Ibarapa: Àwọn ọ̀dọ́ ṣe ìwọ́de lọọọ́físì Seyi Makinde lẹ́yìn tí ọlọ́pàá ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OPC tó mú Wakili mọ́lé

Ibadan

Awọn ọdọ kan ti ya bo ọọfisi ijọba ipinlẹ Oyo to wa ni Agodi, niluu Ibadan, lati fi aidunu wọn lede nitori ipaniyan to n waye nipinlẹ ọhun, paapaa lagbegbe Ibarapa, Oke-Ogun atawọn agbegbe miran.

Bẹẹ ni awọn ọdọ ọhun tun n ṣefẹhonuhan lodi si bi ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ṣe ti awọn ọmọ ẹgbẹ OPC mẹta kan mọle lẹyin ti ile ẹjọ kan paṣẹ pe ki wọn ṣe bẹẹ.

Awọn ọmọ ẹgbẹ OPC naa wa lara awọn ikọ to fi panpẹ ọba mu Iskilu Wakili, ti wọn fẹsun kan pe o n ṣagbatẹru ijinigbe ati ipaniyan niluu Ibarapa.

Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti kọkọ ti awọn ọmọ ẹgbẹ OPC naa mọle, ti wọn si fi ẹsun ipaniyan ati didana sun dukia lọna aitọ kan wọn, ki wọn to ni ki wọn logba diẹ ninu ọgba ẹwọn ki iwadii le tẹsiwaju.

Ibadan

Awọn olufẹhonuhan ọhun, ti ọpọ ninu wọn wa lati Ibarapa ya bo ọọfii ijọba ọhun, ti wọn si n kọrin pe ko si abo kankan fun awọn eeyan awọn pẹlu oriṣiriṣi akọle lọwọ.

Ọkan lara awọn to ṣagbatẹru iwọde na, Oladiran Oladokun sọ fun awọn akọrọrin pe bi awọn ọlọpaa ṣe ti awọn ọmọ ẹgbẹ OPC naa mọle n ṣafihan pe awọn ọlọpaa ko nilo iranlọwọ awọn eeyan ilu lati mu awọn ọdaran lawujọ.

Àkọlé fídíò, Omi iké kan, l'èèyàn kan lè mu f'ọ́jọ́ mẹ́ta láì ro ti ekòló inú rẹ̀ - Ìlú Elega, Kwara

Oladokun ṣalaye pe Wakili da awọn eyan Ibarapa laamu pupọ, bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa kọ lati mu, awọn ọlọpaa ọhun tun n fiya jẹ awọn ọmọ ẹgbẹ OPC to mu afurasi naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "a wa nibi lati ṣe ifẹhonuhan lodi si bi awọn awọn agbofinro ṣe mu awọn ọmọ ẹgbẹ OPC mẹta to mu Wakili to n da agbegbe Kajola, Ayete atawọn agbegbe miran laamu,ti wọn si tun ti wọn mọle."

"Won Ṣawari Wakili, wọn si fi panpẹ ofin mu, ṣugbọn awọn ọlọpaa ti wọn mọle, eyii jẹ ohun to buru jai, to tun n ṣafihan fun awọn eeyan ilu pe ko yẹ ki wọn maa ran ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ lati mu awọn ọdaran."

Àkọlé fídíò, Bed Wetting: Tolulope Joseph ní ò lé ní ogún ọdún tí òun fi tọ̀ sílé kí ìwòsàn tó dé