Vagina facts: Ǹkan pàtàkì márùn-ún tí gbogbo obìnrin tó ní ojú ara gbọ́dọ̀ mọ̀

Oríṣun àwòrán, Emma Russell
Oriṣiriṣi ẹ̀kọ́ ati ilana lo wa lori ayelujara nipa oju ara obinrin. Idi di niyii ti onimọ kan nipa ilera obinrin, Dokita Jen Gunter ṣe sọ fun BBC, iru amojuto to yẹ fun oju ara obinrin.
1 - O ṣe pataki ki o mọ iyatọ laarin oju ara 'vagina' ati ita rẹ 'vulva'
Oju ara ni eyi to wa ni inu ara ninu lọhun - iho to so ile ọmọ pọ mọ ita gbangba. Nkan ti o le ri nita ti o ba bọ awọtẹlẹ rẹ ni wọn n pe ni vulva.
- 'Ẹ wá gbé àwọn òkú yín o! A ò ráyè kó òkú sí mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́...'
- Ẹ̀yìn taa ni Alake ti Egba tò sí yàtọ̀ s'áwọn ọba míì lórí ọ̀rọ̀ Oduduwa Nation tí Sunday Igboho sọ?
- Kò sí Oduduwa Nation kankan ni ilẹ̀ Iwo! Kí n má gbọ́ ọ - Oluwo
- Omi Àgbọn, Ọsàn wẹ́wẹ́, ìbẹ́pẹ àtàwọn ohun mẹ́rin mìí tóo gbọ́dọ̀ mu lásìkò ẹ̀run rèé
2 - Oju ara ma n fọ ara rẹ
Ọpọlọpọ obinrin lo gbagbọ pe awọn nilo lati fi oriṣiriṣi nkan fọ tabi fi pa oju ara wọn ki o le maa rùn daadaa.
Ṣugbọn awọn onimọ iṣegun oyinbo ma n sọ pe funra oju ara obinrin lo n ṣe iwẹnumọ ara rẹ.
Onimọ kan, Jen Gunter tọka si wipe lilo ipara oloorun, jijoko sori omi to lọwọrọ, tabi awọn ilana igbalode mii ti awọn obinrin n lo ni asiko yii lewu pupọ.
O ṣalaye pe omi nikan, lai lo ọṣẹ ti to lati fi fọ oju ara lasiko to ba ṣe koko.
Ọṣẹ ma n fọ awọn asiidi to yẹ kuro ni oju ara ni. Awọn asiidi yii lo duro gẹgẹ bi aabo fun awọ oju ara yii.
Iwadii fihan pe ni gbogbo wakati mẹrindinlọgọrun ni awọn ẹya ara aifojuri 'cell' to wa ni oju ara obinrin ma n paarọ ara wọn.
3- Oju ara rẹ da bi ọgba ajara

Oríṣun àwòrán, Emma Russell
Oriṣiriṣi awọn kokoro aifojuri to dara lo wa ni oju ara obinrin. Iṣẹ ti wọn si n ṣe ni lati fun un ni ilera to peye.
Awọn kokoro aifojuri dara-dara yii ma n pese awọn eroja to n doju ija kọ kokoro aifojuri ti ko dara, to le fa aarun. Bakan naa ni eroja to da bi ikun 'mucus', ti kii jẹ ki oju ara ko gbẹ.
Idi si niyii ti ko fi dara lati maa fi eroja apakokoro nu oju ara. Ti o ba ro pe oju ara rẹ tutu boya nitori oru, o le gbiyanju lati fẹ atẹgun si i.

Oríṣun àwòrán, Emma Russell
4 - O ni idi ti irun fi wa nibẹ
Gunter ṣakiyesi pe ọpọ obinrin ti gba aṣa fifa gbogbo irun abẹ wọn. Lootọ ni ṣiṣe bẹẹ n le kokoro 'ina' jina, ṣugbọn o tun n pa oju ara diẹdiẹ.
To ba pọn dandan fun ọ lati fa irun abẹ rẹ, lo bileedi to mọ, ki o si fa a lati isalẹ nitori ki kokoro ma ba so mọ iyoku irun to wa nibẹ.
Fun awọn to n lo ilana igbalode 'wax', ẹ rii daju pe irinṣẹ ti wọn lo fun yin mọ daadaa.
Gunter sọ pe o ni idi ti awọn irun naa fi wa nibẹ. "O le jẹ pe o ni ojuṣe lasiko ibalopọ, o si le jẹ aabo fun awọ ara".
5 - Ọjọ ori le ṣakoba fun oju ara
Lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti obinrin ti n ṣe nkan oṣu, to tun ti bimọ, ile ọmọ obinrin ko ni ye ẹyin mọ, bẹẹ ni nkan oṣu yoo dawọ duro.
Bi awọn eroja to n ṣe iranlọwọ fun ọmọ bibi ṣe n dinku, yoo ma a ni ipa lara oju ara ati ayika rẹ.
Niṣe ni oju ara naa yoo ma a gbẹ, o si le fa irora lasiko ibalopọ nitori ko si nkan to mu ko 'tutu'.
Amọ, pẹlu iranlọwọ awọn eroja to n mu ki oju ara tutu fun ibalopọ 'lubricant', obinrin to ti dawọ nkan oṣu duro le gbadun ibalopọ.
O le awọn eroja naa ra ni ile itaja ogun.














