itage mi ni ile aye yii jẹ mo si ti fi gbogbo ipa mi ko ipa gidi latyin wa. Mo gbadura lati tẹsiwaju ninu ṣiṣe afihan ipo ẹni nla to n dari siwaju sii".
Bakan naa ni akẹgbẹ rẹ ti ọpọ maa n pe ni ọkọ rẹ, Lateef Adedimeji ṣe tẹ ẹ si rẹpẹtẹ.
Niṣe lo n ki i ni mẹsan an mẹwaa.
Femi Adebayo Salami
Gbajugbaja oṣere tiata, Femi Adebayo Salami ṣe iranti igba ti o lẹpọ pẹlu baba rẹ Adebayo Salami lagbo ogege ṣiṣe.
Asọ aran to ṣiṣẹ si lọrun ni Femi wọn ninu fọto ti oun ati baba rẹ wa ninu rẹ wọ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 4
Ọgbẹ Salami gan an fun ra rẹ ro dẹdẹ, bẹẹ lo kan dudu ninu aṣọ oke alanbara to wọ pẹlu ọpọ lọwọ.
Lai ṣe ani-ani, awọn mejeeji rẹwa lọkunrin ninu aṣọ ti wọn wọ.