Lekki Toll Gate, End Sars Protest: Mr Macaroni ti sọ̀rọ̀sókè fún ìjọba Nàìjíríà lẹ́yìn tó ti àtìmọ́lé dé

Oríṣun àwòrán, others
Awon mọlẹbi mi ki mi nilọ, emi ni ko gbọ́- Mr Macaroni.
Debo Adedayo to jẹ adẹrin poṣonu ti ọpọ mọ si Mr Macaroni lo ti sọrọ soke lẹyin ti ori koo yọ latimọle awọn ọlọpaa lẹyin iwọde ni Lekki Tollgate ni ana.
Mr Macaroni ni ọpẹlọpẹ awọn ọmọ Naijiria to pariwo sita boya wọn ko ba ti gbagbe oun.
O tun fi soju opo twitter ayelujara pe ijọba Naijiria lo kuna lati pese aabo to yẹ fun ara ilu, koda o ni ko si ẹya Hausa tabi Igbo tabi iran kankan to ṣe oun bikoṣe ijọba Naijiria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Debo Adedayo gba pe ọkan naa ni iran Igbo, Yoruba ati Hausa ti wọn jọ jẹ ọrẹ ara wọn
- Ṣé lóòtọ́ ni iléẹjọ́ pàṣẹ àyẹ̀wò DNA fún ọmọ Ronke Odusanya Ìdídowó, nítorí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ti ń fọnmú
- Wo àwọn ọ̀rọ̀, ewì, àwòrán tí kìí ṣe 'lórí irọ́' tí o lè fi yẹ́ olólùfẹ́ rẹ sí fún Valentine
- Mọ̀ síi nípa àwọn ohun tó lè mú kí èèyàn tètè ní irun funfun lórí láì tíì di arúgbó
- Wo ǹkan márùn ún tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò fẹ́ ní 'Valentine' 2021
- Abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ń yí àwọn èèyàn sí oníbálòpọ̀ akọsákọ àti abosábo - Alfa Abbas

Oríṣun àwòrán, Debo Mac/ BBC
N100, 000 ni Mr Macaroni àtàwọn tó kù tí wọ́n mú ní Lekki Tollgate san
Wọ́n ti gba béélì Mr Macaroni àti àwọn olùwọ́de kan tí ọlọ́pàá mú ní Lekki Toll Gate
Wọn ti yọnda diẹ lara awọn oluwọde ti wọn mu ni Lekki Toll gate lọjọ Satide.

Oríṣun àwòrán, @omoyelesowore
Ẹgbẹrun lọna ọgọrun un naira ni ile iṣẹ iroyin abẹle TVC ni wọn san ni owo beeli ẹnikọọkan.
Ogoji eniyan ni awọn ọlọpaa ko nibi iwode Lekki tollgate naa.
- Ìtàn ayé Abiola Peller, ọlọ́wọ́ idán tó fi ọ̀bẹ gé ìyàwó rẹ̀ sí méjì
- Ìyàwó àtàwọn ọmọ mi ń bẹ̀rù fún mi àmọ́ kò sí ẹ̀dá alàyè kankan tó leè pa mí - Sunday Igboho
- Iléẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún méje ká lórí ẹ̀sùn àìjọgbé papọ̀
- Mi ò mọ̀ pé oyún ọmọ mẹ́fà ló wà nínú mi, lẹ́yìn tí a ti w'ọ́mọ fún ọdún méje- Joyce
- N100, 000 ni Mr Macaroni àtàwọn tó kù tí wọ́n mú ní Lekki Tollgate san
Gbajugbaja alawada, Debo Macaroni ati awọn mii wa lara awọn eeyan to ti gba ominira.
Ẹsun iditẹ, dida alaafia ilu ru ati titapa si ilana Covid-19 ni wọn fi kan wọn.
Ọkan lara awọn agbẹjọro to n ṣagbatẹru iwọde ENDSARS, @Mochievous lo fi ikede naa sita loju opo Twitter rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Lara awọn nkan ti wọn yoo nilo lati gba beeli wọn ni oniduro kọọkan, ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira ati esi ayẹwo aarun Covid-19.
Amọ ṣa, ọjọ keji, oṣun Kẹta ni igbẹjọ yoo waye lori ọrọ wọn.

Ajimuna ni ikọ BBC fi ṣe ti wọn ji gbera lọ si ibode Lekki Toll gate nibi ti awọn ọdọ ti fẹ ṣe iwọde.
Ọkan lara awọn ọdọ to wa nibẹ ti awọn ọlọpaa ko ni papamọra wọ inu ọkọ wọn n pariwo sọrọ soke pe ẹtọ oun loun n ja fun.
Damilare Adenola to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun sọ pe jẹjẹ oun loun duro ti oun n woran ti awọn ọlọpaa si wa mu oun.
- Àwọn tó kù mi ni kí n sọ fún ìjọba pé Tollgate gbudọ̀ di títì pa àfi tí ìdájọ́ bá jọba
- Wo àwọn gbajúgbajà ojú ti EFCC máa ba ṣe ẹjọ́ ní 2021
- Ìdí tí wọn kii fi jẹ́ kí obìnrin jẹ Ọ̀ọ̀ni ni Ile Ife
- Ta ló pa ẹbí olùrànlọ́wọ́ Gómìnà Rotimi Akeredolu nínú oko rẹ̀ l'Ondo?
- Ìpèsè iṣẹ́ ló yẹ kí ìjọba gbájú mọọ́, kìí ṣe ''cryptocurrency''- Atiku

Ajimuna ni ikọ BBC fi ṣe ti wọn ji gbera lọ si ibode Lekki Toll gate nibi ti awọn ọdọ ti fẹ ṣe iwọde.
Awọn ọlpaa kogberegbe ti duro wamu si ẹnu ibode Lekki Toll Gate lati kọdi eyikeyi oluwọde to ba fẹ ṣewọde ENDSARS mii ni ipinlẹ Eko.



Lalẹ ọjọ Ẹti ti ikọ BBC kan si 'Lekki Toll Gate Admiralty Plaza' niṣe lakọroyin wa ri awọn ọlọpaa na ti wọn dira ogun.
Saaju ni Yinka Egbeyemi to jẹ alukoro ọlọpaa ti lewaju awọn ikọ ọlọpaa naa lati ṣafihan wamuwamu la duro kaakiri agbegbe Obalende, Ikoyo, Jakande Roundabout ati awọn aaye mi ni Eti Osa Lagos Island.
O ni awọn ṣe bẹ lati dena eyikeyi iwa daran to ba fẹ waye nibẹ.


Ẹwẹ ileeṣẹ to n ṣakoso ibode Lekki Toll Gate lo n rawọ ẹbẹ sawọn to fẹ ṣewọde lọla.

Ileeṣẹ naa ni wọn ti ba ibode naa jẹ tẹlẹ bi wọn ba si tun iwọde mii ṣe, ọgbẹ ọkan ni yoo jẹ fawọn mọlẹbi ti iṣẹlẹ naa fọwọkan lẹmi tẹlẹ.















