Sunday Igboho: Olubadan fèsì lórí ọ̀rọ̀ Oduduwa Republic

Oríṣun àwòrán, Oyo Affairs
Olubadan ti ilu Ibadan, Ọba Oba Saliu Adetunji Aje Ogungunnisọ Kinni ti da si ọrọ pipe fun ki iran Yoruba da duro gẹgẹ bi orilẹede tirẹ pe ko yapa kuro lara orilẹede Naijiria.
Ọrọ yii lawọn eeyan ti n gba bi ẹni n gba igba ọti lẹnu ọjọ mẹta yii leyi ti ajafẹtọ iran Yoruba naa, Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho naa da si pe afi dandan ki wọn ni Yoruba Nation.
Nigba ti BBC Yoruba kan si Aafin Olubadan ti ilu Ibadan, amugbalẹgbẹ ati agbẹnusọ Kabiyesi, Adeola Oloko ni ohun ti Kabiyesi fẹ ki gbogbo eeyan mọ ni wipe lootọ iru ipinu yẹn bii ti nini Yoruba Nation nilo iwadii daadaa, kii ṣe ohun a n ku giri ṣe.
- Wo àwọn ọ̀rọ̀ tó ki pọ́pọ́ tí Lateef Adedimeji fi kọrin ọjọ́ ìbí 23 fún Adebimpe Oyebade rèé
- Àwa ọmọ ìpínlẹ Ondo kò nífẹ́ sí Yoruba Nation, ọmọ Naijiria ni wá- Akeredolu
- Bàbá ni Alake Ẹgba jẹ́ fún mi, mi ò lè ṣe ìkọlù sí ààfin rẹ̀ - Igboho
- 'Ẹ wá gbé àwọn òkú yín o! A ò ráyè kó òkú sí mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́... - Aláṣẹ Mọ́ṣúárì Ilorin
- Ẹ̀yìn taa ni Alake ti Egba tò sí lórí ọ̀rọ̀ Oduduwa Nation tí Sunday Igboho sọ?
- Kò sí Oduduwa Nation kankan ni ilẹ̀ Iwo! Kí n má gbọ́ ọ - Oluwo
- Sùkẹ̀! Ọ̀rọ̀ òṣèlú ni gbogbo ẹ tí Akeredolu ṣe tako ìdásílẹ̀ Oduduwa Nation - Banji Akintoye
Oloko ni bibeere daadaa lọwọ awọn ti ọrọ kan ṣe pataki.
Gẹgẹ bi Alake ti Egba ṣe sọ ninu ọrọ tirẹ to fi sita, agbẹnusọ Olubadan naa ni ohun ti Kabiyesi Olubadan yoo sọ fun awọn eeyan ni wipe ọrọ yii kii ṣe eyi ti eeyan kan yoo dede pinu ni Ibadan, Oyo, Ogbomoso tabi Ife, amọ eeyan gbudọ wadii daadaa ko to sọ gbe iru igbesẹ bẹẹ.
Ṣe awọn Ọba Alade o wa fẹ ti Sunday Igboho lẹyin ni?

Oríṣun àwòrán, @TheNationNews
"Rara o, ẹ ma ṣi wa gbọ o. Awa o sọ pe ọmọ buruku ni Sunday Igboho tabi pe kii ṣe ọmọ Yoruba. Koda o maa n wa si Aafin Olubadan daadaa ṣugbọn o ni ẹtọ tirẹ lati sọ ero rẹ nipa nkankan".
Ohun to ni o jẹ ibeere gaan ni wipe njẹ gbogbo Ọba ti jọ jokoo pọ lati fẹnu ko pe gbogbo ohun taa fẹ sọ nipa rẹ ree.
- Mo gbàdúrà kí n má kábàmọ́ fífagilé ẹjọ́ pẹ̀lú àwọn tó jí àwọn ìbejì mi gbé nílé ẹjọ́ - Akeugbagold
- 'Ẹ wá gbé àwọn òkú yín o! A ò ráyè kó òkú sí mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́... - Aláṣẹ Mọ́ṣúárì Ilorin
- Ṣọ́ra fún ètò àwọn Darandaran, àwọn ọmọ Ekiti nílẹ̀ òkèèrè kìlọ̀ fún Fayemi
- 'Ìjọba Kwara kàn fẹ́ fi ọ̀rọ̀ Hijab dá ìjà sílẹ̀ láàrin Krìstíẹ́ní àti Mùsùlùmí ni'
"Taa ba wa jọ jokoo pọ taa fẹnu ko tan, ẹnikẹni o le gbẹyin ba ẹbọ jẹ".
Olubadan sọ pe ilẹ Yoruba ko le dede yapa kuro ninu Naijiria beere lọwọ alalẹ ilẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, "ti wọn ba fẹ fi ọba jẹ, wọn maa n beere lọwọ alalẹ ilẹ ki wọn to de ẹnikẹni lade ki ilu le tu awọn eeyan lara."
"Nilẹ Yoruba, eeyan kii dede ṣe nnkan to ba wu lori ilẹ lai beere lọwọ alalẹ ilẹ, alalẹ ni awọn to sẹ ilu naa ro."
Agbẹnusọ Olubadan wa beere pe ṣe awọn to n pe fun iyapa ilẹ Yoruba ti beere lọwọ alalẹ ilẹ ki wọn geb igbeṣẹ ọhun.
O pari ọrọ rẹ pe, "ṣe wọn ti beere lọwọ awọn alalẹ?
"Nitori eeyan ko le dede ku giiri da nnkan ṣe lai bi awọn alalẹ leere."
- Omi Àgbọn, Ọsàn wẹ́wẹ́, ìbẹ́pẹ àtàwọn ohun mẹ́rin mìí tóo gbọ́dọ̀ mu lásìkò ẹ̀run rèé
- Àwọn ajínigbé tún ti pé wá lóni ṣùgbọ́n a kò ti rí ìyè owó tí wọn ní ká mu wá-Olori Oba Imope
- O kéré sí Number! 'Àwa ológún ò fi ara wa wọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ láti máa ṣe alamí lórí irú ẹ Sunday Igboho'
- Jimoh Odutola, akọni oníṣòwò tí kò kàwé, àmọ́ táwọn Ààrẹ orílẹ̀-èdè ń ké sí láti wá dá iléesẹ́
- Afurasí olóṣèlú tí ọlọ́pàá mú lórí ikú ọmọ mi, ló jẹ́ alátakò rẹ̀ nínú PDP - Baba Aborode
- Ọwọ́ Sunday Igboho tẹ ‘Sọ́jà’ àti aráàlú mẹ́rin tó ní wọn ń dọdẹ òun















