Sunday Igboho: Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye sọ pé kíì ṣe èrò àwọn ènìyàn Ondo ni Akeredolu sọ lórí Oduduwa Nation

Banji Akintoye ati Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Others

Ọkan pataki lara awọn aṣiwaju ẹya Yoruba, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti sọ pe ọrọ oṣelu ni bi gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ṣe tako idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa.

Ọjọ Aje ni Gomina Akeredolu kede pe ti orilẹ-ede Naijiria ni awọn eniyan ipinlẹ Ondo

Bakan naa lo kilọ fun Sunday Igboho ati awọn eeyan mii to ṣagbatẹru idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa, lati jina si ipinlẹ oun.

Lori ọrọ yii, Ọjọgbọn Akintoye sọ fun BBC pe ọrọ ti Akeredolu sọ, o sọ ọ gẹgẹ bi oloṣelu ni, nitori pe kii ṣe nkan ti awọn ọdọ ti ko raaye lọ si oko mọ, nitori ikọlu awọn Fulani n sọ.

"Ọrọ ẹnu awọn eniyan ipinlẹ Ondo kọ lo sọ."

Lori ipa ti aikopa ipinlẹ Ondo le ni lori ijijagbara fun orilẹ-ede Oduduwa, o ni ifasẹyin ko le ma si.

"Akeredolu jẹ ọkan lara awọn gomina ilẹ Yoruba ti a fẹran pupọ.

O ni awọn ko ti i sẹ ipade pẹlu awọn gomina lori ijijagbara fun orilẹ-ede Oduduwa, nitori pe ko ti de ipele naa, ṣugbọn yoo debẹ laipẹ.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá kan wà tí ẹ kò lè lò pọ̀ mọ́ ara wọn, àwn ọ̀rọ̀ tẹ́ẹ lè fi rọ́pò rèé

O ṣalaye pe o ni nkan to jẹ ki Akeredolu sọ nkan to sọ, o tun le sọ nkan to yatọ to ba ya.

"Idi ni pe laipẹ yii lo i dandan orin Oduduwa ni ki wọn o ma a kọ nipinlẹ Ondo, oun kan naa lo ṣagbatẹru idasilẹ ajọ alaabo Amọtẹkun.

Ao ni binu si, a gba pe oṣelu lo jẹ ko sọ nkan to sọ lori idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa."

Àwa ọmọ ìpínlẹ Ondo kò nífẹ́ sí Yoruba Nation, ọmọ Naijiria ni wá- Akeredolu

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti kilọ fun Sunday Igboho atawọn eeyan miran to n lọgun pe ki Naijiria pin lati ṣora fun ipinlẹ oun.

Akeredolu sọ pe awọn eeyan ipinlẹ Ondo ti yan lati duro gẹgẹ bii ọmọ orilẹ-ede orilẹ-ede Naijiria, nitori naa ki awọn kọlọrọsi kan ma da iyapa silẹ laarin awọn eeyan oun.

O ni oun ko ni fi aye gba ki ẹnikẹni ni ipinlẹ Ondo lati korajọ lori ijangbara to jọ mọ "Yoruba Nation" ti awọn eeyan kan n lọgun rẹ.

Aketi lọ sọ ọrọ naa nibi to ti n burawọle fun arabinrin Oladuni Odu gẹgẹ bii akọwe ijọba ipinlẹ naa tuntun atawọn olubadamọran pataki miran to ṣẹṣẹ yan sipo niluu Akure.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "awọn eeyan ilu lẹtọọ labẹ ofin lati ja fun ẹtọ wọn, ṣugbọn gbogbo nkan ni eto wa fun."

"Kii ṣe pe ẹnikan yoo dede gbe ara rẹ dide, ti yoo si maa sọrọ lorukọ gbogbo ẹya Yoruba lai si ẹnikẹni to yan an si irufẹ ipo bẹẹ."

O fi kun pe ko ko bojumu ki awọn kan maa ja fun ominira nitori ohun ti wọn yoo ri nidii ijagbara naa tabi fun anfani ara wọn.

Lẹyin naa lo bu ẹnu ẹtẹ lu bi awọn agbebọn kan ṣe kọlu Gomina ipinlẹ Benue, Samuelm Ortom lọjọ Abamẹta.

O si tun ke si awọn ẹṣọ alabo lati fi oju gbogbo awọn to n da Naijiria laamu lede.

Àkọlé fídíò, Omi iké kan, l'èèyàn kan lè mu f'ọ́jọ́ mẹ́ta láì ro ti ekòló inú rẹ̀ - Ìlú Elega, Kwara