UITH Mortuary Announcement: Ìyàtọ̀ tó wà láàrín òkú Mọ́ṣúárì aládàáni àti ti ìjọba rèé - Òṣìṣẹ́ Mọ́ṣúárì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oludari ni Ile iṣẹ igbokupamọsi aladani kan ni ipinlẹ Eko ti ni iwa ki awọn eeyan maa pa oku ti si Mọṣuari ko wọpọ ni ọdọ awọn bii ti ijọba.
Eyi waye lẹyin ti ile igbokupamọsi ti Fasiti ilu Ilorin fi ikede kan sita pe awọn ko ri aye gbe oku tuntun si mọ torinaa ki awọn to ti gbe oku sibẹ fun ọjọ pipẹ wa gbe oku wọn kuro.
BBC Yoruba kan si ọkan lara awọn ọga ileeṣẹ igbokupamọsi ti aladani kan ni ilu Eko, Ọgbẹni Deinde Harrison to n ṣiṣẹ pẹlu Ebony Funerals ni awọn o ki n kọ oku kankan niwọn igba ti owo ba ti n wọle.
"Bo tilẹ jẹ pe nigba miran ti aaye ba kun, a o sọ fun ẹbi naa pe ko saye mọ ṣugbọn awọn eeyan kii wa pa oku ti si ọdọ tiwa bii ti Mọṣuari ijọba".
O ni awọn eeyan gbudọ kọkọ san asan silẹ owo na, to ba si wa di pe owo naa ti fẹ tan, wọn a pe wọn lati wa fi kun owo wọn.
"Lootọ gbogbo Mọṣuari lo ni iye aye ti wn n lo fi gbe oku si bi aye naa ba si ti kun, ko si ṣiṣe afi ki wọn kọ oku ti wọn ba gbe wa".
"Kódà wọ́n lè fí òkú sílẹ̀, kí owó ṣáa ti máa wọle bi wọn ba ti n san owo itọju, awọn lo maa sọ asiko ti wọn fẹ wa gbe oku wọn.
Kí ló wá ń jẹ́ kí òkú wọ́pọ̀ ní Mọ́ṣúárì ìjọba?
Ọgbẹni Deinde ṣalaye pe ni ọpọ igba awọn to ba gbe oku lọ si Mọṣuari ijọba maa n foju wo o pe ṣebi ti ijọba ni.
"Awọn oku mii ti wọn kan ri he ni titi tabi ti ẹjọ wa lori ẹ le wa nibẹ fun odidi oṣu mẹfa, idi ti ẹlomiran fi n ṣe bẹẹ le jẹ ọrọ owo to bẹẹ to jẹ pe awọn gan o tii ri owo jẹun, wọn a kan pa oku naa ti sibẹ ni".
Eyi ati ọpọlọpọ idi ni Ọgbẹni Deinde ni o wọpọ ni awọn ile igbokupamọsi ti ijọba to bẹẹ to jẹ wipe awọn eeyan mii o tilẹ ni yọju mọ tori awọn to gbe wọn wa o ki n ṣe mọlẹbi wọn.
Idi ti awọn Mọṣuari fi nilo owo dandan fun itọju oku
Deinde ṣalaye wipe wọn gbudọ fi kẹmika rọ ọ lara daadaa bi wọn ba ti gbe e wa yala ni ti ijọba ni o tabi ti aladani.
"Bi wọn ba "embalm" oku lai sanwo, o kan maa wa nibẹ lasan ni fun ọjọ pipẹ, awọn to ni Mọṣuari ni yoo pofo tori ojoojumọ ni wọn nilo ina lati ma jẹ ki oku bajẹ".
Bakan naa o ni awọn to n ṣiṣẹ ni Mọṣuari yoo ṣaa gba owo, bo tilẹ jẹ ti ijọba, o ni owo naa ni wọn fi ṣe atunṣe ibẹ.
"Oku o gbudọ 'decompose' ko gbudọ bajẹ to ba tile bajẹ, awọn oloku naa lo maa fẹ gbe wọn lọ ile ẹjọ tabi fa wahala".
Ọgbẹni Deinde ni kii ṣe pe o wu awọn Moṣuari naa lati ni ẹbi lara o ṣugbọn owo ni wọn fi n ṣe gbogbo iṣẹ nibẹ.
Koda o ni ninu oku marun ti wọn ba gbe wa nibẹ, ọfẹ lawọn n gba ẹyọkan nibẹ.
Ẹwẹ, iye owo ti Deinde ni ọpọ ile igbokupamọsi aladani n gba fun ọjọ kan jẹ ẹgbẹrun kan eyi to si jẹ pe ti ijọba kere jọjọ si tiwọn.













