UITH Mortuary: Ẹ wá gbé àwọn òkú yín o! A ò ráyè kó òkú sí mọ́

Awọn alaṣẹ ile iwosan Fasiti ilu Ilorin, Univeristiy of ilorin Teaching Hospital ti kede sita pe aaye igboku si ni mọṣuari awọn ti kun fọfọ ti ko gba ero oku ti wọn n gbe wa mọ.
Tori eyi ni wọn ṣe ni ki awọn eeyan to ba ni oku sibẹ wa gbe oku mọlẹbi wọn ati awọn ẹni ire wọn to papoda kuro ni mọṣuari ọhun.
Lati ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kejila ọdun 2020 si Ọjọbọ ọsẹ yii ni wọn ti kọkọ fun wọn gẹgẹ bii gbedeke ni awọn alaṣẹ ile iwosan naa ti n pariwo pe ki awọn eeyan wa gbe oku wọn.
- Wo àwọn ọ̀rọ̀ tó ki pọ́pọ́ tí Lateef Adedimeji fi kọrin ọjọ́ ìbí 23 fún Adebimpe Oyebade rèé
- Ìdí tí Ọba Aládé ò ṣe gbudọ̀ gbè lẹ́yìn ọ̀rọ̀ Oduduwa Republic rèé láì bi Alálẹ̀ ilẹ̀ - Olubadan
- Wo àwọn ìlú tó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti èèwọ̀ ni kí ènìyàn kú níbẹ̀
- Kílódé tí àwọn èèyàn ṣe ń gbé òkú pamọ̀ sílé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìlú yìí?
- Omi Àgbọn, Ọsàn wẹ́wẹ́, ìbẹ́pẹ àtàwọn ohun márùn ún mìí tóo gbọ́dọ̀ mu lásìkò ẹ̀run rèé
- Ọwọ́ tẹ afurasí ọ̀daràn Fulani tó ṣe ìkọlù sílé ìyá Sunday Ighoho
- Àwa ọmọ ìpínlẹ Ondo kò nífẹ́ sí Yoruba Nation, ọmọ Naijiria ni wá- Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nibayii, ọjọ naa ti fẹ ko tan eyi tii ṣe ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹta ọdun 2021 lẹyin eyi ti alaṣẹ ile iwosan naa ni bi awọn eeyan ba kọ, awn yoo ni lati gbe igbesẹ ṣiṣe eto isinku ọlọgọọrọ.
Ipe yii tun jẹ jade ninu atẹjade kan ti Arabinrin E.O Ajiboye to jẹ adari eto gbogbo nileewosan naa fi sita lati tun kede fun awọn araalu eyi ti wọn pe akọle rẹ ni "Ikede isinku ọlọ́gọ̀ọ̀rọ̀".












