Nollywood: Ta ló ní kí Adebimpe Oyebade Omooba bóra nígbà tí ó darapọ̀ mọ́ Nollywood?

Adebimpe Omooba

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mo_bimpe

Gbajugbaja oṣere, Adebimpe Ọmọọba ti sọ iriri rẹ nipa ara bibo to wọpọ ni agbo awọn oṣere.

Adebimpe ni ọpọlọpọ gbajugbaja ni wọn sọ fun ohun pe ki oun lọ bora nitori ẹni dudu ni oun.

Adebimpe Omooba

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mo _bimpe

Amọ o ni idahun oun ni pe oun ko le e bora nitori oun fẹran awọ oun.

''Ọpọlọpọ eniyan lo ni ki n bora nigba ti mo darapọ mọ Nollywood amọ mo ko''

''Ibere mi ni wi pe kilo de ti eniyan dudu ko le e ṣe ere to ba wu u nitori awọ?''

''Ọpọlọpọ eniyan ni ko fẹran mi nitori mo jẹ eniyan dudu, amọ lati igba ti mo ti bẹrẹ si ni ṣiṣẹ arinrinoge ni ẹwa mi bii eniyan dudu ti n pa owo fun mi''

''Nitori naa mo kọ, eleyii si ti jẹ ki n dayatọ laarin awọn oṣere tiata.''

Adebimpe Omooba sọ awọn ọrọ yii lasiko ifẹrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin Nigerian Tribune.

Adebimpe Omooba

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mo_bimpe

Lori iroyin wi pe oun ati akẹgbẹ Lateef Adedimeji n ṣe bi tọkọ-taya, Adebimpe ni ki awọn eniyan fi ara balẹ nitori laipẹ laijina awọn eniyan yoo mọ bi o ṣe n lọ laarin awọn mejeeji.

Amọ ko sọ ni pato boya nkankan wa laarin awọn mejeeji tabi ko si.

Omọọba ni fiimu akọkọ to gbe ohun jade ni Agbede Meji lasiko ti n ṣe agunbanirọ, ti oun ko tilẹ fẹran iṣẹ oṣere.

Adebimpe Omooba

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mo _bimpe

O fikun wi pe ko si ohun ti ẹni pupa leṣe , ti ẹni dudu ko le e ṣe pẹlu.

Ọdun 2020 ni o gba ami ẹyẹ AMVCA to si sọ wi pe inu ohun dun wi pe awọn eniyan ri iṣẹ takuntakun ti oun n ṣe.

Ipinlẹ Ekiti ni Adebimpe ti ṣẹ wa, ti wọn si bii si idile ọba.