Yoruba film celebrities: Wo àwọn ọ̀rọ̀ tó ki pọ́pọ́ tí Lateef Adedimeji fi kọrin ọjọ́ ìbí 23 fún Adebimpe

Oríṣun àwòrán, MO_bimpe
Gbajugbaja oṣerebinrin Adebimpe Oyebade ni oun fẹ maa jẹ ẹni to n fi ipo adari to dara han siwaju sii bi oun ṣe n ṣe latẹyin wa.
Mo_bimpe fi ọrọ dupẹ fun bi awọn ololufẹ rẹ ṣe tu yaya lati ki i ku ọjọ ibi rẹ.
"Ori itage mi ni ile aye yii jẹ mo si ti fi gbogbo ipa mi ko ipa gidi latyin wa. Mo gbadura lati tẹsiwaju ninu ṣiṣe afihan ipo ẹni nla to n dari siwaju sii".
Ohun to ṣẹlẹ lọjọ ibi rẹ ọhun kuro ni keremi gẹgẹ bi akẹgbẹ rẹ ti awọn eeyan tun n pe ni ọkọ rẹ, Lateef Adedimeji ṣe tẹ ẹ si rẹpẹtẹ.
Yoruba bọ wọn ni tẹni n tẹni ti akisa ni ti aatan.
Ohun to ba jẹ teeyan ko ṣee fi bo bẹẹ si ni ẹni to ba sun mọ eeyan bi eti ko ṣee foju fo rara ninu ile tabi lawujọ.
Eyi lo difa fun ara ọtọ eto ayẹyẹ ọjọ ibi pataki ti gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, Lateef Adedimeji fi yẹ ẹni tirẹ ati akẹgbẹ rẹ, Adebimpe Oyebade si gẹgẹ bo ṣe le dun kan sii.
- Seyi Makinde ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 nílùú Ibadan
- Ìdí rèé ti mo fi gbé àfẹ́sọ́nà ẹ̀gbọ́n mi níyàwó lẹ́yìn ikú rẹ̀
- Ẹnikẹ́ni tó bá fa wàhálà míì lẹ́yìn rògbòdìyàn ọ̀rọ̀ Hijab tó wáyé n'Ilorin yóò fojú winá òfin - AbdulRazaq
- Sùkẹ̀! Ọ̀rọ̀ òṣèlú ni gbogbo ẹ tí Akeredolu ṣe tako ìdásílẹ̀ Oduduwa Nation - Banji Akintoye
- Iya Awero fẹ́rẹ̀ẹ́ bú sẹ́kún níbí tó ti tẹ́wọ́ gba ẹ̀bùn ilé tuntun
Laarọ kutu kutu hai oni ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹta lo pe ọdun mẹtalelogun. ṣe ni wọn bẹrẹ ọjọ naa pẹlu adura ṣiṣe fun un lẹyin eyi ti akewi tun wọle to bẹrẹ si ni mu ori ọlọjọ ibi wu.
Gẹgẹ bi oun atawọn ara ile rẹ ṣe maa n pe e, gbogbo wọn pariwo Adebimpe ọmọ Ọba ti akewi si n ran an leti Idere Ekiti nibi to ti ṣẹwa.
O ti ṣe diẹ ti awọn ololufẹ awọn gbajugbaja oṣere meji yii ti n jẹ ọrọ wọn lẹnu pe boya wọn ti di lọkọ laya ni tabi wọn kan n gbe awọn mọra pẹlu oniruuru aworan ati fidio ti wọn jọ maa n ya papọ amọ ti awọn funra wọn ko jade sọ pe awọn ti so yigi.

Oríṣun àwòrán, MO_bimpe

Oríṣun àwòrán, MO_bimpe
Asiko ọjọ ibi yii si tun jẹ akoko kan ti awọn eeyan yoo fẹ ṣọ ihuwasi awọn mejeeji sirawọn.
Pabanbari gbogbo pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ọjọ ibi yii ni igba ti Lateef Adedmeji yọ laarọ ọjọ naa to si bẹrẹ si ni rọjo owo le Adebimpe lori eyi to tun mu ki akewi fi ede ti Lateef maa n saba fi ṣe yẹyẹ bi ẹni n gbadura lede Yoruba amọ to n sọrọ bii ọmọ ẹya Igbo lati fi ṣe adura fun Adebimpe.
ṣaaju ọjọ yii ni gbajugbaja oṣerebinrin yii ti ni oun gba aye lati maa fi oniruuru fọto ara rẹ sita lati mọ riri ore Ọlọrun nitori ọjọ ibi rẹ to n bọ lọna.
Kii ṣe gbogbo eyi nikan ni akẹgbẹ rẹ, Lateef fi yẹ ẹ si, ara ọtọ orin to diidi gbe iṣẹ rẹ fun olorin kan ti oun atirẹ si jẹ n fi orukọ Adebimpe Ọmọ Ọba kọrin fun adumaradan naa ti gbogbo eeyan fẹran awọ dudu rẹ.

Oríṣun àwòrán, MO_bimpe
- A ò pe Sunday Igboho lọ́mọ alè Yorùbá o àmọ́, a ó jọ́ bèrè lọ́wọ́ Alálẹ̀ Ibadan àti gbogbo Yorùbá ni - Olubadan
- 'Ohun táá ṣe rèé bẹ́ẹ bá kọ̀ láti wá gbé àwọn òkú yín kúrò ní Mọ́ṣúárì wa'
- Mo gbàdúrà kí n má kábàmọ́ fífagilé ẹjọ́ pẹ̀lú àwọn tó jí àwọn ìbejì mi gbé nílé ẹjọ́ - Akeugbagold
- Agbébọn yabo ílé ìtajà ìgbàlódé, èèyàn mẹ́wàá bá d'èrò ọ̀run
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Loju opo Lateef Adedimeji gan funrarẹ, orin ikini ku ọjọ ibi yii naa ni o fi ki i ku oriire ọjọ ibi pẹlu ọrọ to fi sita to fi n ṣapejuwe iru obinrin ti Adebimpe jẹ.
"Obinrin alagbara, ara ọtọ ẹda, agbara rẹ maa n da mi lọrun, gbogbo ọna lo ti yaayi.
Eeyan mi, Onitemi mi, onija mi, onironu mi, mo le tẹsiwaju lati maa sọ pupọ lai dakẹ.
O ku ọjọ ibi Ọmọ Ọba mi Ọwọn".
Lateef Adedimeji naa tun gba ọpọ adura fun ẹni to pe ni "Onitemi".
















