Akomolede Yoruba: Arọ́pò orúkọ Relative Pronoun àti àmúlò rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá kan wà tí ẹ kò lè lò pọ̀ mọ́ ara wọn, àwn ọ̀rọ̀ tẹ́ẹ lè fi rọ́pò rèé

Arabinrin Kemi Abiodun ti ileewe Celestial Grammar School nipinlẹ Ondo farabalẹ kọ ẹkọ toni nipa awọn ọrọ arọpo afara jorukọ.

Ọkan pataki ninu iṣọri girama Yoruba ni ọrọ̀ arọpọ orukọ. Lara awọn isọri to ku ti ẹ le ma fọkan si ni:

Ọrọ Orukọ - Noun

Ọrọ iṣe - Verb

Ọrọ apejuwe - Adjective

Apọnle - Preposition

Ọrọ Asopọ - Conjuction

Ẹwẹ, ninu gbogbo isọri gbolohun Yoruba, Arọpo ọrọ orukọ ni olukọ wa fọ si wẹwẹ ninu kilaasi Akomolede ati Aṣa Yoruba lonii.