Heat Season: Àwọn ohun méje tóo gbọ́dọ̀ mu lásìkò ẹ̀run rèé o

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igba ẹrun ati ọgbẹlẹ ti de kaakiri orilẹede Naijiria bayii ti ooru si mu pẹlu oju ọjọ to gbona paapaa ni awọn agbegbe ariwa orilẹede Naijiria ati agbegbe Niger Republic.
Eleyiii mu ki a bere lọwọ awọn onimọ nipa eto ilera lori ohun ti eniyan le jẹ ati mu lasiko ẹrun, ti gbogbo ibi si gbona.
Oju ọjọ gbigbona yii le e fa aisan bii ki o ma a rẹ eniyan lati inu, ki oungbẹ ma a gbẹ eniyan.
Nitori naa, ara nilo omi nigba gbogbo ati agbegbe to tutu, nitori pe ara eniyan ma n padanu omi to le ni mita meji ni ojoojumọ ti eniyan ba n laagun, ti oun mi eemi, to n ṣegbọnsẹ tabi tọ ni ojoojumọ.
Wo ohun meje ti eniyan gbọdọ mu lasiko ẹrun;
Omi mimu ṣe pataki ni gbogbo igba, eniyan si gbọdọ ma a mu o kere tan ike omi mẹjọ ni oojọ ati awọn ohun mimu miran.
Omi ọsan Lemon: O dara lati ma a mu omi ọsan lemon nitori o ni eroja ara Vitamin C ati B , ti eniyan si lee fi omi si tabi Sugar, bi o ba ṣe fẹ ẹ si.
Eso watermelon: Ida marundinlaadọrun eso watermelon lo jẹ omi, ti o si n pa oungbẹ ni kiakia, nitori naa eso to dara lati mu ni lasiko ọgbẹlẹ.
Omi agbọn: Omi agbọn naa ṣe pataki fun agọ ara ti o si pọndandan ki eniyan mu u ni asiko ẹrun nitori awọn eroja aṣeraloore to wa ninu ẹ.
Ibẹpẹ: O tun pọn dandan naa ki eniyan ma a jẹ ibẹpẹ lasiko ẹrun nitori o ma n jẹ ki ounjẹ ati omi tete da ni inu.
Tomatoes: O dara lati jẹ tomato nitori o ni ọpọlọpọ omi ninu, ti eniyan si le jẹ ẹ ni titu tabi ki wọn fikun ounjẹ.
Ẹfọ: Ida ọgọrin si aadọrun ẹfọ lo ni omi ninu, to si ma n jẹ ki o tete da ninu eniyan lati ṣe iṣẹ to yẹ ni agọ ara ti eniyan ba ti jẹ tan. Lara awọn ẹfọ naa ni mọringa, lettuce ati bẹẹ bẹẹ lọ.
















