Kwara Hijab Crisis: Àwà àti Mùsùlùmí ò lọ́rọ̀, àwa àti ìjọba la lọ́rọ̀ - Ìgbákejì alága CAN Kwara

Awọn akẹkọọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wahala to ti n waye lori aṣẹ ti ijọba ipinlẹ Kwara pa lori lilo ijaabu ni awọn ile ẹkọ nipinlẹ naa tun ba ọna mii yọ lọjọ Aje.

Irinajo BBC kaakiri awọn ileewe mẹwaa to jẹ ti ẹlẹsin Kristiẹni ni ipinlẹ naa fihan pe awọn kan lara ileewe naa ko jẹ ki awọ̀n akẹkọọ wọn wọle.

Ni ileewe girama C&S College, Sabo-Oke nilu Ilorin, titi pa ni geeti abawọle wa, ti awọn akẹkọọ ko si raaye wọle.

Ọkan lara awọn to ni ileewe naa, Senior Apostle Popoola, to tun jẹ igbakeji CAN ni Ilorin South sọ fun BBC Yoruba pe o di igba ti ijọba Kwara ba to o gba nkan ti awọn n sọ lori ọrọ lilo ijaabu, ki awọn to sinmi ariwo.

Apostle Popoola sọ pe ijọba Kwara kan fẹ ẹ fi igbesẹ rẹ lori ọrọ ijaabu lilo da ija ẹsin silẹ laarin awọn Musulumi ati Kristiẹni.

"A n tẹnumọ pe ijọba la n baja, kii ṣe awọn Musulumi."

O ni ọpọlọpọ igba ni awọn olori ẹsin Kristiẹni ti ba ijọba ṣe ipade pe ko da awọn ileewe naa pada fun Kristiẹni.

Niṣe ni awọn akẹkọọ ileewe C&S ọhun duro si ita ileewe, ti awọn to lo ijaabu si pọ babi laarin wọn.

Lara ohun ti BBC tun ṣakiyesi nipe gbagbaagba ni awọn ọlọpaa duro ni ayika ileewe naa.

Awọn ileewe kan wa ni ṣiṣi, eto ẹkọ si n lọ lọwọ

Ni ileewe miran to Baptist Secondary School ni agbegbe Surulere nilu, niṣe ni awọn ọmọ ologun si duro wamuwamu si ẹnu ọna ileewe girama naa.

Awọn akẹkọọ ati olukọ si wa ninu kilaasi wọn fun idanilẹkọ.

Amọ, ọkan lara awọn igbakeji ọga agba ileewe naa, Imaamu Abdulrasak,to ba BBC sọrọ sọ pe awọn wọle ni ọjọ Ẹti lẹyin aṣẹ ijọba. O ni ṣugbọn, iyalẹnu lo jẹ lati ri i pe ilẹkun ileewe naa wa ni titi pa ni owurọ ọjọ Aje, lati ọwọ awọn alaṣẹ ijọ Baptist.

Ọsẹ to kọja ni ijọba paṣẹ pe ki awọn ileewe naa di ṣiṣi pada, lẹyin to ti ti wọn fun ọjọ diẹ nitori ọrọ wahala ijaabu.

Awọn olukọni awọn ileewe naa pada lootọ, ṣugbọn ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi ṣi yari pe ko si nkan to jọ ọ.